Hébérù 12:1-29

12  Nípa báyìí, nítorí tí a ní àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí+ tí ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ yí wa ká, ẹ jẹ́ kí àwa pẹ̀lú mú gbogbo ẹrù wíwúwo+ kúrò àti ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa+ pẹ̀lú ìrọ̀rùn, ẹ sì jẹ́ kí a fi ìfaradà+ sá eré ìje+ tí a gbé ka iwájú wa,+  bí a ti tẹjú mọ́ Olórí Aṣojú+ àti Aláṣepé ìgbàgbọ́+ wa, Jésù. Nítorí ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀, ó fara da+ òpó igi oró, ó tẹ́ńbẹ́lú ìtìjú, ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.+  Ní tòótọ́, ẹ ronú jinlẹ̀-jinlẹ̀ nípa ẹni tí ó ti fara da irúfẹ́ òdì ọ̀rọ̀+ bẹ́ẹ̀ láti ẹnu àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lòdì sí ire ara wọn, kí ó má bàa rẹ̀ yín, kí ẹ sì rẹ̀wẹ̀sì nínú ọkàn yín.+  Ní bíbá ìjàkadì yín nìṣó lòdì sí ẹ̀ṣẹ̀ yẹn, ẹ kò tíì dúró tiiri títí dé orí ẹ̀jẹ̀,+  ṣùgbọ́n ẹ ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú náà pátápátá èyí tí ń bá yín sọ̀rọ̀ bí ọmọ+ pé: “Ọmọ mi, má fi ojú kékeré wo ìbáwí láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni kí o má rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí ó bá tọ́ ọ sọ́nà;+  nítorí ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó máa ń bá wí; ní ti tòótọ́, ó máa ń na olúkúlùkù ẹni tí ó gbà gẹ́gẹ́ bí ọmọ lọ́rẹ́.”+  Ó jẹ́ nítorí ìbáwí+ ni ẹ̀yin ṣe ní ìfaradà. Ọlọ́run ń bá yín lò bí ẹní ń bá àwọn ọmọ+ lò. Nítorí ọmọ wo ni baba kì í bá wí?+  Ṣùgbọ́n bí ẹ bá wà láìsí ìbáwí tí gbogbo ènìyàn ti di alábàápín nínú rẹ̀, ọmọ àlè+ ni yín ní ti gidi, ẹ kì í sì í ṣe ọmọ.  Síwájú sí i, a ti máa ń ní àwọn baba tí wọ́n jẹ́ ti ara wa láti bá wa wí,+ a sì ti máa ń fi ọ̀wọ̀ fún wọn. Lọ́nà púpọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ, kò ha yẹ kí a fi ara wa sábẹ́ Baba ìyè wa nípa ti ẹ̀mí kí a sì yè?+ 10  Nítorí fún ọjọ́ díẹ̀, àwọn a máa bá wa wí ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ó dára lójú wọn,+ ṣùgbọ́n òun a máa ṣe bẹ́ẹ̀ fún èrè wa kí a lè ṣalábàápín nínú ìjẹ́mímọ́ rẹ̀.+ 11  Lóòótọ́, kò sí ìbáwí tí ó dà bí ohun ìdùnnú nísinsìnyí, bí kò ṣe akó-ẹ̀dùn-ọkàn-báni;+ síbẹ̀ nígbà tí ó bá yá, fún àwọn tí a ti kọ́ nípasẹ̀ rẹ̀, a máa so èso ẹlẹ́mìí àlàáfíà,+ èyíinì ni, òdodo.+ 12  Nítorí bẹ́ẹ̀, ẹ mú àwọn ọwọ́ rírọ̀ jọwọrọ+ àti àwọn eékún tí ó ti di ahẹrẹpẹ+ nà ró ṣánṣán, 13  kí ẹ sì máa bá a lọ ní ṣíṣe ipa ọ̀nà títọ́ fún ẹsẹ̀ yín,+ kí ohun tí ó rọ má bàa yẹ̀ kúrò ní oríkèé, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, kí a lè mú un lára dá.