Jòhánù 10:1-42
10 “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹni tí kò bá gba ẹnu ọ̀nà+ wọ ọgbà àgùntàn ṣùgbọ́n tí ó gun ibòmíràn, ẹni yẹn ni olè àti olùpiyẹ́.+
2 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá gba ẹnu ọ̀nà+ wọlé ni olùṣọ́+ àwọn àgùntàn.+
3 Olùṣọ́nà+ ṣílẹ̀kùn fún ẹni yìí, àwọn àgùntàn+ sì fetí sí ohùn rẹ̀, ó sì fi orúkọ pe àwọn àgùntàn tirẹ̀, ó sì ṣamọ̀nà wọn jáde.
4 Nígbà tí ó ti kó gbogbo àwọn tirẹ̀ jáde, ó ń lọ níwájú wọn, àwọn àgùntàn sì tẹ̀ lé e,+ nítorí pé wọ́n mọ ohùn rẹ̀.+
5 Àjèjì ni wọn kì yóò tẹ̀ lé lọ́nàkọnà, ṣùgbọ́n wọn yóò sá+ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí pé wọn kò mọ ohùn àwọn àjèjì.”+
6 Jésù sọ àkàwé yìí fún wọn; ṣùgbọ́n wọn kò mọ ohun tí àwọn nǹkan tí ó ń sọ fún wọn túmọ̀ sí.+
7 Nítorí náà, Jésù tún wí pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Èmi ni ẹnu ọ̀nà+ àwọn àgùntàn.
8 Gbogbo àwọn tí wọ́n ti wá ní ipò mi jẹ́ olè àti olùpiyẹ́;+ ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn kò fetí sí wọn.+
9 Èmi ni ẹnu ọ̀nà;+ ẹnì yòówù tí ó bá gba ọ̀dọ̀ mi wọlé ni a ó gbà là, yóò sì wọlé, yóò sì jáde, yóò sì rí pápá ìjẹko.+
10 Olè+ kì í wá bí kò ṣe láti jalè àti láti pani àti láti pa run.+ Èmi ti wá kí wọ́n lè ní ìyè, kí wọ́n sì ní in lọ́pọ̀ yanturu.
11 Èmi ni olùṣọ́ àgùntàn àtàtà;+ olùṣọ́ àgùntàn àtàtà fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn.+
12 Ọkùnrin tí a háyà,+ tí kì í ṣe olùṣọ́ àgùntàn, tí àwọn àgùntàn kò sì jẹ́ tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ti òun fúnra rẹ̀, rí ìkookò tí ń bọ̀, ó sì pa àwọn àgùntàn tì, ó sì sá lọ—ìkookò sì já wọn gbà, ó sì tú wọn ká+—
13 nítorí pé ó jẹ́ ọkùnrin tí a háyà,+ kò sì bìkítà fún àwọn àgùntàn.+
14 Èmi ni olùṣọ́ àgùntàn àtàtà, mo sì mọ àwọn àgùntàn mi,+ àwọn agutan mi sì mọ̀ mí,+
15 gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti mọ̀ mí, tí mo sì mọ Baba;+ mo sì fi ọkàn mi lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn.+
16 “Èmi sì ní àwọn àgùntàn mìíràn,+ tí kì í ṣe ara ọ̀wọ́ yìí;+ àwọn pẹ̀lú ni èmi yóò mú wá, wọn yóò sì fetí sí ohùn mi,+ wọn yóò sì di agbo kan, olùṣọ́ àgùntàn kan.+
17 Ìdí nìyí tí Baba fi nífẹ̀ẹ́ mi,+ nítorí pé mo fi ọkàn mi lélẹ̀,+ kí n lè tún rí i gbà.
18 Kò sí ènìyàn kankan tí ó gbà á kúrò lọ́wọ́ mi, ṣùgbọ́n mo fi í lélẹ̀ ní ìdánúṣe ti ara mi. Mo ní ọlá àṣẹ láti fi í lélẹ̀, mo sì ní ọlá àṣẹ láti tún gbà á.+ Àṣẹ+ lórí èyí ni mo gbà láti ọwọ́ Baba mi.”
19 Ìpínyà+ kan tún jẹyọ láàárín àwọn Júù nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.
20 Ọ̀pọ̀ nínú wọn ń sọ pé: “Ó ní ẹ̀mí èṣù,+ orí rẹ̀ sì ti dà rú. Èé ṣe tí ẹ ń fetí sí i?”
21 Àwọn mìíràn a sọ pé: “Àsọjáde wọ̀nyí kì í ṣe ti ọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù gbédè. Ẹ̀mí èṣù kò lè la ojú àwọn afọ́jú, àbí ó lè ṣe bẹ́ẹ̀?”
22 Ní àkókò yẹn, àjọyọ̀ ìyàsímímọ́ ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù. Ìgbà òtútù ni,
23 Jésù sì ń rìn nínú tẹ́ńpìlì ní ìloro Sólómọ́nì.+
24 Nítorí náà, àwọn Júù pagbo yí i ká, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún un pé: “Báwo ni yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò fi ọkàn wa sínú àníyàn àìdánilójú? Bí ó bá jẹ́ pé ìwọ ni Kristi náà,+ sọ fún wa láìfọ̀rọ̀-bọpo-bọyọ̀.”+
25 Jésù dá wọn lóhùn pé: “Mo ti sọ fún yín, síbẹ̀síbẹ̀, ẹ kò gbà gbọ́. Àwọn iṣẹ́ tí mo ń ṣe ní orúkọ Baba mi, ìwọ̀nyí ni ń jẹ́rìí nípa mi.+
26 Ṣùgbọ́n ẹ kò gbà gbọ́, nítorí ẹ kì í ṣe ọ̀kan lára àwọn àgùntàn mi.+
27 Àwọn àgùntàn+ mi ń fetí sí ohùn mi, mo sì mọ̀ wọ́n, wọ́n sì ń tẹ̀ lé mi.+
28 Èmi sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun,+ a kì yóò sì pa wọ́n run lọ́nàkọnà láé,+ kò sì sí ẹnì kankan tí yóò já wọn gbà kúrò ní ọwọ́ mi.+
29 Ohun tí Baba+ mi ti fún mi jẹ́ ohun kan tí ó tóbi ju gbogbo ohun mìíràn lọ,+ kò sì sí ẹnì kankan tí ó lè já wọn gbà kúrò ní ọwọ́ Baba.+
30 Èmi àti Baba jẹ́ ọ̀kan.”+
31 Lẹ́ẹ̀kan sí i, àwọn Júù gbé òkúta sókè láti sọ ọ́ ní òkúta.+
32 Jésù fèsì fún wọn pé: “Mo fi ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àtàtà hàn yín láti ọ̀dọ̀ Baba. Nítorí èwo lára iṣẹ́ wọnnì ni ẹ fi fẹ́ sọ mí ní òkúta?”
33 Àwọn Júù dá a lóhùn pé: “Kì í ṣe nítorí iṣẹ́ àtàtà ni a fi fẹ́ sọ ọ́ ní òkúta, bí kò ṣe nítorí ọ̀rọ̀ òdì,+ àní nítorí pé ìwọ, bí o tilẹ̀ jẹ́ ènìyàn, sọ ara rẹ di ọlọ́run kan.”+
34 Jésù dá wọn lóhùn pé: “A kò ha kọ ọ́ sínú Òfin yín+ pé, ‘Èmi wí pé: “Ẹ̀yin jẹ́ ọlọ́run”’?+
35 Bí ó bá pe àwọn tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wá bá ní ‘ọlọ́run,’+ síbẹ̀ tí a kò lè sọ Ìwé Mímọ́ di asán,+
36 ẹ̀yin ha ń sọ fún èmi ẹni tí Baba sọ di mímọ́, tí ó sì rán wá sí ayé pé, ‘Ìwọ sọ̀rọ̀ òdì,’ nítorí mo sọ pé, Ọmọ Ọlọ́run ni mí?+
37 Bí èmi kò bá ń ṣe àwọn iṣẹ́+ Baba mi, ẹ má gbà mí gbọ́.
38 Ṣùgbọ́n bí mo bá ń ṣe wọ́n, bí ẹ kò tilẹ̀ gbà mí gbọ́, ẹ gba àwọn iṣẹ́+ náà gbọ́, kí ẹ lè wá mọ̀, kí ẹ sì máa bá a lọ ní mímọ̀ pé Baba wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi, èmi sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Baba.”+
39 Nítorí náà, wọ́n tún gbìyànjú láti gbá a mú;+ ṣùgbọ́n ó bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́.+
40 Nítorí náà, ó tún lọ sí òdì-kejì Jọ́dánì sí ibi tí Jòhánù ti kọ́kọ́ ń batisí,+ ó sì dúró níbẹ̀.
41 Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Jòhánù, ní tòótọ́, kò ṣe ẹyọ iṣẹ́ àmì kan, ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan tí Jòhánù sọ nípa ọkùnrin yìí jẹ́ òótọ́.”+
42 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ níbẹ̀.+

