Dáníẹ́lì 1:1-21
1 Ní ọdún kẹta ìgbà àkóso Jèhóákímù+ ọba Júdà, Nebukadinésárì ọba Bábílónì wá sí Jerúsálẹ́mù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sàga tì í.+
2 Nígbà tí ó ṣe, Jèhófà fi Jèhóákímù ọba Júdà+ lé e lọ́wọ́ àti apá kan lára àwọn nǹkan èlò+ ilé Ọlọ́run tòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni ó kó wọn wá sí ilẹ̀ Ṣínárì+ sí ilé ọlọ́run rẹ̀; àwọn nǹkan èlò náà ni ó sì kó wá sí ilé ìṣúra ọlọ́run+ rẹ̀.
3 Lẹ́yìn náà ni ọba sọ fún Áṣípénásì olórí òṣìṣẹ́+ rẹ̀ láàfin pé kí ó mú àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn ọmọ ọba àti ti àwọn ọ̀tọ̀kùlú+ wá,
4 àwọn ọmọ tí kò ní àbùkù+ rárá, ṣùgbọ́n tí wọ́n dára ní ìrísí, tí wọ́n sì ní ìjìnlẹ̀ òye nínú ọgbọ́n+ gbogbo, tí wọ́n ní ìmọ̀ gan-an, tí wọ́n sì ní ìfòyemọ̀ ohun tí a mọ̀,+ tí wọ́n sì tún ní agbára láti dúró ní ààfin ọba;+ kí a sì kọ́ wọn ní ìkọ̀wé àti ahọ́n àwọn ará Kálídíà.
5 Síwájú sí i, ọba ṣètò ohun tí a yọ̀ǹda lójoojúmọ́ fún wọn láti inú àwọn oúnjẹ adùnyùngbà+ ọba àti láti inú wáìnì tí ó ń mu, àní láti fi bọ́ wọn fún ọdún mẹ́ta, kí wọ́n bàa lè dúró níwájú ọba ní òpin ọdún mẹ́ta náà.
6 Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn kan lára àwọn ọmọ Júdà wà lára wọn, Dáníẹ́lì,+ Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà.+
7 Sàràkí náà tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin sì fún wọn ní orúkọ.+ Ó sì fún Dáníẹ́lì ní orúkọ náà Bẹliteṣásárì;+ ó fún Hananáyà ní Ṣádírákì; ó fún Míṣáẹ́lì ní Méṣákì; ó fún Asaráyà ní Àbẹ́dinígò.+
8 Ṣùgbọ́n Dáníẹ́lì pinnu ní ọkàn-àyà rẹ̀ pé òun kì yóò sọ ara òun di eléèérí+ nípasẹ̀ àwọn oúnjẹ adùnyùngbà ọba àti wáìnì tí ó ń mu. Ó sì ń béèrè lọ́dọ̀ sàràkí náà tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin, kí òun má bàa sọ ara òun di eléèérí.+
9 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Ọlọ́run tòótọ́ fi Dáníẹ́lì fún inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti àánú níwájú sàràkí náà tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin náà.+
10 Nítorí náà, sàràkí náà tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin náà wí fún Dáníẹ́lì pé: “Mo bẹ̀rù olúwa mi ọba, ẹni tí ó ti ṣètò oúnjẹ yín àti ohun mímu yín.+ Kí wá ni ìdí tí yóò fi rí i pé ojú yín rẹ̀wẹ̀sì ní ìfiwéra pẹ̀lú ti àwọn ọmọ tí ẹ jọ jẹ́ ọjọ́ orí kan náà, èé sì ti ṣe tí ẹ óò fi sọ orí mi di ẹlẹ́bi lọ́dọ̀ ọba?”
11 Ṣùgbọ́n Dáníẹ́lì sọ fún olùtọ́jú tí sàràkí náà tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́+ láàfin yàn sípò lórí Dáníẹ́lì, Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà pé:
12 “Jọ̀wọ́, dán àwọn ìránṣẹ́ rẹ wò fún ọjọ́ mẹ́wàá, sì jẹ́ kí wọ́n fún wa ní àwọn ọ̀gbìn oko+ láti jẹ àti omi láti mu;
13 sì jẹ́ kí ojú àwa àti ojú àwọn ọmọ tí wọ́n ń jẹ àwọn oúnjẹ adùnyùngbà ọba fara hàn níwájú rẹ, kí o sì ṣe sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí o bá rí.”
14 Níkẹyìn, ó fetí sí wọn lórí ọ̀ràn yìí, ó sì dán wọn wò fún ọjọ́ mẹ́wàá.
15 Ní òpin ọjọ́ mẹ́wàá, ojú wọn sì fara hàn lọ́nà tí ó túbọ̀ dára sí i, tí wọ́n sì sanra sí i ní ẹran ara ju gbogbo àwọn ọmọ tí ń jẹ àwọn oúnjẹ adùnyùngbà ọba.+
16 Nítorí náà, olùtọ́jú náà ń bá a nìṣó láti kó àwọn oúnjẹ adùnyùngbà àti wáìnì mímu tiwọn lọ, ó sì ń fún wọn ní ọ̀gbìn oko.+
17 Àti ní ti àwọn ọmọ wọ̀nyí, àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, Ọlọ́run tòótọ́ fún wọn ní ìmọ̀ àti ìjìnlẹ̀ òye nínú gbogbo ìkọ̀wé àti ọgbọ́n;+ Dáníẹ́lì alára sì ní òye nínú gbogbo onírúurú ìran àti àlá.+
18 Àti pé ní òpin àwọn ọjọ́ tí ọba sọ pé kí a mú wọn wá,+ sàràkí náà tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin pẹ̀lú tẹ̀ síwájú láti mú wọn wá síwájú Nebukadinésárì.
19 Ọba sì bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn sọ̀rọ̀, nínú gbogbo wọn, a kò rí ọ̀kankan bí Dáníẹ́lì, Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà;+ wọ́n sì ń bá a lọ láti dúró níwájú ọba.+
20 Àti ní ti gbogbo ọ̀ràn ọgbọ́n àti òye+ tí ọba wádìí lọ́wọ́ wọn, ó tilẹ̀ rí i pé wọ́n fi ìlọ́po mẹ́wàá sàn ju gbogbo àwọn àlùfáà+ pidánpidán àti alálùpàyídà+ tí ó wà ní gbogbo ilẹ̀ ọba rẹ̀.
21 Dáníẹ́lì sì ń bá a lọ títí di ọdún àkọ́kọ́ Kírúsì Ọba.+

