Diutarónómì 25:1-19
25 “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé awuyewuye kan dìde láàárín àwọn ènìyàn,+ tí wọ́n sì kó ara wọn wá fún ìdájọ́,+ kí wọ́n ṣe ìdájọ́ wọn, kí wọ́n sì pe olódodo ní olódodo, kí wọ́n sì pe ẹni burúkú ní ẹni burúkú.+
2 Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé bí ẹni burúkú náà bá yẹ fún lílù,+ kí onídàájọ́ náà mú kí a dá a dọ̀bálẹ̀, kí a sì fún un ní ẹgba+ níwájú onídàájọ́ náà ní iye tí ó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú iṣẹ́ burúkú rẹ̀.
3 Kí ó nà án ní ogójì ẹgba. Kí ó má ṣe fi ìkankan kún un, kí ó má bàa máa bá a lọ láti nà án ní ẹgba púpọ̀ ní àfikún sí ìwọ̀nyí,+ kí a sì dójú ti arákùnrin rẹ ní ti tòótọ́ ní ojú rẹ.
4 “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ dí akọ màlúù lẹ́nu nígbà tí ó bá ń pa ọkà.+
5 “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn arákùnrin ń gbé pa pọ̀, tí ọ̀kan nínú wọ́n sì kú láìjẹ́ pé ó ní ọmọ, aya ẹni tí ó kú kò gbọ́dọ̀ di ti ọkùnrin àjèjì kan ní òde. Kí arákùnrin ọkọ rẹ̀ lọ bá a, kí ó sì mú un láti fi ṣe aya rẹ̀, kí ó sì ṣú u lópó.+
6 Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé àkọ́bí tí obìnrin náà yóò bí yóò jogún orúkọ arákùnrin+ rẹ̀ tí ó kú, kí a má bàa nu orúkọ rẹ̀ kúrò ní Ísírẹ́lì.+
7 “Wàyí o, bí ọkùnrin náà kò bá ní inú dídùn sí mímú opó arákùnrin rẹ̀, nígbà náà, kí opó arákùnrin rẹ gòkè lọ sí ẹnubodè, sọ́dọ̀ àwọn àgbà ọkùnrin,+ kí ó sì wí pé, ‘Arákùnrin ọkọ mi kọ̀ láti pa orúkọ arákùnrin rẹ̀ mọ́ láàyè ní Ísírẹ́lì. Òun kò gbà láti ṣú mi lópó.’
8 Kí àwọn àgbà ọkùnrin ìlú ńlá ọkùnrin náà sì pè é, kí wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀, kí ó sì dúró, kí ó sì wí pé, ‘Èmi kò ní inú dídùn sí mímú un.’+
9 Látàrí èyí, opó arákùnrin rẹ̀ yóò sún mọ́ ọn lójú àwọn àgbà ọkùnrin náà, yóò sì bọ́ sálúbàtà ọkùnrin náà kúrò ní ẹsẹ̀+ rẹ̀, yóò sì tutọ́ sí i ní ojú,+ yóò sì dá a lóhùn pé, ‘Bí ó ti yẹ kí a ṣe nìyẹn sí ọkùnrin tí kì yóò gbé agbo ilé+ arákùnrin rẹ̀ ró.’
10 Ní Ísírẹ́lì, a ó sì máa pe orúkọ rẹ̀ ní ‘Ilé ẹni tí a bọ́ sálúbàtà rẹ̀.’
11 “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọkùnrin ń bá ara wọn jì jàkadì, tí aya ọ̀kan nínú wọn sì sún mọ́ tòsí láti dá ọkọ rẹ̀ nídè kúrò ní ọwọ́ ẹni tí ń lù ú, tí ó sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde, tí ó sì rá ọkùnrin náà mú ní abẹ́,+
12 nígbà náà, kí ìwọ gé ọwọ́ rẹ̀ kúrò. Kí ojú rẹ má ṣe káàánú+ rárá.
13 “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ní oríṣi ìwọ̀n+ méjì nínú àpò rẹ, ọ̀kan tí ó tóbi àti ọ̀kan tí ó kéré.
14 Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ní oríṣi òṣùwọ̀n eéfà+ méjì nínú ilé rẹ, ọ̀kan tí ó tóbi àti ọ̀kan tí ó kéré.
15 Ìwọ̀n tí ó péye tí ó sì tọ́ ni kí ó máa ní. Òṣùwọ̀n eéfà tí ó péye tí ó sì tọ́ ni kí o máa ní, kí ọjọ́ rẹ lè gùn lórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ.+
16 Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, gbogbo aláìṣèdájọ́ òdodo, jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ.
17 “Kí a ṣe ìrántí ohun tí Ámálékì ṣe sí ọ ní ọ̀nà nígbà tí ẹ̀yin ń ti Íjíbítì+ jáde wá,
18 bí ó ṣe pàdé rẹ ní ọ̀nà tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọlu gbogbo àwọn tí ń wọ́sẹ̀ rìn ní ìhà ẹ̀yìn rẹ, nígbà tí okun rẹ tán, tí àárẹ̀ sì mú ọ; òun kò sì bẹ̀rù Ọlọ́run.+
19 Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá fún ọ ní ìsinmi kúrò lọ́wọ́ gbogbo ọ̀tá rẹ tí ó wà yíká-yíká ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ bí ogún láti gbà,+ kí o nu mímẹ́nu kan Ámálékì kúrò lábẹ́ ọ̀run.+ Ìwọ kò gbọ́dọ̀ gbàgbé.

