Jóòbù 12:1-25

12  Jóòbù sì bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn, ó sì wí pé:  2  “Ní tòótọ́, ẹ̀yin ni àwọn ènìyàn náà,Ẹ̀yin ni ọgbọ́n yóò sì bá kú!+  3  Èmi pẹ̀lú ní ọkàn-àyà+ bí ẹ̀yin.Èmi kò rẹlẹ̀ sí yín,+Ọ̀dọ̀ ta sì ni nǹkan báwọ̀nyí kò sí?  4  Ẹni tí ọmọnìkejì rẹ̀ ń fi rẹ́rìn-ín ni mo dà,+Ẹni tí ń pe Ọlọ́run pé kí ó dá òun lóhùn.+Ẹni tí a ń fi rẹ́rìn-ín ni olódodo, aláìlẹ́bi.  5  Aláìní àníyàn fojú tín-ín-rín àkúrun nínú ìrònú;+A pèsè rẹ̀ sílẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́sẹ̀ gbígbò yèpéyèpé.+  6  Àgọ́ àwọn afiniṣèjẹ wà láìní ìdààmú,+Àwọn tí ń mú kí Ọlọ́run ní ìhónú sì wà ní ipò àìséwuTí ó jẹ́ ti ẹni tí ó mú ọlọ́run kan wá ní ọwọ́ rẹ̀.+  7  Bí ó ti wù kí ó rí, jọ̀wọ́ béèrè lọ́wọ́ àwọn ẹran agbéléjẹ̀, wọn yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni;+Àti àwọn ẹ̀dá abìyẹ́lápá ojú ọ̀run pẹ̀lú, wọn yóò sì sọ fún ọ.+  8  Tàbí kí o fi ọkàn-ìfẹ́ hàn sí ilẹ̀ ayé, yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni;+Àwọn ẹja inú òkun+ yóò sì polongo rẹ̀ fún ọ.  9  Èwo nínú gbogbo ìwọ̀nyí ni kò mọ̀ dáadáaPé ọwọ́ Jèhófà ni ó ṣe èyí,+ 10  Ọwọ́ ẹni tí ọkàn+ olúkúlùkù ẹni tí ó wà láàyè wàÀti ẹ̀mí gbogbo ẹran ara ènìyàn?+ 11  Etí kò ha ń dán ọ̀rọ̀ wò+Bí òkè ẹnu+ ti ń tọ́ oúnjẹ wò? 12  Ọgbọ́n kò ha wà láàárín àwọn àgbàlagbà+Àti òye nínú gígùn àwọn ọjọ́? 13  Ọgbọ́n àti agbára ńlá wà pẹ̀lú rẹ̀;+Ó ní ìmọ̀ràn àti òye.+ 14  Wò ó! Ó ya lulẹ̀, kí ó má bàa sí gbígbéró;+Ó mú kí a tì í mọ́ ènìyàn, kí a má bàa ṣí i.+ 15  Wò ó! Ó dá omi dúró, wọ́n sì gbẹ táútáú;+Ó sì rán wọn lọ, wọ́n sì yí ilẹ̀ ayé padà.+ 16  Okun àti ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ wà pẹ̀lú rẹ̀;+Ẹni tí ń ṣe àṣìṣe àti ẹni tí ń múni ṣáko lọ jẹ́ tirẹ̀;+ 17  Ó ń mú kí àwọn agbani-nímọ̀ràn lọ láìwọ bàtà,+Ó sì ń mú kí àwọn onídàájọ́ di ayírí. 18  Ìdè àwọn ọba ni ó ń tú ní ti tòótọ́,+Ó sì ń de ìgbànú mọ́ ìgbáròkó wọn. 19  Ó ń mú kí àwọn àlùfáà rìn láìwọ bàtà,+Ó sì ń dojú àwọn tí ó ti jókòó pa dé;+ 20  Ó ń mú ọ̀rọ̀ kúrò lẹ́nu àwọn olùṣòtítọ́,Ó sì ń gba ìlóyenínú àwọn àgbààgbà lọ; 21  Ó ń da ìfojú-tín-ín-rín sára àwọn ọ̀tọ̀kùlú,+Àmùrè àwọn alágbára ni ó sì ń sọ di dídẹ̀ ní ti tòótọ́; 22  Ó ń tú àwọn ohun ìjìnlẹ̀ síta láti inú òkùnkùn,+Ó sì ń mú ibú òjìji jáde wá sínú ìmọ́lẹ̀; 23  Ó ń mú kí àwọn orílẹ̀-èdè di ńlá, kí ó lè pa wọ́n run;+Ó ń tan àwọn orílẹ̀-èdè kálẹ̀, kí ó lè kó wọn lọ; 24  Ó ń mú ọkàn-àyà olórí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà kúrò,Kí ó lè mú wọn rìn gbéregbère ní ibi ṣíṣófo,+ níbi tí ọ̀nà kò sí. 25  Wọ́n ń táràrà nínú òkùnkùn,+ níbi tí ìmọ́lẹ̀ kò sí,Kí ó lè mú wọn rìn gbéregbère bí ọ̀mùtípara.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé