Jẹ́nẹ́sísì 18:1-33

18  Lẹ́yìn náà, Jèhófà fara hàn+ án láàárín àwọn igi ńlá Mámúrè,+ nígbà tí ó jókòó ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ní nǹkan bí ìgbà ooru ọjọ́.+ 2  Nígbà tí ó gbé ojú rẹ̀ sókè,+ nígbà náà ni ó wò, sì kíyè sí i, àwọn ọkùnrin mẹ́ta dúró ní ibi tí kò jìnnà sí i. Nígbà tí ó tajú kán rí wọn, ó bẹ̀rẹ̀ sí sáré láti pàdé wọn láti ẹnu ọ̀nà àgọ́, ó sì ń bá a lọ láti tẹrí ba mọ́lẹ̀.+ 3  Lẹ́yìn náà, ó wí pé: “Jèhófà, bí mo bá ti rí ojú rere ní ojú rẹ nísinsìnyí, jọ̀wọ́, má ṣe ré ìránṣẹ́ rẹ kọjá.+ 4  Jẹ́ kí a bu omi díẹ̀, jọ̀wọ́, kí a sì wẹ ẹsẹ̀ yín.+ Lẹ́yìn náà kí ẹ rọ̀gbọ̀kú lábẹ́ àwọn igi.+ 5  Ẹ sì jẹ́ kí n wá búrẹ́dì díẹ̀, kí n sì tu ọkàn-àyà yín lára.+ Lẹ́yìn ìyẹn, ẹ lè kọjá lọ, nítorí pé ìdí tí ẹ fi gba ọ̀nà yìí dé ọ̀dọ̀ ìránṣẹ́ yín nìyẹn.” Látàrí èyí, wọ́n wí pé: “Ó dára. O lè ṣe gẹ́gẹ́ bí o ti sọ.” 6  Nítorí náà, Ábúráhámù lọ wéréwéré sínú àgọ́, sọ́dọ̀ Sárà, ó sì wí pé: “Ṣe wéré! Pèsè òṣùwọ̀n séà mẹ́ta ìyẹ̀fun kíkúnná, po àpòrọ́ kí o sì ṣe àwọn àkàrà ribiti.”+ 7  Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù sáré lọ sáàárín ọ̀wọ́ ẹran, ó sì ń bá a lọ láti mú òṣéṣé ọmọ akọ màlúù tí ó dára kan, ó sì fi í fún ẹmẹ̀wà, ó sì lọ wéréwéré láti pèsè rẹ̀ sílẹ̀.+ 8  Lẹ́yìn náà, ó mú bọ́tà àti wàrà àti ọmọ akọ màlúù tí ó ti pèsè sílẹ̀, ó sì gbé e kalẹ̀ níwájú wọn.+ Lẹ́yìn náà, òun fúnra rẹ̀ ń bá a nìṣó ní dídúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn lábẹ́ igi bí wọ́n ti ń jẹun.+ 9  Wàyí o, wọ́n sọ fún un pé: “Ibo ni Sárà aya rẹ wà?”+ Ó fèsì pé: “Níhìn-ín nínú àgọ́!”+ 10  Nítorí náà, ó ń bá a lọ pé: “Dájúdájú, èmi yóò padà tọ̀ ọ́ wá ní ọdún tí ń bọ̀ ní àkókò yìí, sì wò ó! Sárà aya rẹ yóò bí ọmọkùnrin kan.”+ Wàyí o, Sárà ń fetí sílẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́, èyí sì wà ní ẹ̀yìn ọkùnrin náà. 11  Ábúráhámù àti Sárà sì ti darúgbó, bí wọ́n ti pọ̀ ní ọdún.+ Sárà ti dẹ́kun ṣíṣe nǹkan oṣù.+ 12  Nítorí náà, Sárà bẹ̀rẹ̀ sí rẹ́rìn-ín nínú ara rẹ̀,+ pé: “Lẹ́yìn tí mo ti gbó tán, èmi yóò ha ní ìdùnnú ní ti gidi, tí olúwa mi ti darúgbó pẹ̀lú?”+ 13  Nígbà náà ni Jèhófà wí fún Ábúráhámù pé: “Èé ṣe tí Sárà fi rẹ́rìn-ín, pé, ‘Èmi, ní ti gidi àti ní tòótọ́, yóò ha bímọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti darúgbó?’+ 14  Ohunkóhun ha ṣe àrà ọ̀tọ̀ jù fún Jèhófà bí?+ Ní àkókò tí a yàn kalẹ̀, èmi yóò padà tọ̀ ọ́ wá, ní ọdún tí ń bọ̀ ní àkókò yìí, Sárà yóò sì bí ọmọkùnrin kan.” 15  Ṣùgbọ́n Sárà bẹ̀rẹ̀ sí sẹ́, pé: “Èmi kò rẹ́rìn-ín!” Nítorí tí àyà fò ó. Látàrí èyí, ó wí pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́! ṣùgbọ́n o rẹ́rìn-ín ní tòótọ́.”+ 16  Lẹ́yìn náà, àwọn ọkùnrin náà dìde kúrò níbẹ̀, wọ́n sì bojú wolẹ̀ síhà Sódómù,+ Ábúráhámù sì ń bá wọn rìn láti sìn wọ́n sọ́nà.+ 17  Jèhófà sì wí pé: “Èmi ha ń fi ohun tí èmi yóò ṣe bò fún Ábúráhámù bí?+ 18  Họ́wù, dájúdájú, Ábúráhámù yóò di orílẹ̀-èdè ńlá tí ó lágbára ńlá, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò sì bù kún ara wọn nípasẹ̀ rẹ̀.+ 19  Nítorí tí mo ti di ojúlùmọ̀ rẹ̀ kí ó lè pàṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀ àti agbo ilé rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀ kí wọ́n bàa lè pa ọ̀nà Jèhófà mọ́ láti ṣe òdodo àti ìdájọ́;+ kí Jèhófà bàa lè mú ohun tí ó ti sọ̀ nípa rẹ̀ wá sórí Ábúráhámù.”+ 20  Nítorí náà, Jèhófà wí pé: “Igbe ìráhùn nípa Sódómù àti Gòmórà,+ bẹ́ẹ̀ ni, ó ń dún kíkankíkan, àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ ni, ó rinlẹ̀ gidigidi.+ 21  Mo ti pinnu tán láti sọ̀ kalẹ̀ lọ kí n lè rí bóyá wọ́n hùwà látòkè délẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú igbe ẹkún tí wọ́n ń ké lé e lórí tí ó ti wá sọ́dọ̀ mi, bí kò bá sì jẹ́ bẹ́ẹ̀, èmi a lè mọ̀.”+ 22  Ìgbà yìí ni àwọn ọkùnrin náà yí padà kúrò níbẹ̀, wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n lọ sí Sódómù; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà,+ ó dúró níwájú Ábúráhámù síbẹ̀.+ 23  Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù sún mọ́ ọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Ìwọ, ní ti tòótọ́, yóò ha gbá olódodo lọ pẹ̀lú àwọn ẹni burúkú bí?+ 24  Ká sọ pé àádọ́ta olódodo wà ní àárín ìlú ńlá náà. Nígbà náà, ìwọ yóò ha gbá wọn lọ, tí o kò sì ní dárí ji ibẹ̀ ní tìtorí àádọ́ta olódodo tí wọ́n wà nínú rẹ̀ bí?+ 25  Kò ṣeé ronú kàn nípa rẹ pé o ń gbé ìgbésẹ̀ ní irú ọ̀nà yìí láti fi ikú pa olódodo pẹ̀lú ẹni burúkú tí ó fi jẹ́ pé ó ní láti ṣẹlẹ̀ sí olódodo bí ó ti ń rí fún ẹni burúkú!+ Kò ṣeé ronú kàn nípa rẹ.+ Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé kì yóò ha ṣe ohun tí ó tọ́ bí?”+ 26  Nígbà náà ni Jèhófà wí pé: “Bí èmi bá lè rí àádọ́ta olódodo ní àárín ìlú ńlá náà ní Sódómù, èmi yóò dárí ji gbogbo ibẹ̀ ní tìtorí wọn.”+ 27  Ṣùgbọ́n Ábúráhámù ń bá a lọ láti dáhùn, ó sì wí pé: “Jọ̀wọ́, kíyè sí i, èmi fúnra mi ti dáwọ́ lé bíbá Jèhófà sọ̀rọ̀, nígbà tí ó jẹ́ pé ekuru àti eérú+ ni èmi. 28  Ká sọ pé àádọ́ta olódodo náà bá dín márùn-ún. Ṣé ìwọ yóò run gbogbo ìlú ńlá náà nítorí àwọn márùn-ún náà?” Ó fèsì pé: “Èmi kì yóò run ún bí mo bá rí márùn-dín-láàádọ́ta níbẹ̀.”+ 29  Ṣùgbọ́n, síbẹ̀, ó tún wí fún un síwájú sí i pé: “Ká sọ pé ogójì ni a rí níbẹ̀.” Ẹ̀wẹ̀, ó wí pé: “Èmi kì yóò ṣe é ní tìtorí ogójì.” 30  Ṣùgbọ́n ó ń bá a lọ pé: “Jọ̀wọ́, kí ìbínú+ Jèhófà má ṣe gbóná, ṣùgbọ́n jẹ́ kí n máa bá a lọ láti sọ̀rọ̀:+ Ká sọ pé ọgbọ̀n ni a rí níbẹ̀.” Ẹ̀wẹ̀, ó wí pé: “Èmi kì yóò ṣe é bí mo bá rí ọgbọ̀n níbẹ̀.” 31  Ṣùgbọ́n ó ń bá a lọ pé: “Jọ̀wọ́, kíyè sí i, èmi fúnra mi ti dáwọ́ lé bíbá Jèhófà sọ̀rọ̀:+ Ká sọ pé ogún ni a rí níbẹ̀.” Ẹ̀wẹ̀, ó wí pé: “Èmi kì yóò run ún ní tìtorí ogún.”+ 32  Níkẹyìn, ó wí pé: “Jọ̀wọ́, kí ìbínú+ Jèhófà má ṣe gbóná, ṣùgbọ́n jẹ́ kí n sọ̀rọ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan yìí péré:+ Ká sọ pé mẹ́wàá ni a rí níbẹ̀.” Ẹ̀wẹ̀, ó wí pé: “Èmi kì yóò run ún ní tìtorí mẹ́wàá.”+ 33  Lẹ́yìn náà, Jèhófà+ bá ọ̀nà rẹ̀ lọ nígbà tí ó ti parí bíbá Ábúráhámù sọ̀rọ̀, Ábúráhámù sì padà sí àyè rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé