Jóòbù 14:1-22
14 “Ènìyàn, tí obìnrin bí,+Ọlọ́jọ́ kúkúrú ni,+ ó sì kún fún ṣìbáṣìbo.+
2 Ó jáde wá bí ìtànná, a sì ké e kúrò,+Ó sì fẹsẹ̀ fẹ bí òjìji,+ kò sì sí mọ́.
3 Bẹ́ẹ̀ ni, ẹni yìí ni ìwọ tẹjú mọ́,Ìwọ sì mú mi wá sínú ìdájọ́+ pẹ̀lú ara rẹ.
4 Ta ní lè mú ẹni tí ó mọ́ jáde láti inú ẹni tí kò mọ́?+Kò sí ẹnì kankan.
5 Bí a bá ti pinnu àwọn ọjọ́ rẹ̀,+Iye oṣù rẹ̀ ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ;Ìwọ ti pa àṣẹ àgbékalẹ̀ fún un, kí ó má bàa lọ ré kọjá rẹ̀.
6 Yí ojú rẹ kúrò lára rẹ̀, kí ó bàa lè sinmi,+Títí òun yóò fi ní ìdùnnú ní ọjọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí lébìrà tí a háyà ti ń ní ìdùnnú.
7 Nítorí pé ìrètí wà fún igi pàápàá.Bí a bá gé e lulẹ̀, àní yóò tún hù,+Ẹ̀ka igi rẹ̀ kì yóò sì kásẹ̀ nílẹ̀.
8 Bí gbòǹgbò rẹ̀ bá di ogbó nínú ilẹ̀,Tí kùkùté rẹ̀ sì kú nínú ekuru,
9 Nígbà tí ó bá gbọ́ ìtasánsán omi, yóò hù,+Yóò sì mú ẹ̀tun bí ọ̀gbìn tuntun wá dájúdájú.+
10 Ṣùgbọ́n abarapá ọkùnrin kú, ó sì wà nílẹ̀ láìlè gbéra sọ;Ará ayé sì gbẹ́mìí mì, ibo ni ó sì wà?+
11 Omi ń dàwátì nínú òkun,Odò sì ń fà, ó sì ń gbẹ táútáú.+
12 Ènìyàn pẹ̀lú yóò dùbúlẹ̀, kì yóò sì dìde.+Títí ọ̀run kì yóò fi sí mọ́, wọn kì yóò jí,+Bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò ta wọ́n jí kúrò lójú oorun wọn.+
13 Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fi mí pa mọ́ sínú Ṣìọ́ọ̀lù,+Pé ìwọ yóò pa mí mọ́ ní ìkọ̀kọ̀ títí ìbínú rẹ yóò fi yí padà,Pé ìwọ yóò yan àkókò kan kalẹ̀+ fún mi, kí o sì rántí mi!+
14 Bí abarapá ènìyàn bá kú, ó ha tún lè wà láàyè bí?+Jálẹ̀ gbogbo ọjọ́ òpò tí mo ní láti ṣe lápàpàǹdodo ni èmi yóò fi dúró,+Títí ìtura mi yóò fi dé.+
15 Ìwọ yóò pè, èmi fúnra mi yóò sì dá ọ lóhùn.+Ìwọ yóò ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
16 Nítorí pé nísinsìnyí, ìwọ ń ka àwọn ìṣísẹ̀ mi pàápàá;+Ìwọ kò ṣọ́ nǹkan mìíràn bí kò ṣe ẹ̀ṣẹ̀ mi.+
17 A fi èdìdì di ìdìtẹ̀ mi sínú àpò,+Ìwọ sì fi àtè lẹ ìṣìnà mi.
18 Bí ó ti wù kí ó rí, òkè ńlá, tí ń ṣubú lọ, yóò pòórá,Àní àpáta sì ni a óò ṣí kúrò ní ipò rẹ̀.
19 Dájúdájú, omi a máa yinrin òkúta pàápàá;Ìtújáde rẹ̀ a máa gbá ekuru ilẹ̀ lọ.Bí o ṣe pa àní ìrètí ẹni kíkú run nìyẹn.
20 Ìwọ borí rẹ̀ títí láé, tí ó fi jẹ́ pé ó lọ;+Ìwọ ń ba ojú rẹ̀ jẹ́, tí ó fi jẹ́ pé o rán an lọ.
21 Àwọn ọmọ rẹ̀ ni a bọlá fún, ṣùgbọ́n òun kò mọ̀;+Wọ́n sì di aláìjámọ́ pàtàkì; ṣùgbọ́n kò ronú nípa wọn.
22 Kìkì pé ẹran ara rẹ̀ yóò máa ro ó nígbà tí ó ṣì wà lára rẹ̀,Ọkàn rẹ̀ yóò sì máa ṣọ̀fọ̀ nígbà tí ó ṣì wà nínú rẹ̀.”

