Jẹ́nẹ́sísì 46:1-34
46 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Ísírẹ́lì àti gbogbo àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀ ṣí, wọ́n sì dé Bíá-ṣébà,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rúbọ sí Ọlọ́run baba rẹ̀ Ísákì.+
2 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run bá Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ nínú ìran ní òru, ó sì wí pé:+ “Jékọ́bù, Jékọ́bù!” òun sì dáhùn pé: “Èmi nìyí!”+
3 Ó sì ń bá a lọ láti wí pé: “Èmi ni Ọlọ́run tòótọ́,+ Ọlọ́run baba rẹ.+ Má fòyà láti sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Íjíbítì, nítorí tí èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá+ níbẹ̀.
4 Èmi fúnra mi yóò bá ọ sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Íjíbítì, èmi fúnra mi yóò sì mú ọ gòkè pẹ̀lú;+ Jósẹ́fù yóò sì fi ọwọ́ rẹ̀ lé ojú rẹ.”+
5 Lẹ́yìn ìyẹn, Jékọ́bù gbéra kúrò ní Bíá-ṣébà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń bá a nìṣó ní gbígbé Jékọ́bù baba wọn àti àwọn ọmọ wọn kéékèèké àti àwọn aya wọn lọ nínú àwọn kẹ̀kẹ́ tí Fáráò fi ránṣẹ́ láti gbé e.+
6 Síwájú sí i, wọ́n kó ọ̀wọ́ ẹran wọn àti àwọn ẹrù wọn, èyí tí wọ́n ti kó jọ rẹpẹtẹ ní ilẹ̀ Kénáánì.+ Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n dé Íjíbítì, Jékọ́bù àti gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀.
7 Àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọkùnrin tí ó jẹ́ ti ọmọkùnrin rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọbìnrin tí ó jẹ́ ti ọmọkùnrin rẹ̀, àní gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀, pẹ̀lú rẹ̀ ni ó kó wá sí Íjíbítì.+
8 Wàyí o, ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì tí ó wá sí Íjíbítì:+ Jékọ́bù àti àwọn ọmọ rẹ̀: àkọ́bí Jékọ́bù ni Rúbẹ́nì.+
9 Àwọn ọmọkùnrin Rúbẹ́nì sì ni Hánókù àti Pálù àti Hésírónì àti Kámì.+
10 Àwọn ọmọkùnrin Síméónì+ sì ni Jémúélì àti Jámínì àti Óhádì àti Jákínì+ àti Sóhárì àti Ṣọ́ọ̀lù+ ọmọkùnrin obìnrin ará Kénáánì kan.
11 Àwọn ọmọkùnrin Léfì+ sì ni Gẹ́ṣónì,+ Kóhátì+ àti Mérárì.+
12 Àwọn ọmọkùnrin Júdà+ sì ni Éérì+ àti Ónánì+ àti Ṣélà+ àti Pérésì+ àti Síírà.+ Àmọ́ ṣá o, Éérì àti Ónánì kú ní ilẹ̀ Kénáánì.+
Àwọn ọmọkùnrin Pérésì sì ni Hésírónì+ àti Hámúlù.+
13 Àwọn ọmọkùnrin Ísákárì+ sì ni Tólà+ àti Púfà+ àti Íóbù àti Ṣímúrónì.+
14 Àwọn ọmọkùnrin Sébúlúnì+ sì ni Sérédì àti Élónì àti Jálíẹ́lì.+
15 Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Léà,+ tí ó bí fún Jékọ́bù ní Padani-árámù, pa pọ̀ pẹ̀lú ọmọbìnrin rẹ̀ Dínà.+ Gbogbo ọkàn àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ jẹ́ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n.
16 Àwọn ọmọkùnrin Gádì+ sì ni Sífíónì àti Hágì, Ṣúnì àti Ésíbónì, Érì àti Áródì àti Árélì.+
17 Àwọn ọmọkùnrin Áṣérì+ sì ni Ímúnà àti Íṣífà àti Íṣífì àti Bẹráyà,+ Sérà sì ni arábìnrin wọn.
Àwọn ọmọkùnrin Bẹráyà sì ni Hébà àti Málíkíélì.+
18 Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Sílípà,+ tí Lábánì fi fún Léà ọmọbìnrin rẹ̀. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó bí ìwọ̀nyí fún Jékọ́bù: ọkàn mẹ́rìndínlógún.
19 Àwọn ọmọkùnrin Rákélì,+ aya Jékọ́bù, ni Jósẹ́fù+ àti Bẹ́ńjámínì.+
20 A sì wá bí Mánásè+ àti Éfúráímù+ fún Jósẹ́fù ní ilẹ̀ Íjíbítì, àwọn tí Ásénátì,+ ọmọbìnrin Pọ́tíférà àlùfáà Ónì bí fún un.
21 Àwọn ọmọkùnrin Bẹ́ńjámínì sì ni Bélà+ àti Békérì+ àti Áṣíbélì, Gérà+ àti Náámánì,+ Éhì àti Róṣì, Múpímù+ àti Húpímù+ àti Áádì.
22 Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Rákélì tí a bí fún Jékọ́bù. Gbogbo ọkàn náà jẹ́ mẹ́rìnlá.
23 Àwọn ọmọkùnrin Dánì+ sì ni Húṣímù.+
24 Àwọn ọmọkùnrin Náfútálì+ sì ni Jáséélì àti Gúnì+ àti Jésérì àti Ṣílẹ́mù.+
25 Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Bílíhà,+ tí Lábánì fi fún Rákélì ọmọbìnrin rẹ̀. Nígbà tí ó ṣe, ó bí ìwọ̀nyí fún Jékọ́bù; gbogbo ọkàn náà jẹ́ méje.
26 Gbogbo ọkàn tí ó tọ Jékọ́bù wá sí Íjíbítì jẹ́ àwọn tí ó jáde wá láti òkè itan rẹ̀,+ yàtọ̀ sí àwọn aya àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù. Gbogbo ọkàn náà jẹ́ mẹ́rìn-dín-láàádọ́rin.
27 Àwọn ọmọkùnrin Jósẹ́fù tí a bí fún un ní Íjíbítì sì jẹ́ ọkàn méjì. Gbogbo ọkàn ilé Jékọ́bù tí wọ́n wá sí Íjíbítì jẹ́ àádọ́rin.+
28 Ó sì rán Júdà+ ṣíwájú rẹ̀ sí Jósẹ́fù láti fún un ní ìsọfúnni de òun ní Góṣénì. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n dé ilẹ̀ Góṣénì.+
29 Nígbà náà ni Jósẹ́fù múra kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ sílẹ̀, ó sì gòkè lọ láti pàdé Ísírẹ́lì baba rẹ̀ ní Góṣénì.+ Nígbà tí ó yọ sí i, lójú-ẹsẹ̀ ni ó gbórí lé e lọ́rùn, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí da omijé sí i lọ́rùn léraléra.+
30 Níkẹyìn, Ísírẹ́lì wí fún Jósẹ́fù pé: “Ní báyìí, mo múra tán láti kú,+ nísinsìnyí tí mo ti rí ojú rẹ, níwọ̀n bí o ti wà láàyè síbẹ̀.”
31 Nígbà náà ni Jósẹ́fù wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ àti fún agbo ilé baba rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí n gòkè lọ ròyìn fún Fáráò, kí n sì wí fún un pé,+ ‘Àwọn arákùnrin mi àti agbo ilé baba mi tí ó wà ní ilẹ̀ Kénáánì ti dé sọ́dọ̀ mi níhìn-ín.+
32 Àwọn ènìyàn náà sì jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn,+ nítorí pé wọ́n jẹ́ olùsin ohun ọ̀sìn;+ agbo ẹran wọn àti ọ̀wọ́ ẹran wọn àti gbogbo ohun tí wọ́n ní ni wọ́n sì ti kó wá síhìn-ín.’+
33 Ohun tí yóò sì ṣẹlẹ̀ ni pé, nígbà tí Fáráò bá pè yín, tí ó sì wí ní tòótọ́ pé, ‘Kí ni iṣẹ́ àjókòótì yín?’
34 Kí ẹ sọ pé, ‘Àwa ìránṣẹ́ rẹ ti ń bá a lọ láti jẹ́ olùsin ohun ọ̀sìn láti ìgbà èwe wa títí di ìsinsìnyí, àti àwa àti àwọn baba ńlá wa,’+ kí ẹ bàa lè máa gbé ní ilẹ̀ Góṣénì,+ nítorí pé gbogbo olùda àgùntàn jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Íjíbítì.”+