+ 14  Ẹ máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn,+ àti ìsọdimímọ́+ èyí tí ó jẹ́ pé láìsí i, kò sí ènìyàn kankan tí yóò rí Olúwa,+ 15  ní ṣíṣọ́ra gidigidi kí ó má bàa sí ẹnì kankan tí a fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run+ dù; kí gbòǹgbò+ onímájèlé kankan má bàa rú yọ, kí ó sì dá ìjàngbọ̀n sílẹ̀ àti kí a má bàa sọ ọ̀pọ̀ di ẹlẹ́gbin nípasẹ̀ rẹ̀;+ 16  kí ó má bàa sí àgbèrè kankan tàbí ẹnikẹ́ni tí kò mọrírì àwọn ohun ọlọ́wọ̀, bí Ísọ̀,+ ẹni tí ó fi àwọn ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí+ tọrẹ ní pàṣípààrọ̀ fún oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo. 17  Nítorí ẹ̀yin mọ̀ pé lẹ́yìn náà pẹ̀lú, nígbà tí ó fẹ́ láti jogún ìbùkún náà,+ a kọ̀ ọ́ tì,+ nítorí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fi taratara wá ìyípadà èrò inú pẹ̀lú omijé,+ kò rí àyè fún un.+ 18  Nítorí ẹ kò sún mọ́ èyíinì tí a lè fọwọ́ bà+ àti èyí tí a ti fi iná mú jó lala,+ àti àwọsánmà ṣíṣú àti òkùnkùn nínípọn àti ìjì líle,+ 19  àti ìró kíkankíkan kàkàkí+ àti ohùn àwọn ọ̀rọ̀;+ ohùn tí ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ àwọn ènìyàn náà fi taratara bẹ̀bẹ̀ pé kí a má fi ọ̀rọ̀ kankan kún un fún wọn.+ 20  Nítorí tí àṣẹ náà kò ṣeé mú mọ́ra fún wọn pé: “Bí ẹranko kan bá sì fara kan òkè ńlá náà, a gbọ́dọ̀ sọ ọ́ lókùúta.”+ 21  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ìfihàn náà bani lẹ́rù tó bẹ́ẹ̀ tí Mósè fi wí pé: “Ẹ̀rù ń bà mí, mo sì ń wárìrì.”+ 22  Ṣùgbọ́n ẹ ti sún mọ́ Òkè Ńlá Síónì+ kan àti ìlú ńlá+ Ọlọ́run alààyè, Jerúsálẹ́mù ti ọ̀run,+ àti ọ̀pọ̀ ẹgbẹẹgbàárùn-ún áńgẹ́lì,+ 23  ní àpéjọ gbogbogbòò,+ àti ìjọ àwọn àkọ́bí+ tí a ti kọrúkọ wọn sílẹ̀+ ní ọ̀run, àti Ọlọ́run Onídàájọ́ gbogbo ènìyàn,+ àti ìyè nípa ti ẹ̀mí+ fún àwọn olódodo tí a ti sọ di pípé,+ 24  àti Jésù alárinà+ májẹ̀mú tuntun,+ àti ẹ̀jẹ̀ ìbùwọ́n,+ èyí tí ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ó dára ju ẹ̀jẹ̀ Ébẹ́lì lọ.+ 25  Ẹ rí i pé ẹ kò tọrọ gáfárà kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ń sọ̀rọ̀.+ Nítorí bí àwọn tí wọ́n tọrọ gáfárà kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ń fúnni ní ìkìlọ̀ àtọ̀runwá lórí ilẹ̀ ayé+ kò bá yè bọ́, mélòómélòó ni àwa kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ bí a bá yí padà kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ń sọ̀rọ̀ láti ọ̀run.+ 26  Ní àkókò yẹn, ohùn rẹ̀ mi ilẹ̀ ayé,+ ṣùgbọ́n nísinsìnyí ó ti ṣèlérí pé: “Síbẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i dájúdájú kì í ṣe ilẹ̀ ayé nìkan ni èmi yóò fi sínú arukutu ṣùgbọ́n ọ̀run pẹ̀lú.”+ 27  Wàyí o, gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà “Síbẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i” tọ́ka sí ìmúkúrò àwọn ohun tí a ń mì gẹ́gẹ́ bí àwọn ohun tí a ti ṣe,+ kí àwọn ohun tí a kò mì lè dúró.+ 28  Nítorí náà, níwọ̀n bí a ó ti gba ìjọba kan tí kò ṣeé mì,+ ẹ jẹ́ kí a máa bá a lọ láti ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, nípasẹ̀ èyí tí a fi lè ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run lọ́nà tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọ́run àti ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀.+ 29  Nítorí Ọlọ́run wa jẹ́ iná tí ń jóni run+ pẹ̀lú.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé