Jẹ́nẹ́sísì 2:1-25

2  Bí ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn ṣe wá sí àṣeparí nìyẹn.+  Àti ní ọjọ́ keje, Ọlọ́run dé àṣeparí iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ti ṣe, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ti ṣe.+  Ọlọ́run sì tẹ̀ síwájú láti bù kún ọjọ́ keje, ó sì ṣe é ní ọlọ́wọ̀, nítorí pé inú rẹ̀ ni ó ti ń sinmi kúrò nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ tí Ọlọ́run ti dá fún ète ṣíṣe.+  Èyí ni ọ̀rọ̀-ìtàn nípa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé ní àkókò dídá wọn, ní ọjọ́ tí Jèhófà Ọlọ́run ṣe ilẹ̀ ayé àti ọ̀run.+  Wàyí o, kò tíì sí igi kéékèèké tí ó wà ní ilẹ̀ ayé, kò sì sí ewéko kankan tí ó tíì rú jáde, nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run kò tíì mú kí òjò+ rọ̀ sórí ilẹ̀ ayé, kò sì sí ènìyàn kankan láti ro ilẹ̀.  Ṣùgbọ́n ìkùukùu+ a máa gòkè lọ láti inú ilẹ̀ ayé, a sì bomi rin ojú gbogbo ilẹ̀.+  Jèhófà Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ̀dá ọkùnrin náà láti inú ekuru+ ilẹ̀,+ ó sì fẹ́ èémí ìyè+ sínú ihò imú rẹ̀, ọkùnrin náà sì wá di alààyè ọkàn.+  Síwájú sí i, Jèhófà Ọlọ́run gbin ọgbà kan ní Édẹ́nì,+ síhà ìlà-oòrùn, ibẹ̀ ni ó sì fi ọkùnrin tí ó ti ṣẹ̀dá sí.+  Nípa báyìí, Jèhófà Ọlọ́run mú kí olúkúlùkù igi tí ó fani mọ́ra ní wíwò, tí ó sì dára fún oúnjẹ hù láti inú ilẹ̀ àti igi ìyè+ pẹ̀lú ní àárín ọgbà náà àti igi ìmọ rere àti búburú.+ 10  Wàyí o, odò kan wà tí ń ṣàn jáde láti Édẹ́nì láti bomi rin ọgbà náà, ibẹ̀ ni ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí pínyà, ó sì di ohun tí a lè pè ní ẹ̀ka mẹ́rin. 11  Orúkọ èyí èkíní ni Píṣónì; òun ni èyí tí ó yí gbogbo ilẹ̀ Háfílà+ ká, níbi tí wúrà wà. 12  Wúrà ilẹ̀ náà sì dára.+ Gọ́ọ̀mù bídẹ́líọ́mù+ àti òkúta ónísì+ wà níbẹ̀ pẹ̀lú. 13  Orúkọ odò kejì sì ni Gíhónì; òun ni èyí tí ó yí gbogbo ilẹ̀ Kúṣì ká. 14  Orúkọ odò kẹta sì ni Hídẹ́kẹ́lì;+ òun ni èyí tí ó lọ sí ìlà-oòrùn Ásíríà.+ Odò kẹrin sì ni Yúfírétì.+ 15  Jèhófà Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti mú ọkùnrin náà, ó sì mú un tẹ̀ dó sínú ọgbà Édẹ́nì+ láti máa ro ó àti láti máa bójú tó o.+ 16  Pẹ̀lúpẹ̀lù Jèhófà Ọlọ́run sì gbé àṣẹ yìí kalẹ̀ fún ọkùnrin náà pé: “Nínú gbogbo igi ọgbà ni kí ìwọ ti máa jẹ àjẹtẹ́rùn.+ 17  Ṣùgbọ́n ní ti igi ìmọ̀ rere àti búburú, ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.”+ 18  Jèhófà Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti wí pé: “Kò dára kí ọkùnrin náà máa wà nìṣó ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un, gẹ́gẹ́ bí àṣekún rẹ̀.”+ 19  Wàyí o, Jèhófà Ọlọ́run ń ṣẹ̀dá gbogbo ẹranko inú pápá àti gbogbo ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run láti inú ilẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mú wọn wá sọ́dọ̀ ọkùnrin náà láti wo ohun tí yóò pe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn; ohun yòówù tí ọkùnrin náà bá sì pè é, alààyè ọkàn+ kọ̀ọ̀kan, ìyẹn ni orúkọ rẹ̀.+ 20  Nítorí náà, ọkùnrin náà ń sọ gbogbo ẹran agbéléjẹ̀ àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti gbogbo ẹranko inú pápá lórúkọ, ṣùgbọ́n fún ènìyàn, kò sí olùrànlọ́wọ́ kankan gẹ́gẹ́ bí àṣekún rẹ̀. 21  Nítorí náà, Jèhófà Ọlọ́run mú kí oorun àsùnwọra+ kun ọkùnrin náà, bí ó sì ti ń sùn lọ́wọ́, ó mú ọ̀kan nínú egungun ìhà rẹ̀, lẹ́yìn náà, ó pa ẹran dé mọ́ àyè rẹ̀. 22  Jèhófà Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí fi egungun ìhà tí ó mú láti inú ara ọkùnrin náà mọ obìnrin, ó sì mú un wá fún ọkùnrin náà.+ 23  Nígbà náà ni ọkùnrin náà sọ pé: “Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, èyí ni egungun nínú àwọn egungun mi Àti ẹran ara nínú ẹran ara mi.+ Obìnrin ni a óò máa pe èyí, Nítorí pé láti ara ọkùnrin ni a ti mú èyí wá.”+ 24  Ìdí nìyẹn tí ọkùnrin yóò ṣe fi baba rẹ̀ àti ìyá+ rẹ̀ sílẹ̀ tí yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.+ 25  Àwọn méjèèjì sì ń bá a lọ láti wà ní ìhòòhò,+ ọkùnrin náà àti aya rẹ̀, síbẹ̀ ojú kò tì wọ́n.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé