Hóséà 2:1-23

2  “Ẹ wí fún àwọn arákùnrin yín pé, ‘Ẹ̀yin ènìyàn mi!’+ àti fún àwọn arábìnrin yín pé, ‘Ìwọ obìnrin tí a fi àánú+ hàn sí!’  Ẹ bá ìyá+ yín ṣe ẹjọ́; ẹ ṣe ẹjọ́, nítorí òun kì í ṣe aya+ mi, èmi kì í sì í ṣe ọkọ+ rẹ̀. Kí ó sì mú àgbèrè rẹ̀ kúrò níwájú ara rẹ̀ àti ìwà panṣágà rẹ̀ kúrò láàárín ọmú+ rẹ̀,  kí èmi má bàa tú u sí ìhòòhò+ kí n sì ṣe é ní bí ó ṣe rí ní ọjọ́ tí a bí+ i ní ti tòótọ́, kí n sì gbé e kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aginjù+ ní ti tòótọ́, kí n sì ṣe é bí ilẹ̀ aláìlómi,+ kí n sì fi òùngbẹ+ ṣekú pa á.  Èmi kì yóò sì fi àánú+ hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀, nítorí ọmọ àgbèrè+ ni wọ́n.  Nítorí ìyá wọn ti ṣe àgbèrè.+ Ẹni tí ó lóyún wọn ti hùwà lọ́nà tí ń tini lójú,+ nítorí tí ó sọ pé, ‘Mo fẹ́ tọ àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ mi+ lọ́nà ìgbónára lẹ́yìn, àwọn tí ń pèsè oúnjẹ mi àti omi mi, irun àgùntàn mi àti aṣọ ọ̀gbọ̀ mi, òróró mi àti ohun mímu mi.’+  “Nítorí náà, kíyè sí i èmi yóò fi ẹ̀gún ṣe ọgbà ààbò yí ọ̀nà rẹ ká; dájúdájú, èmi yóò sì gbé ògiri òkúta nà ró lòdì sí i,+ tó bẹ́ẹ̀ tí òun kì yóò fi rí+ òpópónà ara rẹ̀.  Òun yóò sì lépa àwọn olùfẹ́ rẹ̀ onígbòónára ní ti tòótọ́, ṣùgbọ́n kì yóò bá wọn;+ òun yóò sì wá wọn dájúdájú, ṣùgbọ́n kì yóò rí wọn. Yóò sì wá sọ pé, ‘Mo fẹ́ padà lọ sọ́dọ̀ ọkọ mi,+ ti àkọ́kọ́,+ nítorí ó sàn fún mi ní àkókò yẹn ju ìsinsìnyí lọ.’+  Ṣùgbọ́n òun alára kò mọ̀+ pé èmi ni ó fún òun ní ọkà+ àti wáìnì dídùn àti òróró, àti pé èmi ni ó ti mú kí fàdákà pọ̀ gidigidi fún un, àti wúrà, èyí tí wọ́n lò fún Báálì.+  “‘Nítorí náà, èmi yóò yí padà, èmi yóò sì kó ọkà mi lọ dájúdájú ní àkókò rẹ̀ àti wáìnì dídùn mi ní àsìkò rẹ̀,+ èmi yóò sì já irun àgùntàn mi gbà àti aṣọ ọ̀gbọ̀ mi tí ó fi ń bo ìhòòhò rẹ̀.+ 10  Wàyí o, èmi yóò ṣí abẹ́ rẹ̀ síta sí ojú àwọn olùfẹ́ rẹ̀ onígbòónára,+ kì yóò sì sí ọkùnrin kankan tí yóò já a gbà kúrò ní ọwọ́ mi.+ 11  Dájúdájú, èmi yóò sì mú kí gbogbo ayọ̀ ńláǹlà rẹ̀,+ àjọyọ̀ rẹ̀,+ òṣùpá+ tuntun rẹ̀ àti sábáàtì rẹ̀ àti gbogbo àkókò àjọyọ̀ rẹ̀ kásẹ̀ nílẹ̀. 12  Dájúdájú, èmi yóò sì sọ àjàrà+ rẹ̀ àti igi ọ̀pọ̀tọ́+ rẹ̀ di ahoro, nípa èyí tí ó sọ pé: “Ẹ̀bùn ni wọ́n jẹ́ fún mi, èyí tí àwọn olùfẹ́ mi onígbòónára fi fún mi”; èmi yóò sì ṣe wọ́n bí igbó,+ ẹranko inú pápá yóò sì jẹ wọ́n run dájúdájú. 