Gálátíà 3:1-29

3  Ẹ̀yin òpònú ará Gálátíà, ta ní mú yín wá sábẹ́ agbára ibi,+ ẹ̀yin, ní ojú ẹni tí a fi àpèjúwe Jésù Kristi hàn ní gbangba pé a kàn án mọ́gi?+  Èyí nìkan ni mo fẹ́ gbọ́ láti ẹnu yín: Ẹ ha gba ẹ̀mí+ nítorí àwọn iṣẹ́ òfin+ tàbí nítorí gbígbọ́+ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́?  Ẹ ha jẹ́ òpònú tó bẹ́ẹ̀ bí? Lẹ́yìn bíbẹ̀rẹ̀ nínú ẹ̀mí,+ a ha ń ṣe yín parí nínú ara nísinsìnyí bí?+  Ẹ ha fara gba ìjìyà púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ lásán ni bí?+ Bí ó bá jẹ́ lásán ní ti gidi.  Nítorí náà, ẹni tí ń pèsè ẹ̀mí+ fún yín, tí ó sì ń mú àwọn iṣẹ́ agbára+ ṣe láàárín yín, ha ń ṣe é nítorí àwọn iṣẹ́ òfin tàbí nítorí gbígbọ́ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́?  Gan-an gẹ́gẹ́ bí Ábúráhámù ti “ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, tí a sì kà á sí òdodo fún un.”+  Dájúdájú, ẹ mọ̀ pé àwọn tí ó rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́+ ni àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Ábúráhámù.+  Wàyí o, ní rírí i ṣáájú pé Ọlọ́run yóò polongo àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè ní olódodo nítorí ìgbàgbọ́, Ìwé Mímọ́ polongo ìhìn rere ṣáájú fún Ábúráhámù, pé: “Nípasẹ̀ rẹ ni a ó bù kún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.”+  Nítorí náà, àwọn tí ń rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ ni a ń bù kún+ pa pọ̀ pẹ̀lú Ábúráhámù olùṣòtítọ́.+ 10  Nítorí gbogbo àwọn tí ó gbára lé àwọn iṣẹ́ òfin wà lábẹ́ ègún; nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé: “Ègún ni fún olúkúlùkù ẹni tí kì í bá a lọ láti dúró nínú gbogbo ohun tí a kọ sínú àkájọ ìwé Òfin láti ṣe wọ́n.”+ 11  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó hàn gbangba pé nípa òfin, kò sí ẹnì kankan tí a polongo ní olódodo+ lọ́dọ̀ Ọlọ́run, nítorí “olódodo yóò wà láàyè nítorí ìgbàgbọ́.”+ 12  Wàyí o, Òfin kò rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n “ẹni tí ó bá ń ṣe wọ́n yóò wà láàyè dájúdájú nípasẹ̀ wọn.”+ 13  Kristi nípa rírà,+ tú wa sílẹ̀+ kúrò lábẹ́ ègún Òfin nípa dídi ègún+ dípò wa, nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé: “Ẹni ègún ni olúkúlùkù ènìyàn tí a gbé kọ́ sórí òpó igi.”+ 14  Ète náà ni pé kí ìbùkún Ábúráhámù lè wá wà fún àwọn orílẹ̀-èdè nípasẹ̀ Jésù Kristi,+ kí a lè rí ẹ̀mí+ tí a ṣèlérí náà gbà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ wa.+ 15  Ẹ̀yin ará, èmi ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àpèjúwe ti ẹ̀dá ènìyàn: Májẹ̀mú tí a mú lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ ti ènìyàn, kò sí ẹnì kankan tí í pa á tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan tàbí so àwọn àfikún mọ́ ọn.+ 16  Wàyí o, àwọn ìlérí náà ni a sọ fún Ábúráhámù+ àti fún irú-ọmọ rẹ̀.+ Kò sọ pé: “Àti fún àwọn irú-ọmọ,” gẹ́gẹ́ bí nínú ọ̀ràn ti ọ̀pọ̀ irúfẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí nínú ọ̀ràn ẹnì kan:+ “Àti fún irú-ọmọ rẹ,”+ tí í ṣe Kristi.+ 17  Síwájú sí i, mo sọ èyí pé: Ní ti májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti mú lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ níṣàájú,+ Òfin tí ó wá wà ní ọgbọ̀n-lé-nírínwó ọdún+ lẹ́yìn ìgbà náà kò sọ ọ́ di aláìlẹ́sẹ̀nílẹ̀, tí ì bá fi fi òpin sí ìlérí náà.+ 18  Nítorí bí ogún náà bá jẹ́ nítorí òfin, kì í ṣe nítorí ìlérí mọ́;+ nígbà tí ó jẹ́ pé Ọlọ́run ti fi inú rere fi í fún Ábúráhámù nípasẹ̀ ìlérí.+ 19  Ti Òfin ti wá jẹ́? A fi kún un láti mú kí àwọn ìrélànàkọjá fara hàn kedere,+ títí irú-ọmọ tí a ṣe ìlérí fún yóò fi dé;+ a sì ta á látaré nípasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì+ láti ọwọ́ alárinà kan.+ 20  Wàyí o, kò sí alárinà kankan níbi tí ó ti jẹ́ pé ẹnì kan ṣoṣo ni ọ̀ràn kàn, ṣùgbọ́n ẹnì kan ṣoṣo ni Ọlọ́run.+ 21  Nítorí náà, Òfin ha lòdì sí àwọn ìlérí Ọlọ́run bí?+ Kí èyíinì má ṣẹlẹ̀ láé! Nítorí ká ní a ti fúnni ní òfin tí ó lè fúnni ní ìyè ni,+ òdodo ì bá ti jẹ́ nípasẹ̀ òfin ní ti gidi.+ 22  Ṣùgbọ́n Ìwé Mímọ́+ fi ohun gbogbo lápapọ̀ sínú ìhámọ́ ẹ̀ṣẹ̀,+ kí a lè fi ìlérí tí ń jẹyọ láti inú ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi fún àwọn tí ń lo ìgbàgbọ́.+ 23  Bí ó ti wù kí ó rí, kí ìgbàgbọ́ náà tó dé,+ a ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí wa lábẹ́ òfin,+ a ń fi wá sínú ìhámọ́ lápapọ̀, a ń wojú ìgbàgbọ́ tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ fún ṣíṣípayá.+ 24  Nítorí náà, Òfin ti di akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa tí ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi,+ kí a lè polongo wa ní olódodo+ nítorí ìgbàgbọ́. 25  Ṣùgbọ́n nísinsìnyí tí ìgbàgbọ́ ti dé,+ a kò sí lábẹ́ akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kan mọ́.+ 26  Ní ti tòótọ́, ọmọ+ Ọlọ́run ni gbogbo yín nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín nínú Kristi Jésù. 27  Nítorí gbogbo ẹ̀yin tí a ti batisí sínú Kristi+ ti gbé Kristi wọ̀.+ 28  Kò sí Júù tàbí Gíríìkì,+ kò sí ẹrú tàbí òmìnira,+ kò sí akọ tàbí abo;+ nítorí ẹnì kan ṣoṣo ni gbogbo yín ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.+ 29  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí ẹ bá jẹ́ ti Kristi, ẹ̀yin jẹ́ irú-ọmọ Ábúráhámù ní ti tòótọ́,+ ajogún ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìlérí.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé