Jẹ́nẹ́sísì 23:1-20

23  Ọdún ìgbésí ayé Sárà sì wá jẹ́ mẹ́tà-dín-láàádóje ní gígùn. Wọ́n jẹ́ ọdún ìgbésí ayé Sárà.+  Nítorí náà, Sárà kú ní Kiriati-ábà,+ èyíinì ni, Hébúrónì,+ ní ilẹ̀ Kénáánì,+ Ábúráhámù sì wọlé láti pohùn réré ẹkún Sárà àti láti sunkún lórí rẹ̀.  Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù dìde kúrò níwájú òkú rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn ọmọ Hétì,+ pé:  “Àtìpó àti olùtẹ̀dó ni mo jẹ́ láàárín yín.+ Ẹ fún mi ní ibi ìsìnkú gẹ́gẹ́ bí ohun ìní láàárín yín kí n lè sin òkú mi kúrò ní iwájú mi.”+  Látàrí èyí, àwọn ọmọ Hétì dá Ábúráhámù lóhùn, ní wíwí fún un pé:  “Gbọ́ wa, olúwa mi.+ Ìjòyè Ọlọ́run ni ìwọ jẹ́ ní àárín wa.+ Ibi tí ó jẹ́ ààyò jù lọ nínú àwọn ibi ìsìnkú wa ni kí o sin òkú rẹ sí.+ Kò sí ẹnì kankan lára wa ti yóò fawọ́ ibi ìsìnkú rẹ̀ sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ láti ṣèdíwọ́ fún sísin òkú rẹ.”+  Nígbà náà, Ábúráhámù dìde, ó sì tẹrí ba fún àwọn ọmọ ìbílẹ̀+ náà, fún àwọn ọmọ Hétì,+  ó sì bá wọn sọ̀rọ̀, pé: “Bí ọkàn yín bá gbà bẹ́ẹ̀ láti sin òkú mi kúrò ní iwájú mi, ẹ fetí sí mi kí ẹ sì bá mi rọ Éfúrónì ọmọkùnrin Sóhárì,+  kí ó lè fún mi ní hòrò Mákípẹ́là,+ èyí tí ó jẹ́ tirẹ̀, tí ó wà ní ìkangun pápá rẹ̀. Ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye fàdákà ni kí ó fi í fún mi ní àárín yín fún ibi ìsìnkú gẹ́gẹ́ bí ohun ìní.”+ 10  Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí, Éfúrónì jókòó láàárín àwọn ọmọ Hétì. Nítorí náà, Éfúrónì ọmọ Hétì+ dá Ábúráhámù lóhùn ní etí-ìgbọ́ àwọn ọmọ Hétì pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ń wọ ẹnubodè ìlú ńlá rẹ̀, pé:+ 11  “Bẹ́ẹ̀ kọ́, olúwa mi! Fetí sí mi. Pápá náà ni mo fi fún ọ, ìwọ ni mo sì fi hòrò tí ó wà nínú rẹ̀ fún. Lójú àwọn ọmọ àwọn ènìyàn mi ni mo fi í fún ọ.+ Sin òkú rẹ.” 12  Látàrí ìyẹn, Ábúráhámù tẹrí ba níwájú àwọn ọmọ ìbílẹ̀, 13  ó sì sọ fún Éfúrónì ní etí-ìgbọ́ àwọn ọmọ ìbílẹ̀ náà, pé: “Kìkì bí ìwọ bá—rárá, fetí sí mi! Èmi yóò fún ọ ní iye fàdákà fún pápá náà. Gbà á ní ọwọ́ mi,+ kí n lè sin òkú mi níbẹ̀.” 14  Nígbà náà ni Éfúrónì dá Ábúráhámù lóhùn, ó wí fún un pé: 15  “Olúwa mi, fetí sí mi. Ilẹ̀ bíírí tí iye rẹ̀ tó irínwó ṣékélì fàdákà, kí ni ìyẹn jẹ́ láàárín èmi àti ìwọ? Nítorí náà, sin òkú rẹ.”+ 16  Nítorí náà, Ábúráhámù fetí sí Éfúrónì, Ábúráhámù sì wọn iye fàdákà tí ó sọ ní etí-ìgbọ́ àwọn ọmọ Hétì fún Éfúrónì, irínwó ṣékélì fàdákà tí àwọn olówò ń ná nígbà yẹn.+ 17  Nípa báyìí, pápá Éfúrónì tí ó wà ní Mákípẹ́là, èyí tí ó wà ní iwájú Mámúrè, àti pápá àti hòrò tí ó wà nínú rẹ̀ àti gbogbo igi tí ó wà nínú pápá náà,+ èyí tí ó wà nínú gbogbo ààlà rẹ̀ yí ká, ni a fìdí òtítọ́ rẹ̀ múlẹ̀+ 18  fún Ábúráhámù gẹ́gẹ́ bí dúkìá tí ó rà lójú àwọn ọmọ Hétì láàárín gbogbo àwọn tí ń wọ ẹnubodè ìlú ńlá rẹ̀.+ 19  Lẹ́yìn ìyẹn, Ábúráhámù sì sin Sárà aya rẹ̀ sínú hòrò pápá Mákípẹ́là ní iwájú Mámúrè, èyíinì ni, Hébúrónì, ní ilẹ̀ Kénáánì.+ 20  Nípa báyìí, a fìdí òtítọ́ pápá náà àti hòrò tí ó wà nínú rẹ̀ múlẹ̀ fún Ábúráhámù fún ibi ìsìnkú gẹ́gẹ́ bí ohun ìní láti ọwọ́ àwọn ọmọ Hétì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé