Hóséà 14:1-9

14  “Padà wá, ìwọ Ísírẹ́lì, sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ nítorí ìwọ ti kọsẹ̀ nínú ìṣìnà rẹ.+  Ẹ mú àwọn ọ̀rọ̀ dáni pẹ̀lú yín, kí ẹ sì padà sọ́dọ̀ Jèhófà.+ Gbogbo yín, ẹ sọ fún un pé, ‘Kí o dárí ìṣìnà jì;+ kí o sì tẹ́wọ́ gba ohun rere, àwa yóò sì fi ẹgbọrọ akọ màlúù ètè wa rúbọ ní ìdápadà.+  Ásíríà alára kì yóò gbà wá là.+ Àwa kì yóò gun ẹṣin.+ A kì yóò sì tún wí fún iṣẹ́ ọwọ́ wa pé: “Ìwọ Ọlọ́run wa!” nítorí pé nípasẹ̀ rẹ ni a ń fi àánú hàn sí ọmọdékùnrin aláìníbaba.’+  “Èmi yóò wo àìṣòótọ́ wọn sàn.+ Èmi yóò nífẹ̀ẹ́ wọn láti inú ìfẹ́ àtinúwá tèmi,+ nítorí pé ìbínú mi ti yí padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.+  Èmi yóò dà bí ìrì sí Ísírẹ́lì.+ Òun yóò yọ ìtànná bí òdòdó lílì, yóò sì ta gbòǹgbò rẹ̀ bí Lẹ́bánónì.  Àwọn ẹ̀ka igi rẹ̀ yóò yọ jáde, iyì rẹ̀ yóò sì dà bí ti igi ólífì,+ ìtasánsán rẹ̀ yóò sì dà bí ti Lẹ́bánónì.  Wọn yóò tún jẹ́ olùgbé lábẹ́ òjìji rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.+ Wọn yóò gbin ọkà, wọn yóò sì rudi bí àjàrà.+ Ìrántí rẹ̀ yóò dà bí wáìnì Lẹ́bánónì.  “Éfúráímù yóò wí pé, ‘Kí ni ó tún lè pa èmi àti àwọn òrìṣà pọ̀?’+ “Èmi fúnra mi yóò dáhùn dájúdájú, èmi yóò sì máa bá a nìṣó ní wíwò ó.+ Mo dà bí igi júnípà+ tí ó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀. Ọ̀dọ̀ mi ni a ó ti rí èso fún ọ.”  Ta ni ó gbọ́n, kí ó lè lóye nǹkan wọ̀nyí?+ Ta ni ó lóye, kí ó lè mọ̀ wọ́n?+ Nítorí àwọn ọ̀nà Jèhófà dúró ṣánṣán,+ àwọn olódodo sì ni yóò máa rìn nínú wọn;+ ṣùgbọ́n àwọn olùrélànàkọjá ni yóò kọsẹ̀ nínú wọn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé