Jẹ́nẹ́sísì 32:1-32

32  Ní ti Jékọ́bù, ó ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run sì wá bá a pàdé.+  Nígbà tí ó rí wọn, Jékọ́bù wí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé: “Ibùdó Ọlọ́run ni èyí!”+ Nítorí náà, ó pe orúkọ ibẹ̀ ní Máhánáímù.+  Nígbà náà, Jékọ́bù rán àwọn ońṣẹ́+ ṣáájú ara rẹ̀ sí Ísọ̀ arákùnrin rẹ̀ ní ilẹ̀ Séírì,+ pápá Édómù,+  ó sì pàṣẹ fún wọn pé: “Èyí ni ohun tí ẹ̀yin yóò wí fún olúwa mi,+ fún Ísọ̀, ‘Èyí ni ohun tí ìránṣẹ́ rẹ Jékọ́bù wí: “Ọ̀dọ̀ Lábánì ni mo ti ṣe àtìpó, mo sì ti wà níbẹ̀ fún àkókò gígùn títí di ìsinsìnyí.+  Mo sì wá ní àwọn akọ màlúù àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn àgùntàn, àti àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin,+ èmi yóò sì fẹ́ láti ránṣẹ́ láti fi tó olúwa mi létí, kí n lè rí ojú rere ní ojú rẹ.”’”+  Nígbà tí ó ṣe, àwọn ońṣẹ́ náà padà tọ Jékọ́bù wá pé: “A dé ọ̀dọ̀ arákùnrin rẹ Ísọ̀, òun pẹ̀lú sì ń bá ọ̀nà rẹ̀ bọ̀ láti pàdé rẹ, ti òun ti irínwó ọkùnrin.”+  Àyà sì fo Jékọ́bù gidigidi, ó sì ṣàníyàn.+ Nítorí náà, ó pín àwọn ènìyàn tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, àti àwọn agbo ẹran àti àwọn màlúù àti àwọn ràkúnmí sí ibùdó méjì,+  ó sì wí pé: “Bí Ísọ̀ bá wá bá ibùdó kan tí ó sì fipá kọlù ú, nígbà náà, ó dájú pé ibùdó kan yóò ṣẹ́ kù láti sá àsálà.”+  Lẹ́yìn ìyẹn, Jékọ́bù wí pé: “Ìwọ Ọlọ́run Ábúráhámù baba mi àti Ọlọ́run Ísákì baba mi,+ Jèhófà, ìwọ tí o sọ fún mi pé, ‘Padà sí ilẹ̀ rẹ àti sọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, èmi yóò sì ṣe dáadáa sí ọ,’+ 10  èmi kò yẹ fún gbogbo inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti gbogbo ìṣòtítọ́ tí o ti ṣe sí ìránṣẹ́ rẹ,+ nítorí pẹ̀lú ọ̀pá mi nìkan ṣoṣo ni mo sọdá Jọ́dánì yìí, mo sì ti di ibùdó méjì nísinsìnyí.+ 11  Mo bẹ̀ ọ́, dá mi nídè+ lọ́wọ́ arákùnrin mi, lọ́wọ́ Ísọ̀, nítorí tí àyà rẹ̀ ń fò mí, pé ó lè dé, kí ó sì fipá kọlù mí dájúdájú,+ àti ìyá àti àwọn ọmọ mi. 12  Àti pé ìwọ, ìwọ ti sọ pé, ‘Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, èmi yóò ṣe dáadáa sí ọ, èmi yóò sì mú irú-ọmọ rẹ dà bí àwọn egunrín iyanrìn òkun, tí kì yóò níye nítorí jíjẹ́ ògìdìgbó.’”+ 13  Ó sì ń bá a nìṣó láti wọ̀ sí ibẹ̀ ní òru yẹn. Lára ohun tí ó sì bọ́ sí i lọ́wọ́ ni ó ti bẹ̀rẹ̀ sí mú ẹ̀bùn fún Ísọ̀ arákùnrin rẹ̀:+ 14  igba abo ewúrẹ́ àti ogún òbúkọ, igba abo àgùntàn àti ogún àgbò, 15  ọgbọ̀n ràkúnmí tí ń fọ́mọ lọ́mú àti àwọn ọmọ wọn, ogójì abo màlúù àti akọ màlúù mẹ́wàá, ogún abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tí ó ti dàgbà tán.+ 16  Nígbà náà, ó fi agbo ẹran ọ̀sìn kan tẹ̀ lé òmíràn lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ léraléra pé: “Ẹ sọdá níwájú mi, kí ẹ sì fi àlàfo sílẹ̀ láàárín agbo ẹran ọ̀sìn àti agbo ẹran ọ̀sìn.”