Dáníẹ́lì 8:1-27
8 Ní ọdún kẹta ìgbà àkóso Bẹliṣásárì+ Ọba, ìran kan fara hàn mí, àní èmi, Dáníẹ́lì, lẹ́yìn èyí tí ó fara hàn mí ní ìbẹ̀rẹ̀.+
2 Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí rí lójú ìran; ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí mo ti rí i, mo wà ní Ṣúṣánì,+ ilé aláruru, èyí tí ó wà ní Élámù,+ àgbègbè abẹ́ àṣẹ; mo sì ń bá a lọ láti rí i lójú ìran, èmi fúnra mi sì wà ní ipadò Úláì.+
3 Nígbà tí mo gbé ojú mi sókè, mo wá rí i, sì wò ó! àgbò+ kan dúró níwájú ipadò, ó sì ní ìwo méjì. Ìwo méjèèjì náà sì ga, ṣùgbọ́n ọ̀kan ga ju èkejì lọ, èyí tí ó ga jù ni ó sì jáde wá lẹ́yìn náà.+
4 Mo rí tí àgbò náà ń ṣe ìkọlù síhà ìwọ̀-oòrùn àti síhà àríwá àti síhà gúúsù, kò sì sí ẹranko ìgbẹ́ kankan tí ó dúró níwájú rẹ̀, kò sì sí ẹni tí ó ń ṣe ìdáǹdè kankan kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.+ Ó sì ṣe bí ìfẹ́ rẹ̀, ó sì gbé àgbéré ńláǹlà.
5 Ní tèmi, mo ń gbé e yẹ̀wò nìṣó, sì wò ó! akọ ewúrẹ́ kan+ wà tí ń bọ̀ láti wíwọ̀-oòrùn sórí gbogbo ilẹ̀ ayé, kò sì kanlẹ̀. Àti ní ti òbúkọ náà, ìwo kan tí ó fara hàn gbangba-gbàǹgbà wà láàárín àwọn ojú rẹ̀.+
6 Ó sì ń bọ̀ tààrà sọ́dọ̀ àgbò tí ó ní ìwo méjì náà, èyí tí mo ti rí tí ó dúró níwájú ipadò; ó sì ń sáré bọ̀ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ nínú ìhónú rẹ̀ tí ó lágbára.
7 Mo sì rí i tí ó ń sún mọ́ àgbò náà pẹ́kípẹ́kí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ìkorò hàn sí i, ó sì ń bá a lọ láti ṣá àgbò náà balẹ̀, ó sì ṣẹ́ ìwo rẹ̀ méjèèjì, kò sì sí agbára kankan nínú àgbò náà láti dúró níwájú rẹ̀. Nítorí náà, ó là á mọ́lẹ̀, ó sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, àgbò náà kò sì ní olùdáǹdè kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.+
8 Akọ ewúrẹ́ náà, ní tirẹ̀, gbé àgbéré ńláǹlà+ dé góńgó; ṣùgbọ́n gbàrà tí ó di alágbára ńlá, a ṣẹ́ ìwo ńlá náà, mẹ́rin tí ó fara hàn gbangba-gbàǹgbà sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde wá dípò rẹ̀, síhà ẹ̀fúùfù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ojú ọ̀run.+
9 Láti inú ọ̀kan lára wọn sì ni ìwo mìíràn ti jáde wá, ọ̀kan tí ó kéré,+ ó sì ń tóbi sí i gidigidi síhà gúúsù àti síhà yíyọ oòrùn àti síhà Ìṣelóge.+
10 Ó sì tóbi sí i dé iyàn-níyàn ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run,+ tí ó fi mú àwọn kan lára ẹgbẹ́ ọmọ ogun àti àwọn kan lára ìràwọ̀+ já bọ́ sí ilẹ̀, ó sì ń tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀.+
11 Àti dé iyàn-níyàn ọ̀dọ̀ Olórí+ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni ó gbé àgbéré ńláǹlà, a sì mú apá pàtàkì ìgbà gbogbo+ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, a sì wó ibi àfìdímúlẹ̀ ibùjọsìn rẹ̀ lulẹ̀.+
12 Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan ni a fi léni lọ́wọ́,+ pa pọ̀ pẹ̀lú apá pàtàkì ìgbà gbogbo,+ nítorí ìrélànàkọjá;+ ó sì ń bá a lọ láti wó òtítọ́+ mọ́lẹ̀,+ ó gbé ìgbésẹ̀, ó sì kẹ́sẹ járí.+
13 Mo sì wá gbọ́ ẹni mímọ́ kan+ tí ó sọ̀rọ̀, ẹni mímọ́ mìíràn sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún ẹni náà gan-an tí ó ń sọ̀rọ̀ pé: “Ìran apá pàtàkì ìgbà gbogbo+ àti ti ìrélànàkọjá tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro+ náà yóò ti pẹ́ tó, láti sọ ibi mímọ́ náà àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun náà di ohun ìtẹ̀mọ́lẹ̀?”+
14 Nítorí náà, ó wí fún mi pé: “Títí di ẹ̀ẹ́dégbèjìlá alẹ́ àti òwúrọ̀; dájúdájú, a óò mú ibi mímọ́ náà wá sí ipò rẹ̀ tí ó tọ́.”+
15 Nígbà náà, ó wá ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí èmi, Dáníẹ́lì, fúnra mi rí ìran náà tí mo sì ń wá òye,+ họ́wù, wò ó! ẹnì kan tí ó ní ìrísí abarapá ọkùnrin dúró ní iwájú mi.+
16 Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ohùn ará ayé ní àárín Úláì,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ké jáde pé: “Gébúrẹ́lì,+ mú kí ẹnì yẹn lóye ohun tí a rí náà.”+
17 Nítorí náà, ó wá sẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi tí mo dúró sí, ṣùgbọ́n nígbà tí ó dé, ìpayà bá mi, bẹ́ẹ̀ ni mo dojú bolẹ̀. Ó sì ń bá a lọ láti wí fún mi pé: “Kí ó yé ọ,+ ọmọ ènìyàn,+ pé ìran náà wà fún àkókò òpin.”+
18 Bí ó sì ti ń bá mi sọ̀rọ̀, mo ti sùn lọ fọnfọn ní ìdojúbolẹ̀.+ Nítorí náà, ó fọwọ́ kàn mí, ó sì mú mi dìde dúró níbi tí mo ti dúró sí rí.+
19 Ó sì ń bá a lọ láti wí pé: “Kíyè sí i, mo ń jẹ́ kí o mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn ìdálẹ́bi náà, nítorí ó wà fún àkókò òpin tí a yàn kalẹ̀.+
20 “Àgbò tí ìwọ rí tí ó ní ìwo méjì dúró fún àwọn ọba Mídíà àti Páṣíà.+
21 Òbúkọ onírun náà sì dúró fún ọba ilẹ̀ Gíríìsì;+ àti ní ti ìwo ńlá tí ó wà láàárín àwọn ojú rẹ̀, ó dúró fún ọba àkọ́kọ́.+
22 Bí ìyẹn sì ti ṣẹ́, tí ó fi jẹ́ pé mẹ́rin dìde dúró dípò rẹ̀,+ ìjọba mẹ́rin ni yóò dìde láti orílẹ̀-èdè rẹ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe pẹ̀lú agbára rẹ̀.
23 “Àti ní apá ìgbẹ̀yìn ìjọba wọn, bí àwọn olùrélànàkọjá ti ń gbé ìgbésẹ̀ lọ dé ìparí, ọba kan yóò dìde, tí ó rorò ní ojú, tí ó sì lóye àwọn ọ̀rọ̀ onítumọ̀ púpọ̀.+
24 Agbára rẹ̀ yóò sì di ńlá, ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa agbára ti òun fúnra rẹ̀.+ Yóò sì fa ìparun ní ọ̀nà àgbàyanu,+ dájúdájú yóò kẹ́sẹ járí, yóò sì gbéṣẹ́. Ní ti tòótọ́, òun yóò run àwọn alágbára ńlá, àti àwọn tí í ṣe ẹni mímọ́.+
25 Àti gẹ́gẹ́ bí ìjìnlẹ̀ òye rẹ̀, dájúdájú, yóò mú kí ẹ̀tàn kẹ́sẹ járí ní ọwọ́ rẹ̀+ pẹ̀lú. Yóò sì gbé àgbéré ńláǹlà+ ní ọkàn-àyà rẹ̀, àti lákòókò òmìnira kúrò lọ́wọ́ àníyàn,+ yóò run ọ̀pọ̀lọpọ̀. Yóò sì dìde sí Olórí àwọn ọmọ aládé,+ ṣùgbọ́n a óò ṣẹ́ ẹ láìsí ọwọ́.+
26 “Ohun tí a sì ti rí nípa alẹ́ àti òwúrọ̀, èyí tí a ti sọ, òótọ́ ni.+ Ìwọ, ní tìrẹ, pa ìran náà mọ́ láṣìírí, nítorí tí ó ṣì wà fún ọ̀pọ̀ ọjọ́.”+
27 Ní ti èmi, Dáníẹ́lì, okun mi tán, a sì mú mi ṣàìsàn fún ọjọ́ mélòó kan.+ Lẹ́yìn náà, mo dìde, mo sì ṣe iṣẹ́ ọba;+ ṣùgbọ́n ara mi kú tipiri ní tìtorí ohun tí mo rí, ẹnikẹ́ni kò sì lóye rẹ̀.+