Jóòbù 16:1-22
16 Jóòbù sì bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn, ó sì wí pé:
2 “Mo ti gbọ́ ọpọ̀ nǹkan báwọ̀nyí.Olùtùnú tí ń dani láàmú ni gbogbo yín!+
3 Òpin ha wà fún àwọn ọ̀rọ̀ òfìfo?+Tàbí kí ní ń kan ọ́ lára, tí ìwọ fi dáhùn?
4 Èmi pẹ̀lú lè sọ̀rọ̀ dáadáa bí tiyín.Ì bá ṣe pé ọkàn yín wà ní ibi tí ọkàn mi wà,Ọ̀rọ̀ mi yóò ha múná ṣámúṣámú lòdì sí yín,+Èmi yóò ha sì mi orí mi sí yín?+
5 Èmi ì bá fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi fún yín lókun,+Ìtùnú ètè mi ì bá sì dá dúró—.
6 Bí mo bá sọ̀rọ̀, ìrora mi ni a kò dá dúró,+Bí mo bá sì ṣíwọ́ ṣíṣe bẹ́ẹ̀, kí ni ó lọ kúrò lọ́dọ̀ mi?
7 Kìkì pé nísinsìnyí, ó ti tán mi lókun;+Ó ti sọ gbogbo àwọn tí ó péjọ tì mí di ahoro.
8 Ìwọ pẹ̀lú gbá mi mú. Ó ti di ẹlẹ́rìí,+Tí rírù tí mo rù fi dìde sí mi. Ó ń jẹ́rìí ní ojú mi.
9 Àní ìbínú rẹ̀ ti fà mí ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ó sì ń ṣe kèéta+ sí mi.Ní ti gidi, ó ń wa eyín pọ̀ sí mi.+Elénìní mi ń fẹjú mọ́ mi.+
10 Wọ́n ti la ẹnu wọn gbàù sí mi,+Tẹ̀gàntẹ̀gàn ni wọ́n gbá mi ní ẹ̀rẹ̀kẹ́,Wọ́n wọ́ ara wọn jọpọ̀ lòdì sí mi ní iye púpọ̀.+
11 Ọlọ́run fi mí lé àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin lọ́wọ́,Ó sì jù mí lógèdèǹgbé sọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú.+
12 Mo ti wá wà ní ìdẹ̀rùn, ṣùgbọ́n ó tẹ̀ síwájú láti gbọ̀n mí jìgìjìgì;+Ó sì rá mi mú ní ẹ̀yìn ọrùn, ó sì tẹ̀ síwájú láti fọ́ mi túútúú,Ó sì gbé mi kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àfojúsùn fún ara rẹ̀.
13 Àwọn tafàtafà rẹ̀+ pagbo yí mi ká;Ó la àwọn kíndìnrín mi+ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, kò sì ní ìyọ́nú;Ó da àpò òróòró mi sórí ilẹ̀yílẹ̀.
14 Ó ń dá mi lu pẹ̀lú àlàfo tẹ̀ lé àlàfo;Ó sáré sí mi bí alágbára ńlá.+
15 Aṣọ àpò ìdọ̀họ+ ni mo rán pọ̀ láti fi bo awọ ara mi,Mo sì ti ìwo mi bọ inú ekuru pàápàá.+
16 Àní ojú mi ti di pípọ́n láti inú ẹkún sísun,+Ibú òjìji sì wà ní ìpéǹpéjú mi,+
17 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ìwà ipá ní àtẹ́lẹwọ́ mi,Àdúrà mi sì mọ́ gaara.+
18 Ìwọ ilẹ̀, má bo ẹ̀jẹ̀ mi!+Má sì jẹ́ kí àyè kankan wà fún igbe ẹkún mi!
19 Pẹ̀lúpẹ̀lù nísinsìnyí, wò ó! ẹni tí ń jẹ́rìí nípa mi ń bẹ ní ọ̀run,Ẹlẹ́rìí mi sì ń bẹ ní ibi gíga.+
20 Àwọn alábàákẹ́gbẹ́ mi jẹ́ agbọ̀rọ̀sọ lòdì sí mi;+Ojú mi ń wo Ọlọ́run láìlèsùn.+
21 Ìpinnu náà ni a ó sì ṣe láàárín abarapá ọkùnrin àti Ọlọ́run.Bákan náà, bí i láàárín ọmọ ènìyàn àti ọmọnìkejì rẹ̀.+
22 Nítorí pé kìkì ọdún díẹ̀ sí i ni yóò dé,Ipa ọ̀nà tí èmi kì yóò sì gbà padà ni èmi yóò gbà lọ.+