13  Èmi yóò sì béèrè ìjíhìn+ lọ́wọ́ rẹ̀ nítorí àwọn ọjọ́ ère+ Báálì èyí tí ó ń bá a nìṣó ní rírú èéfín+ ẹbọ sí, nígbà tí ó ń bá a nìṣó ní fífi òrùka ara rẹ̀ àti ohun ọ̀ṣọ́+ ara rẹ̀ ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́, tí ó sì ń bá a nìṣó ní títọ àwọn olùfẹ́+ rẹ̀ onígbòónára lẹ́yìn, èmi sì ni ẹni tí ó gbàgbé,’+ ni àsọjáde Jèhófà. 14  “‘Nítorí náà, kíyè sí i, èmi yóò borí rẹ̀, dájúdájú, èmi yóò sì mú kí ó lọ sí aginjù,+ èmi yóò sì bá ọkàn-àyà+ rẹ̀ sọ̀rọ̀. 15  Dájúdájú, èmi yóò sì fún un ní àwọn ọgbà àjàrà rẹ̀ láti ìgbà náà lọ,+ àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Ákórì+ gẹ́gẹ́ bí ẹnu ọ̀nà sí ìrètí; dájúdájú, òun yóò sì dáhùn níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ti àwọn ọjọ́ ìgbà èwe+ rẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí ti àwọn ọjọ́ tí ó gòkè wá láti ilẹ̀ Íjíbítì.+ 16  Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘pé ìwọ yóò pè mí ní ọkọ Mi, ìwọ kì yóò sì tún pè mí ní olúwa+ Mi mọ́.’ 17  “‘Dájúdájú, èmi yóò sì mú àwọn orúkọ ère Báálì kúrò ní ẹnu rẹ̀,+ a kì yóò sì tún fi orúkọ+ wọn rántí wọn mọ́. 18  Dájúdájú, èmi yóò sì dá májẹ̀mú fún wọn ní ọjọ́ yẹn ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹranko inú pápá+ àti pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti ohun tí ń rákò lórí ilẹ̀, ọrun àti idà àti ogun ni èmi yóò sì ṣẹ́ kúrò ní ilẹ̀ náà,+ èmi yóò sì mú kí wọ́n dùbúlẹ̀ ní ààbò.+ 19  Èmi yóò sì fẹ́ ọ fún ara mi fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ èmi yóò sì fẹ́ ọ fún ara mi ní òdodo àti ní ìdájọ́ òdodo àti ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti ní àánú.+ 20  Èmi yóò sì fẹ́ ọ fún ara mi ní ìṣòtítọ́; dájúdájú, ìwọ yóò sì mọ Jèhófà.’+ 21  “‘Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé èmi yóò dáhùn,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘èmi yóò dá ọ̀run lóhùn, àwọn, ní tiwọn, yóò sì dá ilẹ̀ ayé+ lóhùn; 22  ilẹ̀ ayé, ní tirẹ̀, yóò sì dá ọkà+ àti wáìnì dídùn àti òróró lóhùn; àti àwọn, ní tiwọn, yóò dá Jésíréélì [‘Ọlọ́run yóò fúnrúgbìn’]+ lóhùn. 23  Dájúdájú, èmi yóò sì fọ́n ọn bí irúgbìn fún ara mi ní ilẹ̀ ayé,+ èmi yóò sì fi àánú hàn sí ẹni tí a kò fi àánú+ hàn sí, èmi yóò sì wí fún àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi pé: “Ẹ̀yin ni ènìyàn mi”;+ àwọn, ní tiwọn, yóò sì sọ pé: “Ìwọ ni Ọlọ́run mi.”’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé