Jẹ́nẹ́sísì 13:1-18
13 Lẹ́yìn ìyẹn, Ábúrámù gòkè lọ kúrò ní Íjíbítì, òun àti aya rẹ̀ àti gbogbo ohun tí ó ní, àti Lọ́ọ̀tì pẹ̀lú rẹ̀, sí Négébù.+
2 Ábúrámù sì ní ọ̀pọ̀ wọ̀ǹtìwọnti ọ̀wọ́ ẹran àti fàdákà àti wúrà.+
3 Ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n lọ láti ibùdó sí ibùdó jáde kúrò ní Négébù àti sí Bẹ́tẹ́lì, sí ibi tí àgọ́ rẹ̀ ti wà ní àkọ́kọ́, láàárín Bẹ́tẹ́lì àti Áì,+
4 sí ibi pẹpẹ tí ó ti ṣe síbẹ̀ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀;+ Ábúrámù sì bẹ̀rẹ̀ sí pe orúkọ Jèhófà níbẹ̀.+
5 Wàyí o, Lọ́ọ̀tì pẹ̀lú, ẹni tí ń bá Ábúrámù lọ, ní àwọn àgùntàn àti màlúù àti àwọn àgọ́.
6 Nítorí èyí, ilẹ̀ náà kò gba gbogbo wọn láti máa gbé pa pọ̀, nítorí pé ẹrù wọn ti di púpọ̀, gbogbo wọn kò sì lè máa gbé pa pọ̀.+
7 Aáwọ̀ sì dìde láàárín àwọn olùda ohun ọ̀sìn Ábúrámù àti àwọn olùda ohun ọ̀sìn Lọ́ọ̀tì; ní àkókò yẹn, àwọn ọmọ Kénáánì àti àwọn Pérísì sì ń gbé ní ilẹ̀ náà.+
8 Fún ìdí yìí, Ábúrámù sọ fún Lọ́ọ̀tì+ pé: “Jọ̀wọ́, má ṣe jẹ́ kí aáwọ̀ máa bá a lọ láàárín èmi àti ìwọ àti láàárín àwọn olùṣọ́ agbo ẹran mi àti àwọn olùṣọ́ agbo ẹran rẹ, nítorí arákùnrin ni wá.+
9 Gbogbo ilẹ̀ kò ha wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ? Jọ̀wọ́, yà sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi. Bí ìwọ bá lọ sí apá òsì, nígbà náà, èmi yóò lọ sí apá ọ̀tún; ṣùgbọ́n bí ìwọ bá lọ sí apá ọ̀tún, nígbà náà, èmi yóò lọ sí apá òsì.”+
10 Nítorí náà, Lọ́ọ̀tì gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì rí gbogbo Àgbègbè Jọ́dánì,+ pé gbogbo rẹ̀ jẹ́ ẹkùn ilẹ̀ olómi púpọ̀ kí Jèhófà tó run Sódómù àti Gòmórà, bí ọgbà Jèhófà,+ bí ilẹ̀ Íjíbítì títí dé Sóárì.+
11 Nígbà náà, Lọ́ọ̀tì yan gbogbo Àgbègbè Jọ́dánì fún ara rẹ̀, Lọ́ọ̀tì sì ṣí ibùdó rẹ̀ lọ sí ìlà-oòrùn. Nítorí náà, wọ́n yà sọ́tọ̀, ẹnì kìíní kúrò lọ́dọ̀ ẹnì kejì.
12 Ábúrámù ń gbé ní ilẹ̀ Kénáánì, ṣùgbọ́n Lọ́ọ̀tì ń gbé láàárín àwọn ìlú ńlá Àgbègbè náà.+ Níkẹyìn, ó pàgọ́ sí tòsí Sódómù.
13 Àwọn ọkùnrin Sódómù sì burú, wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ paraku sí Jèhófà.+
14 Jèhófà sì wí fún Ábúrámù lẹ́yìn tí Lọ́ọ̀tì ti yà sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ pé: “Gbé ojú rẹ sókè, jọ̀wọ́, kí o sì wo ìhà àríwá àti ìhà gúúsù àti ìhà ìlà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrùn,+ láti ibi tí o wà,
15 nítorí pé gbogbo ilẹ̀ náà tí ìwọ ń wò, ìwọ àti irú-ọmọ rẹ ni èmi yóò fi fún títí di àkókò tí ó lọ kánrin.+
16 Èmi yóò sì sọ irú-ọmọ rẹ dà bí egunrín ekuru ilẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé, bí ènìyàn kan bá lè ka egunrín ekuru ilẹ̀, nígbà náà, irú-ọmọ rẹ ni a ó lè kà.+
17 Dìde, lọ káàkiri la ilẹ̀ náà já ní gígùn rẹ̀ àti ní ìbú rẹ̀, nítorí pé ìwọ ni èmi yóò fi í fún.”+
18 Nítorí náà, Ábúrámù ń bá a lọ láti gbé nínú àwọn àgọ́. Lẹ́yìn náà, ó wá, ó sì ń gbé láàárín àwọn igi ńlá Mámúrè,+ èyí tí ó wà ní Hébúrónì;+ ibẹ̀ ni ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí mọ pẹpẹ kan fún Jèhófà.+

