Dáníẹ́lì 11:1-45
11 “Ní tèmi, ní ọdún kìíní Dáríúsì ará Mídíà,+ mo dúró bí afúnnilókun àti bí odi agbára fún un.
2 Wàyí o, ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ ni èmi yóò sọ fún ọ:+
“Wò ó! Ọba mẹ́ta ni yóò ṣì dìde fún Páṣíà,+ ẹ̀kẹrin+ yóò sì kó ọrọ̀ jọ tìrìgàngàn ju gbogbo àwọn yòókù.+ Gbàrà tí ó bá sì ti di alágbára nínú ọrọ̀ rẹ̀, yóò gbé ohun gbogbo dìde lòdì sí ìjọba ilẹ̀ Gíríìsì.+
3 “Dájúdájú, ọba alágbára ńlá kan yóò dìde, yóò sì ṣàkóso pẹ̀lú àṣẹ ìṣàkóso tí ó gbilẹ̀,+ yóò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀.+
4 Nígbà tí ó bá sì ti dìde,+ a óò fọ́ ìjọba rẹ̀, a ó sì pín in sí ẹ̀fúùfù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin+ ojú ọ̀run,+ ṣùgbọ́n kì í ṣe fún ìran àtẹ̀lé rẹ̀,+ kì í sì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ ìṣàkóso rẹ̀, èyí tí ó fi ṣàkóso; nítorí pé a ó fa ìjọba rẹ̀ tu tigbòǹgbò-tigbòǹgbò, àní fún àwọn mìíràn dípò ìwọ̀nyí.
5 “Ọba gúúsù yóò sì di alágbára, àní ọ̀kan lára àwọn ọmọ aládé rẹ̀; yóò sì borí rẹ̀, yóò sì ṣàkóso pẹ̀lú àṣẹ ìṣàkóso tí ó gbilẹ̀ ju ti agbára ìṣàkóso ẹni yẹn lọ.
6 “Àti ní òpin àwọn ọdún mélòó kan, wọn yóò bá ara wọn ní àjọṣepọ̀, ọmọbìnrin ọba gúúsù fúnra rẹ̀ yóò sì wá sọ́dọ̀ ọba àríwá láti ṣe ètò ìfẹ̀tọ́-bánilò-lọ́gbọọgba. Ṣùgbọ́n ọmọbìnrin náà kì yóò ní agbára ní apá rẹ̀;+ ọkùnrin náà kì yóò sì dúró, bẹ́ẹ̀ sì ni apá rẹ̀; a ó sì jọ̀wọ́ ọmọbìnrin náà lọ́wọ́, òun fúnra rẹ̀, àti àwọn tí ó mú ọmọbìnrin náà wá àti ọkùnrin náà tí ó bí i, àti ẹni tí ó sọ ọmọbìnrin náà di alágbára ní àwọn àkókò wọnnì.
7 Ẹnì kan yóò sì dìde láti inú èéhù+ gbòǹgbò ọmọbìnrin náà ní ipò ọkùnrin náà, yóò sì wá lòdì sí ẹgbẹ́ ológun àti lòdì sí odi agbára ọba àríwá, yóò sì gbé ìgbésẹ̀ lòdì sí wọn, yóò sì borí.
8 Àti pẹ̀lú àwọn ọlọ́run wọn,+ pẹ̀lú ère dídà wọn, pẹ̀lú àwọn ohun èlò fàdákà àti ti wúrà wọn fífani-lọ́kàn-mọ́ra, àti pẹ̀lú àwọn òǹdè ni yóò wá sí Íjíbítì. Fún ọdún mélòó kan, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró ní títakété sí ọba àríwá.
9 “Ní ti tòótọ́, òun yóò wá sínú ìjọba ọba gúúsù, yóò sì padà lọ sí ilẹ̀ rẹ̀.
10 “Wàyí o, ní ti àwọn ọmọ rẹ̀, wọn yóò ru ara wọn sókè, wọn yóò sì kó ogunlọ́gọ̀ ẹgbẹ́ ológun ńlá jọpọ̀ ní ti gidi. Ní dídé, dájúdájú yóò dé, yóò kún, yóò sì kọjá. Ṣùgbọ́n yóò padà, yóò sì ru ara rẹ̀ sókè dé iyàn-níyàn odi agbára rẹ̀.
11 “Ọba gúúsù yóò sì mú ara rẹ̀ korò, yóò sì jáde lọ láti bá a jà, èyíinì ni, pẹ̀lú ọba àríwá; dájúdájú, yóò mú kí ogunlọ́gọ̀ ńlá dìde, a ó sì fi ogunlọ́gọ̀ náà lé ẹni yẹn lọ́wọ́+ ní ti gidi.
12 Dájúdáju, a óò kó ogunlọ́gọ̀ náà lọ. Ọkàn-àyà rẹ̀ yóò di èyí tí a gbé ga,+ òun yóò sì mú ẹgbẹẹgbẹ̀rún mẹ́wàá-mẹ́wàá ṣubú ní ti gidi; ṣùgbọ́n kì yóò lo ipò alágbára rẹ̀.
13 “Ọba àríwá yóò sì padà, yóò sì kó ogunlọ́gọ̀ jọ tí ó pọ̀ ju ti àkọ́kọ́; àti lẹ́yìn òpin àkókò náà, ní ọdún mélòó kan, yóò dé, ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ ológun ńláǹlà+ àti pẹ̀lú ẹrù púpọ̀ rẹpẹtẹ.+
14 Àti ní àkókò wọnnì, ọ̀pọ̀ yóò dìde sí ọba gúúsù.
“Ní tiwọn, àwọn ọmọ ọlọ́ṣà tí ó jẹ́ ti àwọn ènìyàn rẹ ni a óò gbé lọ nínú ìgbìyànjú láti mú kí ìran kan ní ìmúṣẹ;+ wọn yóò sì kọsẹ̀.+
15 “Ọba àríwá yóò sì wá, yóò sì yára kọ́ ohun àfiṣe-odi ìsàgatì kan,+ yóò sì gba ìlú ńlá tí ó ní odi ní ti gidi. Àti ní ti apá gúúsù, wọn kì yóò dúró, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn ààyò rẹ̀; kì yóò sì sí agbára láti dúró.
16 Ẹni tí ó sì ń bọ̀ láti gbéjà kò ó yóò ṣe ìfẹ́ ara rẹ̀, kì yóò sì sí ẹni tí yóò dúró níwájú rẹ̀. Yóò sì dúró ní ilẹ̀ Ìṣelóge,+ ìparun pátápátá yóò sì wà ní ọwọ́ rẹ̀.+
17 Yóò sì fi ojú sí+ wíwá pẹ̀lú ipá alágbára ti gbogbo ìjọba rẹ̀ pátá, yóò sì ní àdéhùn ìfẹ̀tọ́-bánilò-lọ́gbọọgba;+ yóò sì gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́.+ Ní ti ọmọbìnrin ẹ̀dá obìnrin, a ó yọ̀ǹda fún ọkùnrin náà láti run ún. Obìnrin náà kì yóò dúró, kì yóò jẹ́ ti ọkùnrin náà mọ́.+
18 Yóò sì yí ojú rẹ̀ padà sí ilẹ̀ etí òkun,+ yóò sì kó ọ̀pọ̀ ní ti gidi. Ọ̀gágun kan yóò sì ní láti mú kí ẹ̀gàn rẹ̀ kásẹ̀ nílẹ̀ fún ara rẹ̀, kí ẹ̀gàn rẹ̀ má bàa sí mọ́. Yóò mú kí ó yí padà sórí ẹni yẹn.
19 Yóò sì yí ojú rẹ̀ padà sí odi agbára ilẹ̀ tirẹ̀ fúnra rẹ̀, òun yóò sì kọsẹ̀, yóò sì ṣubú, a kì yóò sì rí i.+
20 “Ẹnì kan yóò sì dìde ní ipò rẹ̀,+ ẹni tí ń mú kí afipámúni+ la ìjọba ọlọ́lá ńlá náà kọjá, àti ní ìwọ̀n ọjọ́ díẹ̀ a óò ṣẹ́ ẹ, ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú ìbínú tàbí nínú ogun.
21 “Ẹnì kan tí a óò tẹ́ńbẹ́lú+ yóò sì dìde ní ipò rẹ̀, wọn kì yóò sì fi iyì ìjọba náà fún un; ní ti gidi, òun yóò wọlé lákòókò òmìnira kúrò lọ́wọ́ àníyàn,+ yóò sì gba ìjọba náà nípasẹ̀ ìpọ́nni dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in.+
22 Ní ti apá+ ìkún omi náà, wọn yóò sì kún àkúnya ní tìtorí rẹ̀, a ó sì ṣẹ́ wọn;+ bí a ó ti ṣẹ́+ Aṣáájú+ májẹ̀mú+ náà pẹ̀lú.
23 Àti nítorí àjọṣepọ̀ tí wọ́n ní pẹ̀lú rẹ̀, yóò máa bá a lọ ní ṣíṣe ẹ̀tàn, yóò sì gòkè wá ní ti gidi, yóò sì di alágbára ńlá nípasẹ̀ orílẹ̀-èdè kékeré.+
24 Lákòókò òmìnira kúrò lọ́wọ́ àníyàn,+ kódà òun yóò wọnú ọ̀rá àgbègbè abẹ́ àṣẹ, ní ti gidi yóò sì ṣe ohun tí àwọn baba rẹ̀ àti àwọn baba baba rẹ̀ kò ṣe. Yóò tú ohun tí a piyẹ́ àti ohun ìfiṣèjẹ àti àwọn ẹrù ká láàárín wọn; ìpètepèrò rẹ̀+ yóò sì jẹ́ ní ìlòdìsí àwọn ibi olódi, ṣùgbọ́n títí di àkókò kan ni.
25 “Yóò sì ru agbára rẹ̀ àti ọkàn-àyà rẹ̀ dìde sí ọba gúúsù pẹ̀lú ẹgbẹ́ ológun ńláǹlà; ọba gúúsù, ní tirẹ̀, yóò sì ru ara rẹ̀ sókè fún ogun pẹ̀lú ẹgbẹ́ ológun kan tí ó pọ̀ lọ́nà tí ó peléke tí ó sì lágbára ńlá. Òun kì yóò sì dúró, nítorí wọn yóò pète-pèrò ní ìlòdìsí i.
26 Àwọn náà gan-an tí ń jẹ oúnjẹ adùnyùngbà rẹ̀ ni yóò sì fa ìwópalẹ̀ rẹ̀.
“Àti ní ti ẹgbẹ́ ológun rẹ̀, ìkún omi yóò gbé e lọ, ọ̀pọ̀ yóò sì ṣubú sílẹ̀ ní òkú.
27 “Àti ní ti ọba méjì yìí, ọkàn-àyà wọn yóò ní ìtẹ̀sí ṣíṣe ohun búburú, àti ní tábìlì kan náà,+ wọn yóò máa pa irọ́.+ Ṣùgbọ́n nǹkan kan kì yóò kẹ́sẹ járí,+ nítorí òpin ṣì jẹ́ fún àkókò tí a yàn kalẹ̀.+
28 “Òun yóò sì padà lọ sí ilẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ẹrù púpọ̀ rẹpẹtẹ, ọkàn-àyà rẹ̀ yóò sì lòdì sí májẹ̀mú mímọ́.+ Yóò sì gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́,+ dájúdájú, yóò sì padà lọ sí ilẹ̀ rẹ̀.
29 “Ní àkókò tí a yàn kalẹ̀,+ òun yóò padà, òun yóò sì wá lòdì sí gúúsù+ ní ti gidi; ṣùgbọ́n kì yóò rí ní ìkẹyìn bí ó ti rí ní àkọ́kọ́.
30 Dájúdájú, àwọn ọkọ̀ òkun àwọn ará Kítímù+ yóò gbéjà kò ó, ìdoríkodò yóò sì bá a.
“Òun yóò sì padà ní ti tòótọ́, yóò sì fi ìdálẹ́bi sọ̀kò+ sí májẹ̀mú mímọ́,+ yóò sì gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà tí ó gbéṣẹ́; òun yóò sì ní láti padà, yóò sì fún àwọn tí ń fi májẹ̀mú mímọ́ sílẹ̀ ní àfiyèsí.
31 Àwọn apá yóò sì dìde, láti ọ̀dọ̀ rẹ̀; ní ti tòótọ́, wọn yóò sọ ibùjọsìn,+ odi agbára di aláìmọ́, wọn yóò sì mú apá pàtàkì ìgbà gbogbo kúrò.+
“Dájúdájú, wọn yóò gbé ohun ìríra+ tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro+ kalẹ̀.
32 “Àwọn tí ń ṣe ohun burúkú sí májẹ̀mú+ náà ni òun yóò sì ṣamọ̀nà sí ìpẹ̀yìndà+ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in.+ Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ènìyàn tí wọ́n mọ Ọlọ́run wọn,+ wọn yóò borí,+ wọn yóò sì gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́.
33 Àti ní ti àwọn tí wọ́n ní ìjìnlẹ̀ òye+ nínú àwọn ènìyàn náà, wọn yóò la ọ̀pọ̀ lóye.+ Dájúdájú, a óò mú wọn kọsẹ̀ nípa idà àti ọwọ́ iná, nípa oko òǹdè àti ìpiyẹ́,+ fún ọjọ́ mélòó kan.
34 Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá mú wọn kọsẹ̀, a ó fi ìrànlọ́wọ́ díẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́;+ dájúdájú, ọ̀pọ̀ yóò dara pọ̀ mọ́ wọn nípasẹ̀ ìpọ́nni dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in.+
35 A ó sì mú lára àwọn tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye kọsẹ̀,+ láti lè ṣe iṣẹ́ ìyọ́mọ́ nítorí wọn àti láti lè ṣe ìwẹ̀nùmọ́ àti láti lè ṣe ìsọdi-funfun,+ títí di àkókò òpin;+ nítorí pé ó ṣì jẹ́ fún àkókò tí a yàn kalẹ̀.+
36 “Ọba náà yóò sì ṣe bí ìfẹ́ rẹ̀ ní ti gidi, yóò sì gbé ara rẹ̀ ga, yóò sì gbé ara rẹ̀ ga lọ́lá ju gbogbo ọlọ́run lọ;+ yóò sì sọ àwọn ohun ìyanu lòdì sí Ọlọ́run àwọn ọlọ́run.+ Dájúdájú, yóò kẹ́sẹ járí títí ìdálẹ́bi náà yóò fi wá sí òpin;+ nítorí ohun tí a ti ṣe ìpinnu lé lórí ni a gbọ́dọ̀ ṣe.
37 Kò sì ní náání Ọlọ́run àwọn baba rẹ̀; ìfẹ́-ọkàn fún obìnrin àti gbogbo ọlọ́run mìíràn ni kì yóò sì náání, ṣùgbọ́n yóò gbé ara rẹ̀ ga lọ́lá lórí ẹni gbogbo.+
38 Ṣùgbọ́n ní ipò rẹ̀, yóò fi ògo fún ọlọ́run odi agbára; àti ọlọ́run tí àwọn baba rẹ̀ kò mọ̀ ni òun yóò fi ògo fún nípasẹ̀ wúrà àti nípasẹ̀ fàdákà àti nípasẹ̀ òkúta iyebíye àti nípasẹ̀ àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra.
39 Òun yóò sì gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́ lòdì sí àwọn ibi odi agbára tí a dáàbò bò jù lọ, pa pọ̀ pẹ̀lú ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè. Ẹnì yòówù tí ó bá fún un ní àkànṣe àfiyèsí ni òun yóò mú pọ̀ gidigidi ní ògo, ní ti gidi, òun yóò sì mú wọn ṣàkóso láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀; yóò sì pín ilẹ̀ fún iye owó kan.
40 “Àti ní àkókò òpin, ọba gúúsù+ yóò bá a ta kàn-ǹ-gbọ̀n, ọba àríwá yóò sì fipá rọ́lù ú pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣin àti pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ọkọ̀ òkun; yóò sì wọ ilẹ̀ náà, yóò ya lù ú, yóò sì là á kọjá.
41 Ní ti gidi, yóò wọ+ ilẹ̀ Ìṣelóge+ pẹ̀lú, a ó sì mú ọ̀pọ̀ ilẹ̀ kọsẹ̀.+ Ṣùgbọ́n ìwọ̀nyí ni àwọn tí yóò sá àsálà kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, Édómù àti Móábù+ àti lájorí lára àwọn ọmọ Ámónì.
42 Yóò sì máa na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí àwọn ilẹ̀ náà; àti ní ti ilẹ̀ Íjíbítì,+ kì yóò jẹ́ olùsálà.
43 Òun yóò sì ṣàkóso ní ti gidi lórí àwọn ìṣúra fífarasin ti wúrà àti fàdákà àti lórí gbogbo ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra ti Íjíbítì. Àwọn ará Líbíà àti àwọn ará Etiópíà yóò sì wà ní ìṣísẹ̀ rẹ̀.
44 “Ṣùgbọ́n ìròyìn kan yóò wà tí yóò yọ ọ́ lẹ́nu,+ láti yíyọ oòrùn+ àti láti àríwá, dájúdájú yóò jáde lọ nínú ìhónú ńláǹlà láti pani rẹ́ ráúráú àti láti ya ọ̀pọ̀ sọ́tọ̀ fún ìparun.+
45 Yóò sì pa àgọ́ rẹ̀ tí ó dà bí ààfin sáàárín òkun títóbi lọ́lá náà àti òkè ńlá mímọ́ Ìṣelóge;+ ó sì dájú pé yóò wá ní tààrà sí òpin rẹ̀,+ kì yóò sì sí olùrànlọ́wọ́ kankan fún un.+

