Hábákúkù 1:1-17

1  Ọ̀rọ̀ ìkéde tí Hábákúkù wòlíì rí ní ìran:  Yóò ti pẹ́ tó, Jèhófà, tí èmi yóò fi kígbe fún ìrànlọ́wọ́, tí ìwọ kò sì gbọ́?+ Yóò ti pẹ́ tó tí èmi yóò fi ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́ kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá, tí ìwọ kò sì gbà là?+  Èé ṣe tí ìwọ fi mú kí n rí ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, tí ìwọ sì ń wo èkìdá ìdààmú? Èé sì ti ṣe tí ìfiṣèjẹ àti ìwà ipá fi wà ní iwájú mi, èé sì ti ṣe tí aáwọ̀ fi ń ṣẹlẹ̀, èé sì ti ṣe tí gbọ́nmi-si omi-ò-to fi ń bẹ?+  Nítorí náà, òfin kú tipiri, ìdájọ́ òdodo kò sì jáde lọ rárá.+ Nítorí pé ẹni burúkú yí olódodo ká, nítorí ìdí yẹn ni ìdájọ́ òdodo fi jáde lọ ní wíwọ́.+  “Ẹ wo inú àwọn orílẹ̀-èdè, kí ẹ sì máa wò, kí ẹ sì wo ara yín sùn-ùn lẹ́nì kìíní-kejì pẹ̀lú kàyéfì.+ Ẹ ṣe kàyéfì; nítorí ìgbòkègbodò kan wà tí ẹnì kan ń ṣe ní àwọn ọjọ́ yín, èyí tí ẹ kì yóò gbà gbọ́ bí a tilẹ̀ ṣèròyìn rẹ̀.+  Nítorí kíyè sí i, èmi yóò gbé àwọn ará Kálídíà+ dìde, orílẹ̀-èdè tí ó korò, tí ó sì ní inú fùfù, èyí tí ń lọ sí àwọn ibi fífẹ̀ gbayawu ilẹ̀ ayé kí ó bàa lè gba àwọn ibùgbé tí kì í ṣe tirẹ̀.+  Ó jẹ́ adajìnnìjìnnì-boni àti amúnikún-fún-ẹ̀rù. Láti ọ̀dọ̀ òun fúnra rẹ̀ ni ìdájọ́ òdodo tirẹ̀ àti iyì tirẹ̀ ti ń jáde lọ.+  Àwọn ẹṣin rẹ̀ sì jẹ́ èyí tí ó yára ju àmọ̀tẹ́kùn, wọ́n sì jẹ́ òǹrorò ju ìkookò+ ìrọ̀lẹ́. Àwọn ẹṣin ogun rẹ̀ sì ti fi àtẹ́sẹ̀ talẹ̀, ibi jíjìnnàréré sì ni àwọn ẹṣin ogun rẹ̀ ti wá. Wọ́n ń fò bí idì tí ń yára kánkán lọ jẹ nǹkan.+  Látòkè délẹ̀, kìkì ìwà ipá+ ni ó wá fún. Ìpéjọ ojú wọ́n dà bí ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn,+ ó sì ń kó àwọn òǹdè jọpọ̀ bí iyanrìn. 10  Ní tirẹ̀, ó ń fi àwọn ọba pàápàá ṣe yẹ̀yẹ́,+ àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga sì jẹ́ ohun apanilẹ́rìn-ín fún un. Ní tirẹ̀, ó ń fi gbogbo ibi olódi+ pàápàá rẹ́rìn-ín, ó sì ń kó ekuru jọ pelemọ, ó sì ń gbà á. 11  Ní àkókò yẹn, dájúdájú, òun yóò lọ síwájú bí ẹ̀fúùfù, yóò sì kọjá lọ, yóò sì jẹ̀bi+ ní ti tòótọ́. Agbára rẹ̀ yìí wá láti ọwọ́ ọlọ́run+ rẹ̀.” 12  Kì í ha ṣe láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn ni ìwọ ti wà, Jèhófà?+ Ìwọ Ọlọ́run mi, Ẹni Mímọ́ mi, ìwọ kì í kú.+ Jèhófà, ìwọ ti gbé e kalẹ̀ fún ìdájọ́; ìwọ Àpáta+ sì ti fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ fún ìfìbáwítọ́sọ́nà.+ 13  Ojú rẹ ti mọ́ gaara jù láti rí ohun tí ó burú; ìwọ kò sì lè wo ìdààmú.+ Èé ṣe tí o fi ń wo àwọn tí ń ṣe àdàkàdekè,+ tí o fi dákẹ́ nígbà tí ẹni burúkú gbé ẹnì kan tí ó jẹ́ olódodo jù ú mì?+ 14  Èé sì ti ṣe tí ìwọ fi ṣe ará ayé bí àwọn ẹja òkun, bí àwọn ohun tí ń rákò, tí kò sí ẹni tí ń ṣàkóso lórí wọn?+ 15  Gbogbo ìwọ̀nyí ni ó ti fi ìwọ̀ ẹja+ lásán-làsàn mú gòkè wá; ó wọ́ wọn lọ nínú àwọ̀n ńlá rẹ̀, ó sì kó wọn jọ nínú àwọ̀n ìpẹja+ rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí ó fi ń yọ̀, tí ó sì kún fún ìdùnnú.+ 16  Ìdí nìyẹn tí ó fi ń rú ẹbọ sí àwọ̀n ńlá rẹ̀, tí ó sì ń rú èéfín ẹbọ sí àwọ̀n ìpẹja rẹ̀; nítorí nípasẹ̀ wọn, ìpín rẹ̀ ni a fi òróró dùn dáadáa, oúnjẹ rẹ̀ sì jẹ́ afúnni-nílera.+ 17  Ṣé ìdí nìyẹn tí yóò fi sọ àwọ̀n ńlá rẹ̀ di òfìfo, ó ha sì ní láti máa pa àwọn orílẹ̀-èdè nígbà gbogbo, nígbà tí kò fi ìyọ́nú hàn?+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé