Jákọ́bù 1:1-27

1  Jákọ́bù,+ ẹrú+ Ọlọ́run àti ti Jésù Kristi Olúwa, sí ẹ̀yà méjìlá+ tí ó tú ká káàkiri:+ Mo kí yín!  Ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ìdùnnú, ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ bá ń bá onírúurú àdánwò pàdé,+  gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀ ní tòótọ́ pé ìjójúlówó ìgbàgbọ́ yín yìí tí a ti dán wò ń ṣiṣẹ́ yọrí sí ìfaradà.+  Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí ìfaradà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pé pérépéré, kí ẹ lè pé pérépéré,+ kí ẹ sì yè kooro ní gbogbo ọ̀nà, láìṣe aláìní ohunkóhun.+  Nítorí náà, bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣaláìní ọgbọ́n,+ kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run,+ nítorí òun a máa fi fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́ àti láìsí gíganni;+ a ó sì fi í fún un.+  Ṣùgbọ́n kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè+ nínú ìgbàgbọ́, láìṣiyèméjì rárá,+ nítorí ẹni tí ó bá ń ṣiyèméjì dà bí ìgbì òkun tí ẹ̀fúùfù ń bì,+ tí a sì ń fẹ́ káàkiri.  Ní ti tòótọ́, kí ẹni yẹn má rò pé òun yóò rí ohunkóhun gbà lọ́dọ̀ Jèhófà;+  ó jẹ́ aláìnípinnu,+ aláìdúrósójúkan+ ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀.  Ṣùgbọ́n kí arákùnrin rírẹlẹ̀ máa yọ ayọ̀ ńláǹlà lórí ìgbéga rẹ̀,+ 10  àti èyí ọlọ́rọ̀+ lórí ìtẹ́lógo rẹ̀, nítorí bí òdòdó ewéko ni yóò ṣe kọjá lọ.+ 11  Nítorí oòrùn a máa là pẹ̀lú ooru rẹ̀ jíjóni, a sì máa mú kí ewéko rọ, òdòdó rẹ̀ a sì wọ̀ dànù, ẹwà ìrísí òde rẹ̀ a sì ṣègbé. Bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú, ni ọlọ́rọ̀ yóò ṣe rẹ̀ dànù nínú àwọn ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀.+ 12  Aláyọ̀ ni ẹni tí ń bá a nìṣó ní fífarada àdánwò,+ nítorí nígbà tí ó bá di ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, yóò gba adé ìyè,+ èyí tí [Jèhófà] ṣèlérí fún àwọn tí ń bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.+ 13  Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá wà lábẹ́ àdánwò,+ kí ó má ṣe sọ pé: “Ọlọ́run ni ó ń dán mi wò.” Nítorí a kò lè fi àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi dán Ọlọ́run wò, bẹ́ẹ̀ ni òun fúnra rẹ̀ kì í dán ẹnikẹ́ni wò. 14  Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn òun fúnra rẹ̀.+ 15  Lẹ́yìn náà, ìfẹ́-ọkàn náà, nígbà tí ó bá lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀;+ ẹ̀wẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀, nígbà tí a bá ti ṣàṣeparí rẹ̀, a mú ikú wá.+ 16  Kí a má ṣì yín lọ́nà,+ ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n. 17  Gbogbo ẹ̀bùn rere+ àti gbogbo ọrẹ pípé jẹ́ láti òkè,+ nítorí a máa sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá,+ kò sì sí àyídà ìyípo òjìji lọ́dọ̀ rẹ̀.+ 18  Nítorí tí ó fẹ́ ẹ bẹ́ẹ̀,+ ó mú wa wá nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ òtítọ́,+ fún wa láti jẹ́ àkọ́so+ kan nínú àwọn ẹ̀dá rẹ̀. 19  Kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n. Kí olúkúlùkù ènìyàn yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ,+ lọ́ra nípa ìrunú;+ 20  nítorí ìrunú ènìyàn kì í ṣiṣẹ́ yọrí sí òdodo Ọlọ́run.+ 21  Nítorí bẹ́ẹ̀, ẹ mú gbogbo èérí kúrò àti ohun àṣerégèé yẹn, ìwà búburú,+ kí ẹ sì fi ìwà tútù tẹ́wọ́ gba gbígbin ọ̀rọ̀ náà sínú,+ èyí tí ó lè gba ọkàn yín là.+ 22  Bí ó ti wù kí ó rí, ẹ di olùṣe ọ̀rọ̀ náà,+ kì í sì í ṣe olùgbọ́ nìkan, ní fífi èrò èké tan ara yín jẹ.+ 23  Nítorí bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí kò sì jẹ́ olùṣe,+ ẹni yìí dà bí ènìyàn tí ń wo ojú àdánidá rẹ̀ nínú dígí. 24  Nítorí ó wo ara rẹ̀, ó sì lọ, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó gbàgbé irú ènìyàn tí òun jẹ́. 25  Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé+ tí í ṣe ti òmìnira ní àwòfín, tí ó sì tẹpẹlẹ mọ́ ọn, ẹni yìí, nítorí tí kò di olùgbọ́ tí ń gbàgbé, bí kò ṣe olùṣe iṣẹ́ náà,+ yóò láyọ̀+ nínú ṣíṣe é. 26  Bí ọkùnrin èyíkéyìí lójú ara rẹ̀ bá dà bí olùjọsìn ní irú ọ̀nà kan,+ síbẹ̀ tí kò kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu,+ ṣùgbọ́n tí ó ń bá a lọ ní títan ọkàn-àyà ara rẹ̀ jẹ,+ ọ̀nà ìjọsìn ọkùnrin yìí jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.+ 27  Ọ̀nà ìjọsìn tí ó mọ́,+ tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin+ ní ojú ìwòye Ọlọ́run àti Baba wa ni èyí: láti máa bójú tó àwọn ọmọ òrukàn+ àti àwọn opó+ nínú ìpọ́njú wọn,+ àti láti pa ara ẹni mọ́ láìní èérí+ kúrò nínú ayé.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé