Aísáyà 8:1-22
8 Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti sọ fún mi pé: “Mú wàláà+ ńlá kan fún ara rẹ, kí o sì fi kálàmù ẹni kíkú kọ ‘Maheri-ṣalali-háṣí-básì’ sára rẹ̀.
2 Sì jẹ́ kí n ní ẹ̀rí tí ń fìdí ọ̀ràn múlẹ̀+ fún ara mi nípasẹ̀ àwọn ẹlẹ́rìí olùṣòtítọ́,+ Ùráyà àlùfáà+ àti Sekaráyà ọmọkùnrin Jeberekáyà.”
3 Nígbà náà ni mo sún mọ́ wòlíì obìnrin náà, ó sì wá lóyún, nígbà tí ó ṣe, ó bí ọmọkùnrin kan.+ Jèhófà sọ fún mi wàyí pé: “Pe orúkọ rẹ̀ ní Maheri-ṣalali-háṣí-básì,
4 nítorí pé kí ọmọdékùnrin náà tó mọ bí a ti ń pe,+ ‘Baba mi!’ àti ‘Ìyá mi!’ ẹnì kan yóò kó àwọn ohun àmúṣọrọ̀ Damásíkù àti ohun ìfiṣèjẹ Samáríà lọ níwájú ọba Ásíríà.”+
5 Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti bá mi sọ̀rọ̀ síwájú sí i, pé:
6 “Nítorí ìdí náà pé àwọn ènìyàn yìí ti kọ+ omi Ṣílóà+ tí ó rọra ń ṣàn jẹ́ẹ́, tí ayọ̀ ńláǹlà+ sì wà nítorí Résínì àti ọmọkùnrin Remaláyà;+
7 àní nítorí náà, wò ó! Jèhófà yóò gbé omi tí ó ní agbára ńlá tí ó sì pọ̀, tí ó jẹ́ ti Odò+ náà dìde sí wọn,+ èyíinì ni ọba Ásíríà+ àti gbogbo ògo rẹ̀.+ Dájúdájú, òun yóò sì gòkè wá sórí gbogbo ojú ìṣàn omi rẹ̀, yóò sì gun orí gbogbo bèbè rẹ̀,
8 yóò sì la Júdà já. Ní ti tòótọ́, òun yóò kún bò ó.+ Yóò kan ọrùn.+ Ìnàjáde ìyẹ́ apá+ rẹ̀ yóò sì ṣẹlẹ̀ láti lè kún ìbú ilẹ̀ rẹ, ìwọ Ìmánúẹ́lì!”+
9 Ẹ jẹ́ aṣeniléṣe, ẹ̀yin ènìyàn, kí a sì fọ́ yín túútúú; ẹ sì fetí sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ wà ní àwọn apá ibi jíjìnnà ilẹ̀ ayé!+ Ẹ di ara yín lámùrè,+ kí a sì fọ́ yín túútúú!+ Ẹ di ara yín lámùrè, kí a sì fọ́ yín túútúú!
10 Ẹ wéwèé ìpètepèrò, a ó sì fọ́ ọ túútúú!+ Ẹ sọ ọ̀rọ̀ èyíkéyìí, kì yóò sì dúró, nítorí pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa!+
11 Nítorí pé èyí ni ohun tí Jèhófà fi líle ọwọ́ sọ fún mi, kí ó lè mú mi yà kúrò nínú rírìn ní ọ̀nà àwọn ènìyàn yìí, ó wí pé:
12 “Ẹ kò gbọ́dọ̀ sọ pé, ‘Tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun!’ ní ti gbogbo èyí tí àwọn ènìyàn yìí ń sọ pé, ‘Tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun!’+ àti pé ẹ kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù ohun ẹ̀rù wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọ́dọ̀ wárìrì nítorí rẹ̀.+
13 Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun—òun ni Ẹni tí ó yẹ kí ẹ kà sí mímọ́,+ òun sì ni ó yẹ kí ó jẹ́ ohun ẹ̀rù yín,+ òun sì ni Ẹni tí ó yẹ kí ó máa mú yín wárìrì.”+
14 Òun yóò sì dà bí ibi ọlọ́wọ̀;+ ṣùgbọ́n bí òkúta tí a kọlù àti àpáta tí a kọsẹ̀ lára rẹ̀+ sí àwọn ilé Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí pańpẹ́ àti gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn sí àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù.+
15 Ó sì dájú pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú, a ó sì ṣẹ́ wọn, a ó sì dẹkùn mú wọn.+
16 Wíwé ni kí o wé ẹ̀rí tí ń fìdí ọ̀ràn múlẹ̀,+ fi èdìdì di òfin yí ká láàárín àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi!+
17 Ṣe ni èmi yóò máa bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún Jèhófà,+ ẹni tí ń fi ojú rẹ̀ pa mọ́ fún ilé Jékọ́bù,+ èmi yóò sì ní ìrètí nínú rẹ̀.+
18 Wò ó! Èmi àti àwọn ọmọ tí Jèhófà ti fi fún mi+ dà bí àmì+ àti bí iṣẹ́ ìyanu ní Ísírẹ́lì láti ọ̀dọ̀ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ẹni tí ń gbé ní Òkè Ńlá Síónì.+
19 Bí ó bá sì wá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n sọ fún yín pé: “Ẹ béèrè fún nǹkan lọ́wọ́ àwọn abẹ́mìílò+ tàbí lọ́wọ́ àwọn tí ó ní ẹ̀mí ìsàsọtẹ́lẹ̀, àwọn tí ń ké ṣíoṣío,+ tí wọ́n sì ń sọ àwọn àsọjáde ní ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́,” kì í ha ṣe ọwọ́ Ọlọ́run rẹ̀ ni ó yẹ kí ènìyàn ti máa béèrè fún nǹkan?+ [Ó ha yẹ kí ìbéèrè fún nǹkan] lọ́wọ́ àwọn òkú nítorí àwọn alààyè [ṣẹlẹ̀] bí?+
20 Sí òfin àti sí ẹ̀rí tí ń fìdí ọ̀ràn múlẹ̀!+
Dájúdájú, wọn yóò máa sọ gẹ́gẹ́ bí gbólóhùn yìí+ tí kì yóò ní ìmọ́lẹ̀ ọ̀yẹ̀.+
21 Dájúdájú, olúkúlùkù yóò gba ilẹ̀ náà kọjá nínú ìnilára dé góńgó àti nínú ebi;+ yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, nítorí tí ebi ń pa á, tí ó sì ti mú kí ìkannú rẹ̀ ru, ní ti tòótọ́ òun yóò pe ibi wá sórí ọba rẹ̀ àti sórí Ọlọ́run rẹ̀,+ yóò sì gbójú sókè dájúdájú.
22 Yóò sì wo ilẹ̀, sá wò ó! wàhálà àti òkùnkùn,+ ìríran bàìbàì, àwọn àkókò ìnira àti ìṣúdùdù láìsí ìtànyòò.+

