Jóẹ́lì 3:1-21
3 “Nítorí pé, wò ó! ní ọjọ́ wọnnì àti ní àkókò yẹn,+ nígbà tí èmi yóò mú àwọn òǹdè Júdà àti Jerúsálẹ́mù+ padà bọ̀,
2 dájúdájú, èmi pẹ̀lú yóò kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọpọ̀,+ èmi yóò sì mú wọn sọ̀ kalẹ̀ wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Jèhóṣáfátì;+ èmi yóò sì mú ara mi wọnú ìdájọ́ pẹ̀lú wọn níbẹ̀ ní tìtorí àwọn ènìyàn mi àti ní tìtorí Ísírẹ́lì+ ogún mi, tí wọ́n tú ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè; wọ́n sì pín ilẹ̀ mi.+
3 Wọ́n sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣẹ́ kèké+ nítorí àwọn ènìyàn mi; wọn a sì fi àwọn ọmọ tí ó jẹ́ ọkùnrin gba kárùwà,+ ọmọ tí ó jẹ́ obìnrin ni wọ́n sì tà nítorí wáìnì, kí wọ́n bàa lè mu.
4 “Pẹ̀lúpẹ̀lù, kí ní pa tèmi tiyín pọ̀, ìwọ Tírè àti Sídónì+ àti gbogbo ẹ̀yin ẹkùn ilẹ̀ Filísíà?+ Ṣé ìlòsíni tí ẹ fi ń san án fún mi nìyí? Bí ẹ bá sì ń fi irúfẹ́ ìlòsíni bẹ́ẹ̀ hàn sí mi, kíákíá, kánkán ni èmi yóò san ìlòsíni yín padà sórí ẹ̀yin fúnra yín.+
5 Nítorí pé, ẹ̀yin ti kó fàdákà mi àti wúrà+ mi, ẹ sì ti kó àwọn ohun rere mi fífani-lọ́kàn-mọ́ra lọ sínú àwọn tẹ́ńpìlì+ yín;
6 àwọn ọmọ Júdà àti àwọn ọmọ Jerúsálẹ́mù ni ẹ sì ti tà+ fún àwọn ọmọ Gíríìkì,+ fún ète mímú wọn jìnnà réré kúrò ní ìpínlẹ̀ wọn;+
7 kíyè sí i, èmi yóò ru wọ́n dìde láti wá láti ibi tí ẹ tà wọ́n sí,+ dájúdájú, èmi yóò sì san ìlòsíni yín padà sórí ẹ̀yin fúnra yín.+
8 Dájúdájú, èmi yóò sì ta àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín sí ọwọ́ àwọn ọmọ Júdà,+ wọn yóò sì tà wọ́n fún àwọn ará Ṣébà,+ fún orílẹ̀-èdè kan tí ó jìnnà réré;+ nítorí Jèhófà fúnra rẹ̀ ti sọ ọ́.
9 “Ẹ pòkìkí èyí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ ‘Ẹ sọ ogun di mímọ́! Ẹ ru àwọn ọkùnrin alágbára+ dìde! Ẹ jẹ́ kí wọ́n sún mọ́ tòsí! Ẹ jẹ́ kí wọ́n gòkè wá, gbogbo àwọn ọkùnrin ogun!+
10 Ẹ fi àwọn abẹ ohun ìtúlẹ̀+ yín rọ idà, kí ẹ sì fi àwọn ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn yín rọ aṣóró. Ní ti aláìlera, kí ó sọ pé: “Ọkùnrin alágbára+ ni mí.”
11 Ẹ fúnni ní àrànṣe yín, kí ẹ sì wá, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè yíká-yíká,+ kí ẹ sì kó ara yín jọpọ̀.’”+
Jèhófà, mú àwọn alágbára rẹ sọ̀ kalẹ̀ wá sí ibẹ̀ yẹn.+
12 “Jẹ́ kí a ru àwọn orílẹ̀-èdè dìde, kí wọ́n sì gòkè wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Jèhóṣáfátì;+ nítorí ibẹ̀ ni èmi yóò jókòó sí, kí n bàa lè ṣe ìdájọ́ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yíká-yíká.+
13 “Ẹ ti dòjé+ bọ̀ ọ́, nítorí ìkórè ti pọ́n.+ Ẹ wá, ẹ sọ̀ kalẹ̀, nítorí ìfúntí wáìnì ti kún.+ Àwọn ẹkù ìfúntí ti kún àkúnwọ́sílẹ̀ ní ti tòótọ́; nítorí ìwà búburú wọn ti pọ̀ yanturu.+
14 Ogunlọ́gọ̀, ogunlọ́gọ̀ wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti ìpinnu,+ nítorí ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti ìpinnu.+
15 Oòrùn àti òṣùpá yóò ṣókùnkùn dájúdájú, gbogbo àwọn ìràwọ̀ yóò sì fawọ́ mímọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn dájúdájú.+
16 Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò sì ké ramúramù láti Síónì, yóò sì fọ ohùn+ rẹ̀ jáde láti Jerúsálẹ́mù. Dájúdáju, ọ̀run àti ilẹ̀ ayé yóò mì jìgìjìgì;+ ṣùgbọ́n Jèhófà yóò jẹ́ ibi ìsádi fún àwọn ènìyàn rẹ̀,+ àti odi agbára fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+
17 Ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run+ yín, tí ń gbé Síónì òkè ńlá+ mímọ́ mi. Jerúsálẹ́mù yóò sì di ibi+ mímọ́; àti ní ti àwọn àjèjì, wọn kì yóò tún gbà á kọjá mọ́.+
18 “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé, àwọn òkè ńlá yóò máa sẹ̀ fún wáìnì dídùn,+ àwọn òkè kéékèèké yóò sì máa ṣàn fún wàrà, gbogbo ojú ìṣàn omi Júdà ni yóò sì máa ṣàn fún omi. Ìsun+ kan yóò sì jáde lọ láti ilé Jèhófà, yóò sì bomi rin àfonífojì olójú ọ̀gbàrá tí ó ní àwọn Igi Bọn-ọ̀n-ní.+
19 Ní ti Íjíbítì, ahoro ni yóò dà;+ àti ní ti Édómù, aginjù ahoro ni yóò dà,+ nítorí ìwà ipá sí àwọn ọmọ Júdà, ní ilẹ̀ ẹni tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀+ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sílẹ̀.
20 Ṣùgbọ́n ní ti Júdà, a óò máa gbé e+ fún àkókò tí ó lọ kánrin, àti Jerúsálẹ́mù láti ìran dé ìran.+
21 Ẹ̀jẹ̀ wọn tí èmi kò kà sí aláìmọwọ́-mẹsẹ̀+ ni èmi yóò sì ka sí aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ dájúdájú; Jèhófà yóò sì máa gbé Síónì.”+

