Jòhánù 21:1-25
21 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jésù tún fi ara rẹ̀ hàn kedere fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní òkun Tìbéríà; ṣùgbọ́n ó ṣe ìfarahàn kedere náà ní ọ̀nà yìí.
2 Àwọn tí wọ́n jọ wà pa pọ̀ ni Símónì Pétérù àti Tọ́másì, ẹni tí a ń pè ní Ìbejì,+ àti Nàtáníẹ́lì+ láti Kánà ti Gálílì àti àwọn ọmọkùnrin Sébédè+ àti àwọn méjì mìíràn lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.
3 Símónì Pétérù wí fún wọn pé: “Mo ń lọ pẹja.” Wọ́n wí fún un pé: “Àwa náà ń bọ̀ pẹ̀lú rẹ.” Wọ́n jáde, wọ́n sì wọ ọkọ̀ ojú omi, ṣùgbọ́n ní òru yẹn, wọn kò mú nǹkan kan.+
4 Bí ó ti wù kí ó rí, bí ó ti ń di òwúrọ̀ gẹ́lẹ́, Jésù dúró ní etíkun, ṣùgbọ́n ṣá o, àwọn ọmọ ẹ̀yìn kò fi òye mọ̀ pé Jésù ni.+
5 Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, ẹ kò ní ohunkóhun láti jẹ, àbí ẹ ní?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ó tì o!”
6 Ó wí fún wọn pé: “Ẹ ju àwọ̀n sí ìhà ọ̀tún ọkọ̀ ojú omi, ẹ ó sì rí díẹ̀.”+ Nígbà náà ni wọ́n jù ú, ṣùgbọ́n wọn kò lè fà á wọlé mọ́ nítorí ògìdìgbó ẹja.+
7 Nítorí náà, ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù ti máa ń nífẹ̀ẹ́+ wí fún Pétérù+ pé: “Olúwa ni!” Nítorí èyí, Símónì Pétérù, ní gbígbọ́ pé Olúwa ni, ó fi ẹ̀wù àwọ̀sókè rẹ̀ di ara rẹ̀ lámùrè, nítorí pé ó wà ní ìhòòhò, ó sì bẹ́ sínú òkun.
8 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù bá ọkọ̀ ojú omi kékeré náà wá, nítorí wọn kò jìnnà sí ilẹ̀, nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún ẹsẹ̀ bàtà péré ni sí ibẹ̀, wọ́n ń wọ́ àwọ̀n tí ó kún fún ẹja.
9 Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí wọ́n sọ̀ kalẹ̀ láti inú ọkọ̀ sórí ilẹ̀, wọ́n rí iná èédú igi+ tí ó wà nílẹ̀ níbẹ̀ àti ẹja tí ó wà lórí rẹ̀ àti búrẹ́dì.
10 Jésù wí fún wọn pé: “Ẹ mú díẹ̀ wá lára ẹja tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ pa nísinsìnyí.”
11 Nítorí náà, Símónì Pétérù wọ ọkọ̀ lọ, ó sì fa àwọ̀n tí ó kún fún àwọn ẹja ńlá wá sí ilẹ̀, wọ́n jẹ́ ọgọ́rùn-ún kan àti àádọ́ta-lé-mẹ́ta. Ṣùgbọ́n bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n pọ̀ tó yìí, àwọ̀n náà kò bẹ́.
12 Jésù wí fún wọn pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ oúnjẹ àárọ̀ yín.”+ Kò sí ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí ó ní ìgboyà láti ṣe ìwádìí lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ta ni ọ́?” nítorí wọ́n mọ̀ pé Olúwa ni.
13 Jésù wá, ó sì mú búrẹ́dì náà, ó sì fi í fún wọn,+ àti ẹja náà bákan náà.
14 Èyí ni ìgbà kẹta+ nísinsìnyí tí Jésù fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn lẹ́yìn tí a gbé e dìde kúrò nínú òkú.
15 Wàyí o, nígbà tí wọ́n jẹ oúnjẹ àárọ̀ tán, Jésù wí fún Símónì Pétérù pé: “Símónì ọmọkùnrin Jòhánù, ìwọ ha nífẹ̀ẹ́ mi ju ìwọ̀nyí lọ bí?”+ Ó wí fún un pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, ìwọ mọ̀ pé mo ní ìfẹ́ni fún ọ.”+ Ó wí fún un pé: “Máa bọ́ àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn mi.”+
16 Ó tún wí fún un, ní ìgbà kejì pé: “Símónì ọmọkùnrin Jòhánù, ìwọ ha nífẹ̀ẹ́+ mi bí?” Ó wí fún un pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, ìwọ mọ̀ pé mo ní ìfẹ́ni fún ọ.” Ó wí fún un pé: “Máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn àgùntàn mi kéékèèké.”+
17 Ó wí fún un ní ìgbà kẹta pé: “Símónì ọmọkùnrin Jòhánù, ìwọ ha ní ìfẹ́ni fún mi bí?” Ẹ̀dùn-ọkàn bá Pétérù ní ti pé ó wí fún un ní ìgbà kẹta pé: “Ìwọ ha ní ìfẹ́ni fún mi bí?” Nítorí náà, ó wí fún un pé: “Olúwa, ìwọ mọ ohun gbogbo;+ ìwọ mọ̀ pé mo ní ìfẹ́ni fún ọ.” Jésù wí fún un pé: “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi kéékèèké.+
18 Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún ọ pé, Nígbà tí ìwọ jẹ́ ọ̀dọ́, ìwọ a máa di ara rẹ lámùrè, ìwọ a sì máa rìn káàkiri lọ sí ibi tí o fẹ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí o bá darúgbó, ìwọ yóò na ọwọ́ rẹ, ọkùnrin mìíràn yóò dì ọ́ lámùrè,+ yóò sì gbé ọ lọ sí ibi tí ìwọ kò fẹ́.”+
19 Èyí ni ó sọ láti fi tọ́ka sí irú ikú+ tí òun yóò fi yin Ọlọ́run lógo.+ Nítorí náà, nígbà tí ó ti sọ èyí, ó sọ fún un pé: “Máa bá a lọ ní títọ̀ mí lẹ́yìn.”+
20 Ní yíyíjú padà, Pétérù rí ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù ti máa ń nífẹ̀ẹ́+ tí ń tẹ̀ lé wọn, ẹni tí ó tẹ̀ sẹ́yìn lé igẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú nídìí oúnjẹ alẹ́, tí ó sì wí pé: “Olúwa, ta ni ẹni tí yóò dà ọ́?”
21 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí ó tajú kán rí i, Pétérù wí fún Jésù pé: “Olúwa, kí ni ọkùnrin yìí yóò ṣe?”
22 Jésù wí fún un pé: “Bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ mi pé kí ó wà títí èmi yóò fi dé,+ kí ni ó kàn ọ́ níbẹ̀? Ìwọ máa bá a lọ ní títọ̀ mí lẹ́yìn.”
23 Nítorí náà, àsọjáde yìí jáde lọ láàárín àwọn ará, pé ọmọ ẹ̀yìn yẹn kì yóò kú. Bí ó ti wù kí ó rí, Jésù kò sọ fún un pé kì yóò kú, ṣùgbọ́n pé: “Bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ mi pé kí ó wà+ títí èmi yóò fi dé, kí ni ó kàn ọ́ níbẹ̀?”
24 Èyí ni ọmọ ẹ̀yìn+ tí ó jẹ́rìí nípa nǹkan wọ̀nyí, tí ó sì kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí, àwa sì mọ̀ pé òótọ́ ni ẹ̀rí tí ó jẹ́.+
25 Ní ti tòótọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan mìíràn wà pẹ̀lú tí Jésù ṣe, tí ó jẹ́ pé, bí a bá ní láti kọ̀wé kúlẹ̀kúlẹ̀ wọn ní kíkún, mo rò pé, ayé tìkára rẹ̀ kò ní lè gba àwọn àkájọ ìwé tí a bá kọ.+

