Diutarónómì 3:1-29

3  “Lẹ̀yín náà, a yí padà, a sì gòkè lọ ní gbígba ti Báṣánì. Látàrí èyí, Ógù+ ọba Báṣánì jáde wá, òun àti gbogbo ènìyàn rẹ̀, láti pàdé wa nínú ìjà ogun ní Édíréì.+  Nítorí náà, Jèhófà sọ fún mi pé, ‘Má fòyà rẹ̀,+ nítorí, dájúdájú, èmi yóò fi òun àti gbogbo ènìyàn rẹ̀ àti ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́; ìwọ yóò sì ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe sí Síhónì+ ọba àwọn Ámórì, ẹni tí ń gbé ní Hẹ́ṣíbónì.’  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jèhófà Ọlọ́run wa fi Ógù ọba Báṣánì àti gbogbo ènìyàn rẹ̀ lé wa lọ́wọ́ pẹ̀lú, a sì ń kọlù ú, títí kò fi ní olùlàájá kankan tí ó ṣẹ́ kù.+  A sì bẹ̀rẹ̀ sí gba gbogbo ìlú ńlá rẹ̀ ní àkókò yẹn gan-an. Kò sí ìlú kankan tí a kò gbà lọ́wọ́ wọn, ọgọ́ta ìlú ńlá,+ gbogbo ẹkùn ilẹ̀ Ágóbù,+ ìjọba Ógù ní Báṣánì.+  Gbogbo ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn ìlú ńlá olódi tí ó ní ògiri gíga, àwọn ilẹ̀kùn àti ọ̀pá ìdábùú, yàtọ̀ sí àwọn ìlú púpọ̀ gan-an tí wọ́n jẹ́ ìletò.  Bí ó ti wù kí ó rí, a yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ìparun, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe sí Síhónì ọba Hẹ́ṣíbónì, ní yíya olúkúlùkù ìlú ńlá sọ́tọ̀ fún ìparun,+ àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké.+  Àti gbogbo ẹran agbéléjẹ̀ àti ohun ìfiṣèjẹ tí ó wà ní àwọn ìlú ńlá náà ní a kó gẹ́gẹ́ bí ohun tí a piyẹ́ fún ara wa.+  “A sì tẹ̀ síwájú ní àkókò yẹn gan-an láti gba ilẹ̀ lọ́wọ́ ọba méjèèjì ti àwọn Ámórì+ tí wọ́n wà ní ẹkùn ilẹ̀ Jọ́dánì, láti àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Áánónì+ títí dé Òkè Ńlá Hámónì;+  (àwọn ọmọ Sídónì a máa pe Hámónì ní Síríónì,+ àwọn Ámórì a sì máa pè é ní Sénírì,)+ 10  gbogbo ìlú ńlá ilẹ̀ títẹ́ pẹrẹsẹ àti gbogbo Gílíádì àti gbogbo Báṣánì títí dé Sálékà+ àti Édíréì,+ àwọn ìlú ńlá tí ó jẹ́ ìjọba Ógù ní Báṣánì. 11  Nítorí pé Ógù ọba Báṣánì nìkan ni ó ṣẹ́ kù lára ohun tí ó ṣẹ́ kù nínú àwọn Réfáímù.+ Wò ó! Agà ìgbókùú rẹ̀ jẹ́ agà ìgbókùú tí a fi irin ṣe. Kì  í ha ṣe Rábà+ ti àwọn ọmọ Ámónì ni ó wà? Ìgbọ̀nwọ́ mẹ́sàn-án ni gígùn rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin sì ni fífẹ̀ rẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú ìgbọ̀nwọ́ ti ènìyàn. 12  A sì gba ilẹ̀ yìí ní àkókò yẹn gan-an; láti Áróérì,+ èyí tí ó wà lẹ́bàá àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Áánónì, àti ìdajì ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Gílíádì, àti àwọn ìlú ńlá rẹ̀ ni mo ti fi fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì.+ 13  Àti ìyókù Gílíádì+ àti gbogbo Báṣánì+ ti ìjọba Ógù ni mo ti fi fún ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè. Gbogbo ẹkùn ilẹ̀ Ágóbù+ ti gbogbo Báṣánì, òun ha kọ́ ni a máa ń pè ní ilẹ̀ àwọn Réfáímù?+ 14  “Jáírì+ ọmọkùnrin Mánásè gba gbogbo ẹkùn ilẹ̀ Ágóbù+ títí dé ààlà àwọn ará Géṣúrì+ àti àwọn ará Máákátì,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi orúkọ ara rẹ̀, Hafotu-jáírì,+ pe àwọn abúlé Báṣánì, títí di òní yìí. 15  Mákírù+ ni mo sì ti fi Gílíádì+ fún. 16  Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì+ àti àwọn ọmọ Gádì sì ni mo ti fi fún láti Gílíádì+ dé àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Áánónì, tí àárín àfonífojì olójú ọ̀gbàrá jẹ́ ààlà, àti títí dé Jábókù, àfonífojì olójú ọ̀gbàrá tí ó jẹ́ ààlà àwọn ọmọ Ámónì;+ 17  àti Árábà àti Jọ́dánì àti ojú ààlà, láti Kínérétì+ sí òkun Árábà, Òkun Iyọ̀,+ ní ìsàlẹ̀ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Písígà+ síhà yíyọ oòrùn. 18  “Nítorí náà, mo pàṣẹ fún yín ní àkókò yẹn gan-an pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run yín ti fi ilẹ̀ yìí fún yín, pé kí ẹ gbà á. Ẹ̀yin yóò ré kọjá, ní ìgbáradì, níwájú àwọn arákùnrin yín, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, gbogbo akíkanjú ọkùnrin.+ 19  Kì kì àwọn aya yín àti àwọn ọmọ yín kéékèèké àti àwọn ohun ọ̀sìn yín (mo mọ̀ dáadáa pé ẹ ní àwọn ohun ọ̀sìn púpọ̀) ni yóò máa bá a lọ ní gbígbé nínú àwọn ìlú ńlá yín tí mo ti fi fún yín,+ 20  títí Jèhófà yóò fi fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi, àti ẹ̀yin pẹ̀lú, tí àwọn pẹ̀lú yóò sì gba ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín yóò fún wọn ní òdì-kejì Jọ́dánì; lẹ́yìn èyí tí ẹ̀yin yóò padà wá, olúkúlùkù sí ilẹ̀ ìní rẹ̀ tí mo ti fi fún yín.’+ 21  “Mo sì pàṣẹ fún Jóṣúà+ ní àkókò yẹn gan-an pé, ‘Ojú rẹ ń rí gbogbo ohun tí Jèhófà Ọlọ́run yín ti ṣe sí àwọn ọba méjèèjì wọ̀nyí. Bákan náà ni Jèhófà yóò ṣe sí gbogbo ìjọba tí ìwọ yóò ré kọjá níbẹ̀.+ 22  Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ fòyà wọn, nítorí Jèhófà Ọlọ́run yín ni Ẹni tí ń jà fún yín.’+ 23  “Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí fi taratara bẹ̀bẹ̀ fún ojú rere lọ́dọ̀ Jèhófà ní àkókò yẹn gan-an pé, 24  ‘Ìwọ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ìwọ fúnra rẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí mú kí ìránṣẹ́ rẹ rí títóbi rẹ+ àti apá rẹ lílágbára,+ nítorí ta ni ọlọ́run kan ní ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀ ayé tí ń ṣe àwọn iṣẹ́ bí tìrẹ àti àwọn iṣẹ́ agbára ńlá bí tìrẹ?+ 25  Jẹ́ kí ń ré kọjá, jọ̀wọ́, kí n sì rí ilẹ̀ dáradára+ tí ó wà ní òdì-kejì Jọ́dánì, ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá dáradára yìí+ àti Lẹ́bánónì.’+ 26  Jèhófà sì ń bá a lọ láti bínú gidigidi sí mi ní tìtorí yín,+ kò sì fetí sí mi; ṣùgbọ́n Jèhófà sọ fún mi pé, ‘Ó tó ọ gẹ́ẹ́! Má ṣe tún bá mi sọ̀rọ̀ síwájú sí i mọ́ lórí ọ̀ràn yìí. 27  Gòkè lọ sí orí Písígà+ kí o sì gbé ojú rẹ sókè sí ìwọ̀-oòrùn àti àríwá àti gúúsù àti ìlà-oòrùn, kí o sì fi ojú rẹ rí i, nítorí ìwọ kì yóò ré Jọ́dánì+ yìí kọjá. 28  Sì fàṣẹ yan+ Jóṣúà, kí o sì fún un ní ìṣírí, kí o sì fún un lókun, nítorí pé òun ni ẹni tí yóò lọ+ níwájú àwọn ènìyàn yìí, òun sì ni ẹni tí yóò mú kí wọ́n jogún ilẹ̀ tí ìwọ yóò rí.’+ 29  Ní gbogbo àkókò yìí, a ń gbé ní àfonífojì tí ó wà ní iwájú Bẹti-péórù.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé