Diutarónómì 17:1-20
17 “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi akọ màlúù tàbí àgùntàn èyí tí àbùkù wà lára rẹ̀, ohun èyíkéyìí tí ó burú, rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ; nítorí ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí ni ó jẹ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+
2 “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé a rí ní àárín rẹ, nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú ńlá rẹ, èyí tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ, ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó bá ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ, láti tẹ májẹ̀mú+ rẹ̀ lójú,
3 tí ó bá sì lọ jọ́sìn àwọn ọlọ́run mìíràn, tí ó sì tẹrí ba fún wọn tàbí fún oòrùn tàbí òṣùpá tàbí gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run,+ ohun kan tí èmi kò pa láṣẹ,+
4 tí a sì sọ ọ́ fún ọ, tí o sì gbọ́ ọ, tí o sì ṣàyẹ̀wò rẹ̀ fínnífínní, sì wò ó! tí a fìdí ohun náà múlẹ̀ pé ó jẹ́ òtítọ́,+ pé ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí yìí ni a ti ṣe ní Ísírẹ́lì!
5 kí ìwọ sì mú ọkùnrin yẹn tàbí obìnrin yẹn tí ó ṣe ohun búburú yìí jáde sí àwọn ẹnubodè rẹ, bẹ́ẹ̀ ni, ọkùnrin náà tàbí obìnrin náà, kí ìwọ sì sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ ní òkúta, irú ẹni bẹ́ẹ̀ sì gbọ́dọ̀ kú.+
6 Ẹnu ẹlẹ́rìí méjì tàbí ẹlẹ́rìí mẹ́ta+ ni kí a ti fi ikú pa ẹni tí ó yẹ sí ikú. A kì yóò fi ikú pa á ní ẹnu ẹlẹ́rìí kan.+
7 Ọwọ́ àwọn ẹlẹ́rìí náà ni kí ó kọ́kọ́ wá sára rẹ̀ láti fi ikú pa á, àti ọwọ́ gbogbo ènìyàn lẹ́yìn náà;+ kí ìwọ sì mú ohun tí ó burú kúrò láàárín rẹ.+
8 “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọ̀ràn kan tí ó béèrè fún ìpinnu ìdájọ́ ṣe àrà ọ̀tọ̀ gan-an fún ọ,+ ọ̀kan tí a ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ nínú rẹ̀,+ nínú èyí tí a gbé ìbéèrè ẹ̀tọ́ lọ́nà òfin dìde,+ tàbí tí a ti hu ìwà ipá, àwọn ọ̀ràn awuyewuye,+ nínú àwọn ẹnubodè rẹ, kí ìwọ dìde gòkè lọ sí ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò yàn,+
9 kí o sì lọ sọ́dọ̀ àwọn àlùfáà,+ àwọn ọmọ Léfì, àti sọ́dọ̀ onídàájọ́+ tí yóò máa gbéṣẹ́ ṣe ní ọjọ́ wọnnì, kí o sì ṣe ìwádìí, wọn yóò sì fi ọ̀rọ̀ ìpinnu ìdájọ́ lé ọ lọ́wọ́.+
10 Lẹ́yìn náà, kí o ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí wọn yóò fi lé ọ lọ́wọ́ láti ibi tí Jèhófà yóò yàn; kí ìwọ sì kíyè sára láti ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìtọ́ni tí wọ́n fún ọ.
11 Gẹ́gẹ́ bí òfin tí wọn yóò tọ́ka sí fún ọ, àti gẹ́gẹ́ bí ìpinnu ìdájọ́ tí wọn yóò sọ fún ọ, ni kí o ṣe.+ Ìwọ kò gbọ́dọ̀ yà kúrò lórí ọ̀rọ̀ tí wọn yóò fi lé ọ lọ́wọ́, sí ọ̀tún tàbí sí òsì.+
12 Ẹni tí ó bá sì hùwà ìkùgbù, ní ṣíṣáìfetí sí àlùfáà tí ó dúró láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ níbẹ̀ tàbí sí onídàájọ́+ náà, kí ẹni náà kú;+ kí o sì mú ohun tí ó burú kúrò ní Ísírẹ́lì.+
13 Gbogbo ènìyàn náà yóò sì gbọ́, wọn yóò sì fòyà,+ wọn kì yóò sì fi ìkùgbù gbé ìgbésẹ̀ mọ́.
14 “Lẹ́yìn-ọ̀-rẹ̀yìn, nígbà tí o bá dé sí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ, tí o sì ti gbà á, tí o sì ń gbé orí rẹ̀,+ tí o sì wí pé, ‘Jẹ́ kí ń yan ọba kan lé ara mi lórí, bí ti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó yí mi ká’;+
15 ọba tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò yàn+ ni kí ìwọ yàn lé ara rẹ lórí láìkùnà. Láàárín àwọn arákùnrin rẹ ni kí o ti yan ọba lé ara rẹ lórí. A kì yóò gbà ọ́ láyè láti fi ọmọ ilẹ̀ òkèèrè kan tí kì í ṣe arákùnrin rẹ sórí ara rẹ.
16 Kì kì pé kí ó má ṣe mú ẹṣin pọ̀ sí i fún ara rẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ ni kí ó má sì mú kí àwọn ènìyàn náà padà lọ sí Íjíbítì, kí ó bàa lè mú àwọn ẹṣin pọ̀ sí i;+ nígbà tí ó jẹ́ pé Jèhófà ti wí fún yín pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ tún padà lọ sí ọ̀nà yìí mọ́.’
17 Òun kò sì gbọ́dọ̀ sọ aya di púpọ̀ fún ara rẹ̀, kí ọkàn-àyà rẹ̀ má bàa yà kúrò;+ bẹ́ẹ̀ ni kí ó má sì mú fàdákà àti wúrà pọ̀ sí i gidigidi fún ara rẹ̀.+
18 Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí ó bá mú ìjókòó rẹ̀ lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, kí ó kọ ẹ̀dà òfin yìí sínú ìwé kan fún ara rẹ̀ láti inú èyí tí ó wà ní àbójútó àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì.+
19 “Kí ó sì máa wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì máa kà á ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ̀,+ kí ó bàa lè kọ́ láti máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀, kí ó lè máa pa gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí àti ìlànà wọ̀nyí mọ́ nípa títẹ̀lé wọ́n;+
20 kí ọkàn-àyà rẹ̀ má bàa gbé ara rẹ̀ ga lórí àwọn arákùnrin+ rẹ̀ àti kí ó má bàa yà kúrò lórí àṣẹ náà sí ọ̀tún tàbí sí òsì,+ kí ó bàa lè mú ọjọ́ rẹ̀ gùn lórí ìjọba+ rẹ̀, òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ láàárín Ísírẹ́lì.

