Jẹ́nẹ́sísì 14:1-24

14  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọjọ́ Ámúráfélì ọba Ṣínárì,+ Áríókù ọba Élásárì, Kedoláómà+ ọba Élámù,+ àti Tídálì ọba Góíímù,+ 2  pé àwọn wọ̀nyí bá Bérà ọba Sódómù,+ àti Bíṣà ọba Gòmórà,+ Ṣínábù ọba Ádímà,+ àti Ṣémébà ọba Sébóíímù,+ àti ọba Bélà (èyíinì ni, Sóárì)+ ja ogun. 3  Gbogbo àwọn wọ̀nyí lọ, gẹ́gẹ́ bí alájọṣepọ̀,+ sí Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Rírẹlẹ̀ Sídímù,+ eyíini ni, Òkun Iyọ̀.+ 4  Ọdún méjìlá ni wọ́n ti fi sin Kedoláómà, ṣùgbọ́n ní ọdún kẹtàlá, wọ́n ṣọ̀tẹ̀. 5  Ní ọdún kẹrìnlá, Kedoláómà sì wá, àti àwọn ọba tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ bákan náà, wọ́n sì ṣẹ́gun Réfáímù ní Aṣiteroti-kánáímù+ àti Súsímù ní Hámù, àti Émímù+ ní Ṣafe-kíríátáímù, 6  àti àwọn Hórì+ ní òkè ńlá Séírì,+ títí dé Eli-páránì,+ tí ó wà ní aginjù. 7  Lẹ́yìn náà, wọ́n yíjú padà, wọ́n sì dé Ẹn-míṣípátì, èyíinì ni, Kádéṣì,+ wọ́n sì ṣẹ́gun gbogbo pápá àwọn ọmọ Ámálékì+ àti àwọn Ámórì+ pẹ̀lú, tí wọ́n ń gbé ní Hasasoni-támárì.+ 8  Nígbà yìí ni ọba Sódómù lọ, àti ọba Gòmórà pẹ̀lú, àti ọba Ádímà àti ọba Sébóíímù àti ọba Bélà (èyíinì ni, Sóárì), wọ́n sì tẹ́ ìtẹ́gun ìjà ogun ní ìdojúkọ wọ́n ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Rírẹlẹ̀ ti Sídímù,+ 9  lòdì sí Kedoláómà ọba Élámù àti Tídálì ọba Góíímù àti Ámúráfélì ọba Ṣínárì àti Áríókù ọba Élásárì;+ àwọn ọba mẹ́rin ní ìdojú-ìjà-kọ àwọn márààrùn-ún. 10  Wàyí o, Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Rírẹlẹ̀ ti Sídímù+ kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ kòtò ọ̀dà bítúmẹ́nì dídì;+ àwọn ọba Sódómù àti Gòmórà+ sì fẹsẹ̀ fẹ, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣubú sínú wọn, àwọn tí ó sì ṣẹ́ kù sá lọ sí ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá.+ 11  Lẹ́yìn náà, àwọn ajagunmólú kó gbogbo àwọn ẹrù Sódómù àti Gòmórà àti gbogbo oúnjẹ wọn, wọ́n sì bá ọ̀nà wọn lọ.+ 12  Wọ́n tún kó Lọ́ọ̀tì ọmọkùnrin arákùnrin Ábúrámù àti àwọn ẹrù rẹ̀, wọ́n sì ń bá ọ̀nà wọn lọ. Ó ń gbé ní Sódómù nígbà yẹn.+ 13  Lẹ́yìn ìyẹn, ọkùnrin kan tí ó ti sá àsálà wá, ó sì sọ fún Ábúrámù tí í ṣe Hébérù.+ Nígbà yẹn, ó pàgọ́ sáàárín àwọn igi ńlá Mámúrè tí í ṣe Ámórì,+ arákùnrin Éṣíkólì àti arákùnrin Ánérì;+ wọ́n sì jẹ́ alájùmọ̀ṣepọ̀ pẹ̀lú Ábúrámù. 14  Nípa báyìí, Ábúrámù gbọ́ pé a ti mú arákùnrin òun ní òǹdè.+ Pẹ̀lú ìyẹn, ó pe àwọn ọkùnrin tí ó ti kọ́ jọ,+ ọ̀ọ́dúnrún lé méjìdínlógún ẹrú tí a bí ní agbo ilé rẹ̀,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa wọn títí dé Dánì.+ 15  Nígbà tí ó sì di òru, ó yíjú sí pípín àwọn agbo ọmọ ogun rẹ̀,+ òun àti àwọn ẹrú rẹ̀, láti gbéjà kò wọ́n, ó sì tipa báyìí ṣẹ́gun wọn, ó sì ń lépa wọn nìṣó títí dé Hóbà, tí ó jẹ́ àríwá Damásíkù. 16  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gba gbogbo àwọn ẹrù náà padà,+ ó sì tún gba Lọ́ọ̀tì arákùnrin rẹ̀ àti àwọn ẹrù àti àwọn obìnrin àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú padà.+ 17  Nígbà náà ni ọba Sódómù jáde lọ pàdé rẹ̀ lẹ́yìn tí ó padà dé lẹ́nu ṣíṣẹ́gun Kedoláómà àti àwọn ọba tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, sí Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Rírẹlẹ̀ ti Ṣáfè, èyíinì ni, Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Rírẹlẹ̀ ti ọba.+ 18  Melikisédékì+ ọba Sálẹ́mù+ sì gbé oúnjẹ àti wáìnì jáde,+ òun sì ni àlùfáà Ọlọ́run Gíga Jù Lọ.+ 19  Nígbà náà, ó súre fún un, ó sì wí pé: “Ìbùkún ni fún Ábúrámù láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Gíga Jù Lọ wá,+ Ẹni tí Ó Ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé;+ 20  Ìbùkún sì ni fún Ọlọ́run Gíga Jù Lọ,+ Ẹni tí ó ti fi àwọn tí ń ni ọ́ lára lé ọ lọ́wọ́!”+ Látàrí èyí, Ábúrámù fi ìdá mẹ́wàá ohun gbogbo fún un.+ 21  Lẹ́yìn ìyẹn, ọba Sódómù sọ fún Ábúrámù pé: “Fún mi ní àwọn ọkàn,+ ṣùgbọ́n mú àwọn ẹrù fún ara rẹ.” 22  Látàrí èyí, Ábúrámù wí fún ọba Sódómù pé: “Mo gbé ọwọ́ mi sókè ní ti gidi ní ìbúra+ sí Jèhófà Ọlọ́run Gíga Jù Lọ, Ẹni tí Ó Ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, 23  pé, láti orí fọ́nrán òwú dórí okùn sálúbàtà, rárá, èmi kì yóò mú nǹkan kan nínú ohunkóhun tí ó jẹ́ tìrẹ,+ kí o má bàa sọ pé, ‘Èmi ni ó sọ Ábúrámù di ọlọ́rọ̀.’ 24  Èmi kò ní mú nǹkan kan!+ Àyàfi ohun tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin ti jẹ, àti ìpín àwọn ọkùnrin tí wọ́n bá mi lọ, Ánérì, Éṣíkólì àti Mámúrè+—jẹ́ kí wọ́n mú ìpín wọn.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé