Jẹ́nẹ́sísì 44:1-34

44  Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ fún ọkùnrin tí ó jẹ́ olórí ilé rẹ̀+ pé: “Fi oúnjẹ kún àpò àwọn ọkùnrin náà dé ìwọ̀n tí wọ́n lè rù, kí o sì fi owó olúkúlùkù sí ẹnu àpò rẹ̀.+  Ṣùgbọ́n kí o fi ife mi, ife fàdákà, sí ẹnu àpò àbíkẹ́yìn, àti owó hóró ọkà rẹ̀.” Nítorí náà, ó ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jósẹ́fù sọ.+  Ilẹ̀ ti mọ́ nígbà tí a rán àwọn ọkùnrin náà lọ,+ àti àwọn àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn.  Wọ́n jáde lọ kúrò ní ìlú ńlá náà. Wọn kò tíì lọ jìnnà nígbà tí Jósẹ́fù sọ fún ọkùnrin tí ó jẹ́ olórí ilé rẹ̀ pé: “Dìde! Lépa àwọn ọkùnrin náà kí o sì rí i dájú pé o lé wọn bá, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Èé ṣe tí ẹ fi fi búburú san rere padà?+  Èyí ha kọ́ ni ohun tí ọ̀gá mi fi ń mu nǹkan àti èyí tí ó fi ń mọ àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́nà jíjáfáfá?+ Ìwà búburú ni ẹ hù yìí.’”  Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó lé wọn bá, ó sì sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún wọn.  Ṣùgbọ́n wọ́n wí fún un pé: “Èé ṣe tí olúwa mi fi sọ̀rọ̀ báyìí? Kò ṣeé ronú kàn pé kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ ṣe ohunkóhun bí èyí.  Họ́wù, owó tí a rí ní ẹnu àpò wa ni a mú padà wá fún ọ láti ilẹ̀ Kénáánì.+ Báwo wá ni a ṣe lè jí fàdákà tàbí wúrà ní ilé ọ̀gá rẹ?+  Jẹ́ kí ẹni tí a bá rí i lọ́wọ́ rẹ̀ nínú àwọn ẹrú rẹ kú, kí o sì jẹ́ kí àwa fúnra wa di ẹrú ọ̀gá mi.”+ 10  Nípa bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Kí ó rí bẹ́ẹ̀ gan-an nísinsìnyí bí ọ̀rọ̀ yín.+ Nípa báyìí, ẹni tí a bá rí i lọ́wọ́ rẹ̀ yóò di ẹrú mi,+ ṣùgbọ́n ẹ̀yin ní tiyín yóò di ẹni tí a kà sí aláìmọwọ́-mẹsẹ̀.” 11  Pẹ̀lú ìyẹn, olúkúlùkù wọn yára sọ àpò rẹ̀ kalẹ̀, olúkúlùkù wọn sì ṣí àpò tirẹ̀. 12  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fẹ̀sọ̀ wá a. Ó bẹ̀rẹ̀ lọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n pátápátá, ó sì parí sọ́dọ̀ àbíkẹ́yìn. Níkẹyìn, a rí ife náà nínú àpò Bẹ́ńjámínì.+ 13  Nígbà náà ni wọ́n gbọn aṣọ àlàbora+ wọn ya, olúkúlùkù wọn sì gbé ẹrù rẹ̀ padà sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, wọ́n sì padà sí ìlú ńlá náà. 14  Júdà+ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ sì lọ sí ilé Jósẹ́fù, òun ṣì wà níbẹ̀; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wólẹ̀ níwájú rẹ̀.+ 15  Wàyí o, Jósẹ́fù sọ fún wọn pé: “Irú ìwà wo ni èyí tí ẹ hù yìí? Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé irú ènìyàn bí èmi lè mọ àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́nà jíjáfáfá?”+ 16  Látàrí èyí, Júdà figbe ta pé: “Kí ni àwa yóò wí fún ọ̀gá mi? Kí ni kí a sọ? Báwo sì ni a ṣe lè fi ara wa hàn ní olódodo?+ Ọlọ́run tòótọ́ ti rí ìṣìnà àwọn ẹrú rẹ̀.+ Kíyè sí i, àwa jẹ́ ẹrú ọ̀gá mi,+ àti àwa àti ẹni tí a rí ife náà ní ọwọ́ rẹ̀!” 17  Bí ó ti wù kí ó rí, ó sọ pé: “Kò ṣeé ronú kan fún mi láti ṣe èyí!+ Ọkùnrin tí a rí ife náà ní ọwọ́ rẹ̀ ni yóò di ẹrú fún mi.+ Ní ti ẹ̀yin yòókù, ẹ gòkè lọ sọ́dọ̀ baba yín ní àlàáfíà.”+ 18  Wàyí o, Júdà sún mọ́ ọn, ó sì wí pé: “Mo bẹ̀ ọ́, ọ̀gá mi, jọ̀wọ́ jẹ́ kí ẹrú rẹ sọ ọ̀rọ̀ kan ní etí-ìgbọ́ ọ̀gá mi,+ má sì ṣe jẹ́ kí ìbínú+ rẹ ru sí ẹrú rẹ, nítorí pé bákan náà ni ìwọ àti Fáráò.+ 19  Ọ̀gá mi béèrè lọ́wọ́ àwọn ẹrú rẹ̀ pé, ‘Ṣé ẹ ní baba tàbí arákùnrin?’ 20  A sì sọ fún ọ̀gá mi pé, ‘A ní baba àgbàlagbà àti ọmọ ọjọ́ ogbó rẹ̀ kan, àbíkẹ́yìn.+ Ṣùgbọ́n arákùnrin rẹ̀ ti kú, tí ó fi jẹ́ pé òun nìkan ṣoṣo ni ó ṣẹ́ kù fún ìyá rẹ̀,+ baba rẹ̀ sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.’ 21  Lẹ́yìn ìyẹn, o sọ fún àwọn ẹrú rẹ pé, ‘Ẹ mú un wá fún mi, kí n lè fi ojú mi kàn án.’+ 22  Ṣùgbọ́n a sọ fún ọ̀gá mi pé, ‘Ọmọdékùnrin náà kò lè fi baba rẹ̀ sílẹ̀. Bí ó bá fi baba rẹ̀ sílẹ̀, òun yóò kú dájúdájú.’+ 23  Nígbà náà ni o wí fún àwọn ẹrú rẹ pé, ‘Bí kò ṣe pé arákùnrin yín àbíkẹ́yìn bá wá pẹ̀lú yín, ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ rí ojú mi mọ́.’+ 24  “Ó sì ṣẹlẹ̀ pé a lọ sí ọ̀dọ̀ ẹrú rẹ, baba mi, a sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ ọ̀gá mi fún un. 25  Lẹ́yìn náà, baba wa wí pé, ‘Ẹ padà, ẹ ra oúnjẹ díẹ̀ fún wa.’+ 26  Ṣùgbọ́n a sọ fún un pé, ‘Kò lè ṣeé ṣe fún wa láti sọ̀ kalẹ̀ lọ. Bí arákùnrin wa àbíkẹ́yìn bá wà pẹ̀lú wa àwa yóò lọ, nítorí pé kò lè ṣeé ṣe fún wa láti rí ojú ọkùnrin náà bí arákùnrin wa àbíkẹ́yìn kò bá wà pẹ̀lú wa.’+ 27  Nígbà náà ni ẹrú rẹ, baba mi, sọ fún wa pé, ‘Ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ dáadáa pé ọmọkùnrin méjì péré ni aya mi bí fún mi.+ 28  Lẹ́yìn náà, ọ̀kan jáde lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, mo sì figbe ta pé: “Áà, a ti ní láti fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ!”+ èmi kò sì rí i títí di ìsinsìnyí. 29  Bí ẹ̀yin bá mú eléyìí náà kúrò ní iwájú mi, tí jàǹbá aṣekúpani sì ṣẹlẹ̀ sí i, ìyọnu àjálù ni ẹ̀yin yóò fi mú ewú mi sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú Ṣìọ́ọ̀lù.’+ 30  “Wàyí o, gbàrà tí mo bá sì ti dé ọ̀dọ̀ ẹrú rẹ, baba mi, láìsí ọmọdékùnrin náà pẹ̀lú wa, nígbà tí ó jẹ́ pé ọkàn ẹni yẹn fà mọ́ ọkàn ẹni yìí,+ 31  nígbà náà, ó dájú pé yóò ṣẹlẹ̀ pé gbàrà tí ó bá ti rí i pé ọmọdékùnrin náà kò sí níbẹ̀, òun yóò wulẹ̀ kú ni, àwọn ẹrú rẹ yóò sì mú ewú ẹrú rẹ, baba wa, lọ sínú Ṣìọ́ọ̀lù pẹ̀lú ẹ̀dùn-ọkàn. 32  Nítorí ẹrú rẹ ṣe onídùúró+ fún ọmọdékùnrin náà nígbà tí ó fi ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ sílẹ̀, pé, ‘Bí mo bá kùnà láti mú un padà wá fún ọ, nígbà náà, èmi yóò ti ṣẹ̀ sí baba mi títí láé.’+ 33  Ǹjẹ́ nísinsìnyí, jọ̀wọ́, jẹ́ kí ẹrú rẹ dúró bí ẹrú fún ọ̀gá mi dípò ọmọdékùnrin náà, kí ọmọdékùnrin náà lè gòkè lọ pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀.+ 34  Nítorí báwo ni èmi yóò ṣe lọ sọ́dọ̀ baba mi láìsí ọmọdékùnrin náà pẹ̀lú mi, kí ó má bàa wá di pé èmi yóò wo ìyọnu àjálù tí yóò dé bá baba mi?”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé