Aísáyà 63:1-19

63  Ta nìyí tí ń bọ̀ láti Édómù,+ ẹni tí ó wọ ẹ̀wù aláwọ̀ títàn láti Bósírà,+ ẹni yìí tí ó ní ọlá nínú aṣọ rẹ̀, tí ó ń yan lọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu agbára rẹ̀? “Èmi ni, Ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ní òdodo,+ Ẹni tí ó pọ̀ gidigidi ní agbára láti gbani là.”+ 2  Èé ṣe tí aṣọ rẹ fi pupa, tí ẹ̀wù rẹ sì dà bí ti ẹni tí ń tẹ wáìnì ní ibi ìfúntí wáìnì?+ 3  “Ọpọ́n wáìnì ni mo ti tẹ̀ ní èmi nìkan,+ nígbà tí kò sí ẹnì kankan pẹ̀lú mi láti inú àwọn ènìyàn. Mo sì ń tẹ̀ wọ́n nìṣó nínú ìbínú mi,+ mo sì ń tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ nínú ìhónú mi.+ Ẹ̀jẹ̀ wọn tí ń tú ṣùrùṣùrù sì ń fún ṣẹ̀rẹ̀ṣẹ̀rẹ̀ sára ẹ̀wù mi,+ gbogbo aṣọ mi sì ni mo ti sọ di eléèérí. 4  Nítorí pé ọjọ́ ẹ̀san ń bẹ ní ọkàn-àyà mi,+ àní ọdún àwọn tí mo tún rà ti dé. 5  Mo sì ń wò ṣáá, ṣùgbọ́n kò sí olùrànlọ́wọ́ kankan; ẹnu sì bẹ̀rẹ̀ sí yà mí, ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kankan tí ó pèsè ìtìlẹyìn.+ Nítorí náà, apá mi mú ìgbàlà wá fún mi,+ ìhónú mi+ sì ni ohun tí ó tì mí lẹ́yìn. 6  Mo sì ń fi ẹsẹ̀ tẹ àwọn ènìyàn mọ́lẹ̀ nínú ìbínú mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí mú kí wọ́n mu ìhónú mi+ ní àmupara, mo sì mú kí ẹ̀jẹ̀ wọn tí ń tú ṣùrùṣùrù dà wá sí ilẹ̀.”+ 7  Àwọn inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ti Jèhófà ni èmi yóò mẹ́nu kàn,+ àwọn ìyìn Jèhófà, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa,+ àní oore púpọ̀ yanturu fún ilé Ísírẹ́lì,+ èyí tí òun ti ṣe fún wọn ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àánú rẹ̀+ àti ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pọ̀ yanturu àwọn inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́. 8  Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Dájúdájú, ènìyàn mi ni wọ́n,+ àwọn ọmọ tí kì yóò já sí èké.”+ Nítorí náà, àwọn ni òun wá jẹ́ Olùgbàlà fún.+ 9  Nínú gbogbo wàhálà wọn, ó jẹ́ wàhálà fún un.+ Ońṣẹ́ òun tìkára rẹ̀ sì ni ó gbà wọ́n là.+ Nínú ìfẹ́ rẹ̀ àti nínú ìyọ́nú rẹ̀, òun tìkára rẹ̀ tún wọn rà,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé wọn sókè, ó sì rù wọ́n ní gbogbo ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn.+ 10  Ṣùgbọ́n àwọn tìkára wọ́n ṣọ̀tẹ̀,+ wọ́n sì ba ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ nínú jẹ́.+ Wàyí o, ó yí padà di ọ̀tá+ wọn; òun fúnra rẹ̀ bá wọn jagun.+ 11  Ẹnì kan sì bẹ̀rẹ̀ sí rántí àwọn ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn, Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀, pé: “Ẹni tí ó mú wọn gòkè wá láti inú òkun+ pẹ̀lú àwọn olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran rẹ̀+ dà? Ẹni tí ó fi ẹ̀mí mímọ́ Rẹ̀+ sínú rẹ̀ dà? 12  Ẹni tí ó mú kí apá Rẹ̀+ ẹlẹ́wà lọ ní ọwọ́ ọ̀tún Mósè; Ẹni tí ó pín omi níyà níwájú wọn,+ kí ó bàa lè ṣe orúkọ tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin fún ara rẹ̀;+ 13  Ẹni tí ó mú wọn rin àárín omi ríru kọjá tí ó fi jẹ́ pé, gẹ́gẹ́ bí ẹṣin ní aginjù, wọn kò kọsẹ̀?+ 14  Gẹ́gẹ́ bí ẹranko ti ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì, àní ẹ̀mí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí mú kí wọ́n sinmi.”+ Bí o ṣe ṣamọ̀nà àwọn ènìyàn rẹ nìyẹn, kí o bàa lè ṣe orúkọ ẹlẹ́wà fún ara rẹ.+ 15  Wò láti ọ̀run,+ kí o sì rí láti ibùjókòó rẹ gíga fíofío ti ìjẹ́mímọ́ àti ẹwà.+ Ìtara+ rẹ àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá rẹ, rírugùdù ìhà inú rẹ,+ àti àwọn àánú rẹ+ dà? Wọ́n ti ká ara wọn lọ́wọ́ kò sí mi.+ 16  Nítorí pé ìwọ ni Baba wa;+ bí Ábúráhámù alára kò tilẹ̀ mọ̀ wá, tí Ísírẹ́lì alára kò dá wa mọ̀, ìwọ, Jèhófà, ni Baba wa. Olùtúnnirà wa láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn ni orúkọ rẹ.+ 17  Jèhófà, èé ṣe tí o fi ń mú kí a máa rìn gbéregbère kúrò ní àwọn ọ̀nà rẹ? Èé ṣe tí o fi sé ọkàn-àyà wa le sí bíbẹ̀rù rẹ?+ Padà wá nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ẹ̀yà ohun ìní àjogúnbá rẹ.+ 18  Nítorí pé ìgbà díẹ̀ ni àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ+ fi ní ohun ìní. Àwọn elénìní wa ti fi ẹsẹ̀ tẹ ibùjọsìn rẹ mọ́lẹ̀.+ 19  Tipẹ́tipẹ́ ni a ti dà bí àwọn tí ìwọ kò ṣàkóso lé lórí, bí àwọn tí a kò fi orúkọ rẹ pè.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé