Jẹ́nẹ́sísì 38:1-30
38 Wàyí o, láàárín àkókò náà, ó ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Júdà lọ kúrò lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, ó pa àgọ́ rẹ̀ sí tòsí ọkùnrin kan, ará Ádúlámù,+ orúkọ rẹ̀ sì ni Hírà.
2 Ibẹ̀ sì ni Júdà ti wá rí ọmọbìnrin kan, ọmọ Kénáánì,+ orúkọ rẹ̀ sì ni Ṣúà. Nítorí náà, ó fẹ́ ẹ, ó sì ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.
3 Ó sì lóyún. Lẹ́yìn náà, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Éérì.+
4 Ó tún lóyún. Nígbà tí ó ṣe, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ónánì.
5 Síbẹ̀, nígbà tí ó yá, ó tún bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ṣélà. Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé ó wà ní Ákísíbù ní àkókò tí ó bí i.+
6 Nígbà tí ó ṣe, Júdà fẹ́ aya fún Éérì àkọ́bí rẹ̀, orúkọ rẹ̀ sì ni Támárì.+
7 Ṣùgbọ́n Éérì, àkọ́bí Júdà, jẹ́ ẹni búburú ní ojú Jèhófà;+ nítorí èyí, Jèhófà fi ikú pa á.+
8 Nítorí ìyẹn, Júdà sọ fún Ónánì pé: “Ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú aya arákùnrin rẹ, kí o sì ṣú u lópó, kí o sì gbé ọmọ dìde fún arákùnrin rẹ.”+
9 Ṣùgbọ́n Ónánì mọ̀ pé ọmọ náà kì yóò jẹ́ ti òun;+ ó sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí ó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú aya arákùnrin rẹ̀ ní tòótọ́, ó fi àtọ̀ rẹ̀ ṣòfò sórí ilẹ̀, kí ó má bàa fi ọmọ fún arákùnrin rẹ̀.+
10 Wàyí o, ohun tí ó ṣe burú ní ojú Jèhófà;+ nítorí èyí, ó fi ikú pa òun pẹ̀lú.+
11 Nítorí náà, Júdà sọ fún Támárì aya ọmọ rẹ̀ pé: “Máa gbé gẹ́gẹ́ bí opó ní ilé baba rẹ títí di ìgbà tí Ṣélà ọmọkùnrin mi yóò fi dàgbà.”+ Nítorí ó wí fún ara rẹ̀ pé: “Òun pẹ̀lú lè kú bí ti àwọn arákùnrin rẹ̀.”+ Nítorí náà, Támárì lọ, ó sì ń bá a lọ láti máa gbé ní ilé baba rẹ̀.+
12 Nípa báyìí, ọjọ́ di púpọ̀, ọmọbìnrin Ṣúà, aya Júdà,+ sì kú; Júdà sì pa sáà ṣíṣọ̀fọ̀ mọ́.+ Lẹ́yìn ìyẹn, òun àti Hírà alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, ará Ádúlámù,+ gòkè lọ sọ́dọ̀ àwọn olùrẹ́run àgùntàn rẹ̀, ní Tímúnà.+
13 Nígbà náà ni a sọ fún Támárì pé: “Kíyè sí i, baba ọkọ rẹ ń gòkè lọ sí Tímúnà láti rẹ́ irun àwọn àgùntàn rẹ̀.”+
14 Pẹ̀lú ìyẹn, ó bọ́ ẹ̀wù ìgbà opó rẹ̀ kúrò ní ara rẹ̀, ó sì fi ìborùn bo ara rẹ̀, ó sì fi ìbòjú bo ojú rẹ̀, ó sì jókòó ní ẹnu ọ̀nà Énáímù, èyí tí ó wà ní ojú ọ̀nà Tímúnà. Nítorí ó rí i pé Ṣélà ti dàgbà, síbẹ̀ a kò tíì fi òun fún un gẹ́gẹ́ bí aya.+
15 Nígbà tí Júdà tajú kán rí i, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó fi í pe aṣẹ́wó,+ nítorí pé ó bò ojú rẹ̀.+
16 Nítorí náà, ó yà sọ́dọ̀ rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ojú ọ̀nà, ó sì wí pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ.”+ Nítorí tí kò mọ̀ pé aya ọmọ òun ni.+ Bí ó ti wù kí ó rí, ó wí pé: “Kí ni ìwọ yóò fún mi kí o lè ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú mi?”+
17 Ó fèsì pé: “Èmi yóò fi ọmọ ewúrẹ́ láti inú ọ̀wọ́ ẹran ránṣẹ́.” Ṣùgbọ́n obìnrin náà wí pé: “Ìwọ yóò ha fi ohun ìdúró fún mi títí di ìgbà tí ìwọ yóò fi fi í ránṣẹ́ bí?”+
18 Ọkùnrin náà sì ń bá a lọ pé: “Kí ni ohun ìdúró tí èmi yóò fún ọ?” obìnrin náà dáhùn pé: “Òrùka èdìdì+ rẹ àti okùn rẹ àti ọ̀pá rẹ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ.” Nígbà náà ni ó fi wọ́n fún un, ó sì ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì lóyún fún un.
19 Lẹ́yìn ìyẹn, ó dìde, ó si lọ, ó sì mú ìborùn rẹ̀ kúrò, ó sì wọ ẹ̀wù ìgbà opó rẹ̀.+
20 Júdà sì tẹ̀ síwájú láti fi ọmọ ewúrẹ́ ránṣẹ́ láti ọwọ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ará Ádúlámù,+ kí ó bàa lè gba ohun ìdúró náà padà ní ọwọ́ obìnrin náà, ṣùgbọ́n òun kò rí i.
21 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wádìí lọ́wọ́ àwọn ènìyàn nípa ibi tí obìnrin náà wà, pé: “Ibo ni kárùwà inú tẹ́ńpìlì ní Énáímù ní ojú ọ̀nà yẹn wà?” Ṣùgbọ́n wọ́n ń wí pé: “Kò sí kárùwà inú tẹ́ńpìlì+ tí ó tíì gbé ibí yìí rí.”
22 Níkẹyìn, ó padà sọ́dọ̀ Júdà, ó sì wí pé: “Èmi kò rí i, àti pé, àwọn ènìyàn ibẹ̀ sọ pé, ‘Kò sí kárùwà inú tẹ́ńpìlì tí ó tíì gbé ibẹ̀ rí.’”
23 Nítorí náà, Júdà wí pé: “Jẹ́ kí ó sọ wọ́n di tirẹ̀, kí a má bàa di ẹni ìfojú-tín-ín-rín.+ Bí ó ti wù kí ó rí, mo ti fi ọmọ ewúrẹ́ yìí ránṣẹ́, ṣùgbọ́n ìwọ—ìwọ kò rí i.”
24 Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣẹlẹ̀ pé ní nǹkan bí oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà, a sọ fún Júdà pé: “Támárì aya ọmọ rẹ ti ṣe aṣẹ́wó,+ sì kíyè sí i, ó ti lóyún+ nídìí iṣẹ́ aṣẹ́wó rẹ̀.” Látàrí èyí, Júdà wí pé: “Ẹ mú un jáde kí a sì sun ún.”+
25 Bí a ti mú un jáde, òun fúnra rẹ̀ sì ránṣẹ́ sí baba ọkọ rẹ̀, pé: “Ọkùnrin tí ìwọ̀nyí jẹ́ tirẹ̀ ni mo lóyún fún.”+ Ó sì fi kún un pé: “Jọ̀wọ́, ṣàyẹ̀wò+ ẹni tí ó ni ìwọ̀nyí, òrùka èdìdì yìí àti okùn yìí àti ọ̀pá yìí.”+
26 Nígbà náà, Júdà ṣàyẹ̀wò wọn, ó sì wí pé:+ “Ó jẹ́ olódodo jù mí lọ,+ nítorí ìdí náà pé èmi kò fi í fún Ṣélà ọmọkùnrin mi.”+ Ọkùnrin náà kò sì ní ìbádàpọ̀ kankan mọ́ pẹ̀lú rẹ̀ lẹ́yìn èyíinì.+
27 Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé ní àkókò tí ó ń bímọ, họ́wù, ìbejì ni ó wà ní ikùn rẹ̀.
28 Síwájú sí i, ó ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí ó ń bímọ, ọ̀kan na ọwọ́ jáde, agbẹ̀bí sì yára so ìrépé rírẹ̀dòdò mọ́ ọwọ́ rẹ̀, pé: “Èyí ni ó kọ́kọ́ jáde.”
29 Níkẹyìn, ó ṣẹlẹ̀ pé kété tí ó fa ọwọ́ rẹ̀ sẹ́yìn, họ́wù, kíyè sí i, arákùnrin rẹ̀ jáde, tí obìnrin náà fi fi ìyàlẹ́nu sọ pé: “Kí ni ìwọ ní lọ́kàn, tí o fi fa abẹ́ yíya fún ara rẹ?” Nítorí náà, a pe orúkọ rẹ̀ ní Pérésì.+
30 Lẹ́yìn náà, arákùnrin rẹ̀, ẹni tí ìrépé rírẹ̀dòdò wà ní ọwọ́ rẹ̀ jáde wá, a sì pe orúkọ rẹ̀ ní Síírà.+