+ 17  Síwájú sí i, ó pàṣẹ fún èyí àkọ́kọ́, pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé Ísọ̀ arákùnrin mi pàdé rẹ tí ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ pé, ‘Ti ta ni ìwọ, ibo sì ni o ń lọ, ti ta sì ni ìwọ̀nyí tí ó wà níwájú rẹ?’ 18  nígbà náà, kí o wí pé, ‘Ti ìránṣẹ́ rẹ, Jékọ́bù ni. Ẹ̀bùn ni,+ tí a fi ránṣẹ́ sí olúwa mi,+ sí Ísọ̀, sì wò ó! òun fúnra rẹ̀ wà lẹ́yìn wa pẹ̀lú.’” 19  Ó sì pàṣẹ fún èkejì, àti fún ẹ̀kẹta pẹ̀lú, àti fún gbogbo àwọn tí ń tẹ̀ lé agbo ẹran ọ̀sìn náà pé: “Ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ yìí ni kí ẹ sọ fún Ísọ̀ nígbà tí ẹ bá bá a pàdé.+ 20  Kí ẹ sì tún wí pé, ‘Kíyè sí i, ìránṣẹ́ rẹ Jékọ́bù wà lẹ́yìn wa.’”+ Nítorí ó sọ fún ara rẹ̀ pé: “Mo lè fi ẹ̀bùn tí ń lọ ṣáájú mi tù ú lójú,+ àti lẹ́yìn ìgbà náà èmi yóò rí ojú rẹ̀. Bóyá yóò fi inú rere tẹ́wọ́ gbà mí.”+ 21  Nípa báyìí, ẹ̀bùn náà bẹ̀rẹ̀ sí sọdá ṣáájú rẹ̀, ṣùgbọ́n òun fúnra rẹ̀ wọ̀ sí ibùdó ní òru yẹn.+ 22  Lẹ́yìn náà, ní òru yẹn, ó dìde, ó sì mú àwọn aya rẹ̀ méjèèjì+ àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ méjèèjì+ àti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ̀ mọ́kọ̀ọ̀kànlá,+ ó sì sọdá sí ibi pẹ́ṣẹ́pẹ́ṣẹ́ odò Jábókù.+ 23  Nítorí náà, ó kó wọn, ó sì kó wọn kọjá àfonífojì olójú ọ̀gbàrá,+ ó sì kó ohun tí ó ní kọjá. 24  Níkẹyìn, ó ṣẹ́ ku Jékọ́bù ní òun nìkan. Nígbà náà ni ọkùnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí wọ ìwàyá ìjà pẹ̀lú rẹ̀ títí di ìgbà tí ọ̀yẹ̀ là.+ 25  Nígbà tí ó rí i pé òun kò borí rẹ̀,+ ó fọwọ́ kan ojúhò oríkèé itan rẹ̀; ojúhò oríkèé itan Jékọ́bù sì yẹ̀ nígbà tí ó ń wọ ìwàyá ìjà pẹ̀lú rẹ̀.+ 26  Lẹ́yìn ìyẹn, ó wí pé: “Jẹ́ kí n lọ, nítorí ọ̀yẹ̀ ti là.” Ó fèsì pé: “Èmi kò ní jẹ́ kí o lọ, àyàfi tí o bá kọ́kọ́ súre fún mi.”+ 27  Nítorí náà, ó sọ fún un pé: “Kí ni orúkọ rẹ?” ó dáhùn pé: “Jékọ́bù.” 28  Nígbà náà, ó wí pé: “A kì yóò pe orúkọ rẹ ní Jékọ́bù mọ́ bí kò ṣe Ísírẹ́lì,+ nítorí ìwọ ti bá Ọlọ́run àti ènìyàn wọ̀jà,+ o sì borí lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.” 29  Ẹ̀wẹ̀, Jékọ́bù wádìí, ó sì wí pé: “Jọ̀wọ́, sọ orúkọ rẹ fún mi.” Bí ó ti wù kí ó rí, òun sọ pé: “Èé ṣe tí o fi ń wádìí orúkọ mi?”+ Pẹ̀lú ìyẹn, ó súre fún un níbẹ̀. 30  Nítorí náà, Jékọ́bù pe orúkọ ibẹ̀ ní Péníélì,+ nítorí pé, láti fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ, “Mo ti rí Ọlọ́run ní ojúkojú, síbẹ̀ a dá ọkàn mi nídè.”+ 31  Oòrùn sì bẹ̀rẹ̀ sí ràn sára rẹ̀ ní gbàrà tí ó kọjá Pénúélì, ṣùgbọ́n ó ń tiro lórí itan rẹ̀.+ 32  Ìdí nìyẹn tí kì í fi í ṣe àṣà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti máa jẹ fọ́nrán iṣan itan, tí ó wà lára ojúhò oríkèé itan, títí di òní yìí, nítorí pé ó fọwọ́ kan ojúhò oríkèé itan Jékọ́bù níbi fọ́nrán iṣan itan.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé