Dáníẹ́lì 3:1-30

3  Nebukadinésárì Ọba ṣe ère+ wúrà kan, tí gíga rẹ̀ jẹ́ ọgọ́ta ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà. Ó gbé e kalẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà ní àgbègbè abẹ́ àṣẹ Bábílónì.+  Nebukadinésárì Ọba fúnra rẹ̀ sì ránṣẹ́ pe àwọn baálẹ̀, àwọn aṣíwájú+ àti àwọn gómìnà, àwọn agbani-nímọ̀ràn, àwọn olùtọ́jú ìṣúra, àwọn onídàájọ́, àwọn ọlọ́pàá agbófinró+ àti gbogbo olùṣàbójútó àgbègbè abẹ́ àṣẹ jọ láti wá síbi ayẹyẹ ṣíṣí+ ère tí Nebukadinésárì ọba gbé kalẹ̀.  Ní àkókò yẹn, àwọn baálẹ̀,+ àwọn aṣíwájú àti àwọn gómìnà, àwọn agbani-nímọ̀ràn, àwọn olùtọ́jú ìṣúra, àwọn onídàájọ́, àwọn ọlọ́pàá agbófinró àti gbogbo àwọn olùṣàbójútó àgbègbè abẹ́ àṣẹ pe ara wọn jọ fún ayẹyẹ ṣíṣí ère tí Nebukadinésárì Ọba gbé kalẹ̀, wọ́n sì dúró ní iwájú ère tí Nebukadinésárì gbé kalẹ̀.  Akéde ní gbangba+ sì ké jáde kíkankíkan pé: “A ń sọ fún yín, ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin àwùjọ orílẹ̀-èdè àti èdè,+  pé nígbà tí ẹ bá gbọ́ ìró ìwo, fèrè ape, ọpọ́n orin olókùn rẹpẹtẹ, háàpù onígun mẹ́ta, ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín, fèrè alápò awọ àti gbogbo oríṣiríṣi ohun èlò ìkọrin,+ kí ẹ wólẹ̀, kí ẹ sì jọ́sìn ère wúrà tí Nebukadinésárì Ọba gbé kalẹ̀.  Ẹnì yòówù tí kò bá wólẹ̀ kí ó sì jọ́sìn+ ni a ó sọ ní ìṣẹ́jú yẹn+ sínú ìléru oníná tí ń jó.”+  Nítorí èyí, ní àkókò kan náà tí gbogbo ènìyàn gbọ́ ìró ìwo, fèrè ape, ọpọ́n orin olókùn rẹpẹtẹ, háàpù onígun mẹ́ta, ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti gbogbo oríṣiríṣi ohun èlò ìkọrin, gbogbo ènìyàn,+ àwùjọ orílẹ̀-èdè àti èdè wólẹ̀, wọ́n sì jọ́sìn ère wúrà tí Nebukadinésárì Ọba gbé kalẹ̀.  Nítorí èyí, ní àkókò yẹn gan-an, àwọn ará Kálídíà kan wá, wọ́n sì fẹ̀sùn kan àwọn Júù.+  Wọ́n dáhùn, wọ́n sì wí fún Nebukadinésárì Ọba pé: “Kí ọba kí ó pẹ́ àní fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 10  Ọba, ìwọ fúnra rẹ ni o gbé àṣẹ náà kalẹ̀ pé kí gbogbo ènìyàn tí ó bá gbọ́ ìró ìwo, fèrè ape, ọpọ́n orin olókùn rẹpẹtẹ, háàpù onígun mẹ́ta, ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín, fèrè alápò awọ àti gbogbo oríṣiríṣi ohun èlò ìkọrin,+ kí ó wólẹ̀, kí ó sì jọ́sìn ère wúrà náà; 11  ẹnì yòówù tí kò bá sì wólẹ̀, kí ó sì jọ́sìn ni kí a sọ sínú ìléru oníná tí ń jó.+ 12  Àwọn Júù kan wà tí o yàn sípò iṣẹ́ àbójútó lórí àgbègbè abẹ́ àṣẹ Bábílónì,+ Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò; àwọn abarapá ọkùnrin yìí kò fi ọ́ pè rárá, ọba, wọn kò sin àwọn ọlọ́run rẹ, wọn kò sì jọ́sìn ère wúrà tí o gbé kalẹ̀.”+ 13  Ní àkókò yẹn, Nebukadinésárì nínú ìhónú àti ìbínú kíkan+ sọ pé kí wọ́n mú Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò wá.+ Nítorí náà, wọ́n mú àwọn abarapá ọkùnrin yìí wá síwájú ọba. 14  Nebukadinésárì dáhùn, ó sì wí fún wọn pé: “Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, ṣé bẹ́ẹ̀ ni, ní ti tòótọ́ pé ẹ kò sin àwọn ọlọ́run mi,+ ẹ kò sì jọ́sìn ère wúrà tí mo gbé kalẹ̀?+ 15  Nísinsìnyí, bí ẹ bá ti múra tán tí ó fi jẹ́ pé nígbà tí ẹ bá gbọ́ ìró ìwo, fèrè ape, ọpọ́n orin olókùn rẹpẹtẹ, háàpù onígun mẹ́ta, ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín, fèrè alápò awọ, gbogbo oríṣiríṣi ohun èlò ìkọrin,+ ẹ óò wólẹ̀, ẹ ó sì jọ́sìn ère tí mo ṣe, ó dára. Ṣùgbọ́n bí ẹ kò bá jọ́sìn, ní ìṣẹ́jú yẹn a ó sọ yín sínú ìléru oníná tí ń jó. Ta sì ni ọlọ́run yẹn tí ó lè gbà yín sílẹ̀ ní ọwọ́ mi?”+ 16  Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò dáhùn, wọ́n sì wí fún ọba pé: “Nebukadinésárì, a kò sí lábẹ́ ọ̀ranyàn rárá láti sọ ọ̀rọ̀ kankan padà fún ọ.+ 17  Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run wa, ẹni tí àwa ń sìn lè gbà wá sílẹ̀. Òun yóò gbà wá sílẹ̀ kúrò+ nínú ìléru oníná tí ń jó àti kúrò ní ọwọ́ rẹ, ọba. 18  Ṣùgbọ́n bí bẹ́ẹ̀ kọ́, jẹ́ kí ó di mímọ̀ fún ọ, ọba, pé àwọn ọlọ́run rẹ kì í ṣe èyí tí àwa ń sìn, àwa kì yóò sì jọ́sìn ère wúrà tí o gbé kalẹ̀.”+ 19  Nígbà náà ni Nebukadinésárì kún fún ìbínú kíkan, ìrísí ojú rẹ̀ sì yí padà sí Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò. Ó sì dáhùn pé kí wọ́n mú ìléru náà gbóná ní ìgbà méje ju bí a ti sábà máa ń mú un gbóná. 20  Ó sì sọ fún àwọn abarapá ọkùnrin kan tí wọ́n ní ìmí+ nínú ẹgbẹ́ ológun rẹ̀ pé kí wọ́n de Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, láti sọ wọ́n sínú ìléru oníná tí ń jó.+ 21  Nígbà náà ni wọ́n de àwọn abarapá ọkùnrin yìí nínú aṣọ àlàbora wọn, ẹ̀wù wọn, àti fìlà wọn àti aṣọ wọn yòókù, wọ́n sì sọ wọ́n sínú ìléru oníná tí ń jó. 22  Kìkì nítorí pé ọ̀rọ̀ ọba le koko tí a sì mú ìléru náà gbóná ré kọjá ààlà, àwọn abarapá ọkùnrin tí ó gbé Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò lọ ni ọwọ́ iná tí ń jó náà pa. 23  Ṣùgbọ́n àwọn abarapá ọkùnrin yòókù, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, ṣubú lulẹ̀ ní dídè sí àárín ìléru oníná tí ń jó.+ 24  Ní àkókò yẹn, jìnnìjìnnì bá Nebukadinésárì ọba, ó sì dìde pẹ̀lú ìkánjú. Ó dáhùn, ó sì wí fún àwọn olóyè rẹ̀ onípò gíga pé: “Àwọn abarapá ọkùnrin mẹ́ta ha kọ́ ni a sọ sí àárín iná ní dídè?”+ Wọ́n dá ọba lóhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, ọba.” 25  Ó dáhùn pé: “Wò ó! Abarapá ọkùnrin mẹ́rin ni mo ń rí tí wọ́n ń rìn káàkiri ní òmìnira ní àárín iná náà, ọṣẹ́ kankan kò sì ṣe wọ́n, ìrísí ẹni kẹrin sì jọ ti ọmọ àwọn ọlọ́run.”+ 26  Nígbà náà ni Nebukadinésárì sún mọ́ ilẹ̀kùn ìléru oníná tí ń jó+ náà. Ó dáhùn pé: “Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Ọlọ́run Gíga Jù Lọ,+ ẹ jáde síta kí ẹ sì máa bọ̀!” Ní àkókò yẹn, Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò jáde síta láti àárín iná náà. 27  Àwọn baálẹ̀, àwọn aṣíwájú, àwọn gómìnà, àwọn òṣìṣẹ́ onípò gíga+ ọba tí wọ́n péjọ sì wo àwọn abarapá ọkùnrin wọ̀nyí pé iná náà kò ní agbára kankan ní ara wọn,+ iná kò wi ẹyọ kan lára irun orí wọn,+ kódà aṣọ àlàbora wọn kò yí padà, òórùn iná náà kò sì sí lára wọn. 28  Nebukadinésárì dáhùn, pé: “Ìbùkún ni fún Ọlọ́run Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò,+ tí ó rán áńgẹ́lì rẹ̀,+ tí ó sì gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e+ sílẹ̀, tí wọ́n sì yí ọ̀rọ̀ ọba pàápàá padà, tí wọ́n sì jọ̀wọ́ ara wọn, nítorí pé wọn kò sìn,+ wọn kò sì jọ́sìn+ ọlọ́run èyíkéyìí rárá bí kò ṣe Ọlọ́run tiwọn.+ 29  Láti ọ̀dọ̀ mi sì ni àṣẹ ìtọ́ni kan ti jáde,+ pé ènìyàn, àwùjọ orílẹ̀-èdè tàbí èdè èyíkéyìí tí ó bá sọ ohun tí kò tọ́ sí Ọlọ́run Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, a óò gé e sí wẹ́wẹ́,+ a ó sì sọ ilé rẹ̀ di ilé ìgbọ̀nsẹ̀ gbogbo ènìyàn;+ níwọ̀n bí kò ti sí ọlọ́run mìíràn tí ó lè dáni nídè bí èyí.”+ 30  Ní àkókò yẹn, ọba mú kí Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò láásìkí ní àgbègbè abẹ́ àṣẹ Bábílónì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé