Hébérù 2:1-18

2  Ìdí nìyẹn tí ó fi pọndandan fún wa láti fún àwọn ohun tí a gbọ́+ ní àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, kí a má bàa sú lọ láé.+ 2  Nítorí bí ọ̀rọ̀ tí a tipasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì+ sọ bá já sí èyí tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in, tí gbogbo ìrélànàkọjá àti ìwà àìgbọràn sì gba ẹ̀san iṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo;+ 3  báwo ni a ó ṣe yèbọ́+ bí a bá ti ṣàìnáání+ ìgbàlà tí ó tóbi tó bẹ́ẹ̀+ ní ti pé a bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ́ nípasẹ̀ Olúwa wa,+ tí àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì fìdí èyí múlẹ̀+ fún wa, 4  nígbà tí Ọlọ́run dara pọ̀ ní jíjẹ́rìí pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn àmì àgbàyanu àti onírúurú iṣẹ́ agbára+ àti pẹ̀lú ìpínfúnni+ ẹ̀mí mímọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀?+ 5  Nítorí kì í ṣe abẹ́ àwọn áńgẹ́lì ni ó fi ilẹ̀ ayé gbígbé tí ń bọ̀ sí,+ èyí tí a ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. 6  Ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí kan ti fúnni ní ẹ̀rí ìdánilójú ní ibì kan, pé: “Kí ni ènìyàn tí o fi ń fi í sọ́kàn,+ tàbí ọmọ ènìyàn tí o fi ń tọ́jú rẹ̀?+ 7  Ìwọ ṣe é ní ẹni rírẹlẹ̀ díẹ̀ ju àwọn áńgẹ́lì; o fi ògo àti ọlá+ dé e ládé, o sì yàn án sípò ṣe olórí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.+ 8  O fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.”+ Nítorí ní ti pé ó fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀,+ Ọlọ́run kò fi nǹkan kan sílẹ̀ tí a kò fi sábẹ́ rẹ̀.+ Nísinsìnyí, bí ó ti wù kí ó rí, a kò tíì rí ohun gbogbo ní abẹ́ rẹ̀;+ 9  ṣùgbọ́n a rí Jésù, tí a ti ṣe ní ẹni rírẹlẹ̀ díẹ̀ ju àwọn áńgẹ́lì,+ tí a fi ògo+ àti ọlá dé ládé nítorí tí ó ti jìyà ikú,+ kí ó lè tọ́ ikú wò fún olúkúlùkù ènìyàn+ nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run. 10  Nítorí ó yẹ fún ẹni tí ohun gbogbo torí rẹ̀ wà+ àti nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo fi wà, ní mímú ọ̀pọ̀ ọmọ wá sínú ògo,+ láti sọ Olórí Aṣojú+ ìgbàlà wọn di pípé nípasẹ̀ àwọn ìjìyà.+ 11  Nítorí àti ẹni tí ń sọni di mímọ́ àti àwọn tí a ń sọ di mímọ́,+ gbogbo wọn jáde wá láti ọ̀dọ̀ ẹnì kan,+ àti nítorí ìdí yìí ojú kò tì í láti pè wọ́n ní “arákùnrin,”+ 12  gẹ́gẹ́ bí ó ti wí pé: “Ṣe ni èmi yóò máa polongo orúkọ rẹ fún àwọn arákùnrin mi; ṣe ni èmi yóò máa fi orin yìn ọ́ ní àárín ìjọ.”+ 13  Àti pẹ̀lú: “Èmi yóò ní ìgbẹ́kẹ̀lé mi nínú rẹ̀.”+ Àti pẹ̀lú: “Wò ó! Èmi àti àwọn ọmọ kéékèèké, tí Jèhófà fi fún mi.”+ 14  Nítorí náà, níwọ̀n bí “àwọn ọmọ kéékèèké” ti jẹ́ alájọpín ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara, òun pẹ̀lú lọ́nà kan náà ṣalábàápín àwọn ohun kan náà,+ pé nípasẹ̀ ikú+ rẹ̀ kí ó lè sọ ẹni tí ó ní ọ̀nà àtimú ikú+ wá di asán,+ èyíinì ni, Èṣù;+ 15  àti pé kí ó lè dá gbogbo àwọn tí a ti fi sábẹ́ ìsìnrú ní gbogbo ìgbésí ayé wọn+ nítorí ìbẹ̀rù ikú+ nídè kúrò lóko ẹrú.+ 16  Nítorí ní ti gidi, kì í ṣe àwọn áńgẹ́lì ni ó ń ṣèrànwọ́ fún rárá, ṣùgbọ́n ó ń ṣèrànwọ́ fún irú-ọmọ Ábúráhámù.+ 17  Nítorí náà, ó di dandan fún un láti dà bí “àwọn arákùnrin” rẹ̀ lọ́nà gbogbo,+ kí ó lè di àlùfáà àgbà tí ó jẹ́ aláàánú àti olùṣòtítọ́ nínú àwọn ohun tí ó jẹmọ́ ti Ọlọ́run,+ kí ó bàa lè rú ẹbọ ìpẹ̀tù+ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn.+ 18  Nítorí níwọ̀n bí òun fúnra rẹ̀ ti jìyà nígbà tí a ń dán an wò,+ ó lè wá ṣe àrànṣe fún àwọn tí a ń dán wò.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé