Jòhánù 15:1-27

15  “Èmi ni àjàrà tòótọ́,+ Baba mi sì ni aroko.+ 2  Gbogbo ẹ̀ka tí ń bẹ nínú mi tí kì í so èso ni ó ń mú kúrò,+ gbogbo èyí tí ó sì ń so èso ni ó ń wẹ̀ mọ́,+ kí ó lè so èso púpọ̀ sí i.+ 3  Ẹ ti mọ́ nísinsìnyí nítorí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún yín.+ 4  Ẹ dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi, àti èmi ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú yín.+ Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka kò ti lè so èso fúnra rẹ̀ láìjẹ́ pé ó dúró nínú àjàrà, lọ́nà kan náà ni ẹ̀yin náà kò lè ṣe bẹ́ẹ̀, láìjẹ́ pé ẹ dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi.+ 5  Èmi ni àjàrà náà, ẹ̀yin ni ẹ̀ka. Ẹni tí ó bá dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi, àti èmi ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ẹni yìí ń so èso púpọ̀;+ nítorí láìsí mi, ẹ kò lè ṣe nǹkan kan rárá. 6  Bí ẹnikẹ́ni kò bá dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi, a ó ya á dànù gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka kan, a sì gbẹ; àwọn ènìyàn a sì kó ẹ̀ka wọnnì jọ, wọn a sì gbé wọn sọ sínú iná, wọn a sì jóná.+ 7  Bí ẹ bá dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi, tí àwọn àsọjáde mi sì dúró nínú yín, ẹ béèrè ohun yòówù tí ẹ bá fẹ́, yóò sì ṣẹlẹ̀ fún yín.+ 8  A yin Baba mi lógo nínú èyí, pé ẹ ń bá a nìṣó ní síso èso púpọ̀, tí ẹ sì fi ara yín hàn ní ọmọ ẹ̀yìn mi.+ 9  Gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti nífẹ̀ẹ́ mi,+ tí èmi sì nífẹ̀ẹ́ yín, ẹ dúró nínú ìfẹ́ mi. 10  Bí ẹ bá pa àwọn àṣẹ mi mọ́,+ ẹ óò dúró nínú ìfẹ́ mi, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti pa àwọn àṣẹ Baba+ mọ́, tí mo sì dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀. 11  “Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, kí ìdùnnú mi lè wà nínú yín, kí a sì lè sọ ìdùnnú yín di kíkún.+ 12  Èyí ni àṣẹ mi, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín.+ 13  Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.+ 14  Ọ̀rẹ́ mi ni yín, bí ẹ bá ń ṣe ohun tí mo ń pa láṣẹ fún yín.+ 15  Èmi kò pè yín ní ẹrú mọ́, nítorí pé ẹrú kì í mọ ohun tí ọ̀gá rẹ̀ ń ṣe. Ṣùgbọ́n mo pè yín ní ọ̀rẹ́,+ nítorí pé gbogbo nǹkan tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba mi ni mo ti sọ di mímọ̀ fún yín.+ 16  Ẹ̀yin kọ́ ni ẹ yàn mí, ṣùgbọ́n èmi ni mo yàn yín, mo sì yàn yín sípò láti máa bá a lọ àti láti máa so èso,+ kí èso yín sì máa wà síbẹ̀; kí ó lè jẹ́ pé ohunkóhun yòówù tí ẹ bá béèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, kí ó lè fi í fún yín.+ 17  “Nǹkan wọ̀nyí ni mo pa láṣẹ fún yín, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.+ 18  Bí ayé bá kórìíra yín, ẹ mọ̀ pé ó ti kórìíra mi kí ó tó kórìíra yín.+ 19  Bí ẹ̀yin bá jẹ́ apá kan ayé, ayé yóò máa ní ìfẹ́ni fún ohun tí í ṣe tirẹ̀.+ Wàyí o, nítorí pé ẹ kì í ṣe apá kan ayé,+ ṣùgbọ́n mo ti yàn yín kúrò nínú ayé, ní tìtorí èyí ni ayé fi kórìíra yín.+ 20  Ẹ fi ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún yín sọ́kàn, pé, Ẹrú kò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ. Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọn yóò ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú;+ bí wọ́n bá ti pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, wọn yóò pa tiyín mọ́ pẹ̀lú. 21  Ṣùgbọ́n wọn yóò ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí sí yín ní tìtorí orúkọ mi, nítorí wọn kò mọ ẹni tí ó rán mi.+ 22  Ká ní èmi kò ti wá, kí n sì ti bá wọn sọ̀rọ̀, wọn kì bá ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan;+ ṣùgbọ́n nísinsìnyí, wọn kò ní àwíjàre kankan fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.+ 23  Ẹni tí ó bá kórìíra mi, kórìíra Baba mi pẹ̀lú.+ 24  Ká ní èmi kò ti ṣe àwọn iṣẹ́ tí ẹlòmíràn kankan kò ṣe láàárín wọn ni,+ wọn kì bá ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan;+ ṣùgbọ́n nísinsìnyí wọ́n ti rí, wọ́n sì ti kórìíra èmi àti Baba mi.+ 25  Ṣùgbọ́n ó jẹ́ láti lè mú ọ̀rọ̀ tí a kọ sínú Òfin wọn ṣẹ pé, ‘Wọ́n kórìíra mi láìnídìí.’+ 26  Nígbà tí olùrànlọ́wọ́ tí èmi yóò rán sí yín láti ọ̀dọ̀ Baba bá dé, ẹ̀mí òtítọ́ náà, tí ń wá láti ọ̀dọ̀ Baba,+ èyíinì yóò jẹ́rìí nípa mi;+ 27  ẹ̀yin, ẹ̀wẹ̀, yóò sì jẹ́rìí,+ nítorí pé ẹ̀yin ti wà pẹ̀lú mi láti ìgbà tí mo ti bẹ̀rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé