Hébérù 4:1-16
4 Nítorí náà, níwọ̀n bí ó ti ku ìlérí kan nílẹ̀ fún wíwọnú ìsinmi rẹ̀,+ ẹ jẹ́ kí a bẹ̀rù kí ó má bàa jẹ́ pé ní àkókò kan ẹnì kan nínú yín lè dà bí ẹni tí ó ti kùnà láti dé ojú ìwọ̀n rẹ̀.+
2 Nítorí tí a ti polongo ìhìn rere fún àwa náà,+ àní gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe fún àwọn pẹ̀lú;+ ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ kò ṣe wọ́n láǹfààní,+ nítorí tí a kò fi ìgbàgbọ́+ so wọ́n pọ̀ ṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn tí ó gbọ́.+
3 Nítorí àwa tí a ti lo ìgbàgbọ́ wọnú ìsinmi náà ní tòótọ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti wí pé: “Nítorí náà, mo búra+ nínú ìbínú mi pé, ‘Dájúdájú, wọn kì yóò wọnú+ ìsinmi mi,’”+ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti parí+ àwọn iṣẹ́ rẹ̀ láti ìgbà pípilẹ̀ ayé.+
4 Nítorí ní ibì kan, ó sọ nípa ọjọ́ keje báyìí pé: “Ọlọ́run sì sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀,”+
5 àti pẹ̀lú ní ibí yìí pé: “Dájúdájú, wọn kì yóò wọnú ìsinmi mi.”+
6 Nítorí náà, níwọ̀n bí ó ti kù kí àwọn kan wọnú rẹ̀, tí àwọn tí a kọ́kọ́ polongo ìhìn rere+ fún kò sì wọnú rẹ̀ nítorí àìgbọràn,+
7 ó tún sàmì sí ọjọ́ kan pàtó nípa sísọ lẹ́yìn àkókò gígùn gan-an nínú sáàmù Dáfídì pé “Lónìí”; gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti sọ lókè yìí pé: “Lónìí, bí ẹ bá fetí sí ohùn rẹ̀,+ ẹ má ṣe sé ọkàn-àyà yín le.”+
8 Nítorí bí Jóṣúà+ bá ti mú wọn lọ sí ibi ìsinmi kan,+ Ọlọ́run lẹ́yìn náà kì bá ti sọ̀rọ̀+ ọjọ́ mìíràn.
9 Nítorí náà, ìsinmi ti sábáàtì kan ṣì kù fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run.+
10 Nítorí ẹni tí ó ti wọnú ìsinmi+ Ọlọ́run, òun pẹ̀lú ti sinmi kúrò nínú àwọn iṣẹ́ tirẹ̀,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe kúrò nínú tirẹ̀.
11 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a sa gbogbo ipá wa láti wọnú ìsinmi yẹn, kí ẹnikẹ́ni má bàa ṣubú sínú àpẹẹrẹ ọ̀nà àìgbọràn+ kan náà.
12 Nítorí tí ọ̀rọ̀+ Ọlọ́run yè,+ ó sì ń sa agbára,+ ó mú ju idà+ olójú méjì èyíkéyìí lọ, ó sì ń gúnni àní títí dé pípín ọkàn+ àti ẹ̀mí+ níyà, àti àwọn oríkèé àti mùdùnmúdùn wọn, ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.+
13 Kò sì sí ìṣẹ̀dá tí kò hàn kedere sí ojú rẹ̀,+ ṣùgbọ́n ohun gbogbo wà ní ìhòòhò àti ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu fún ojú ẹni tí a óò jíhìn fún.+
14 Nítorí náà, níwọ̀n bí a ti ní àlùfáà àgbà títóbi, ẹni tí ó ti la ọ̀run kọjá,+ Jésù Ọmọ Ọlọ́run,+ ẹ jẹ́ kí a rọ̀ mọ́ ìjẹ́wọ́ wa nípa rẹ̀.+
15 Nítorí àwa ní gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà, kì í ṣe ẹni tí kò lè báni kẹ́dùn+ fún àwọn àìlera wa, bí kò ṣe ẹni tí a ti dán wò ní gbogbo ọ̀nà bí àwa fúnra wa, ṣùgbọ́n tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀.+
16 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a sún mọ́+ ìtẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ,+ kí a lè rí àánú gbà, kí a sì rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tí ó tọ́.+

