Aísáyà 6:1-13

6  Bí ó ti wù kí ó rí, ní ọdún tí Ùsáyà Ọba kú,+ mo wá rí Jèhófà,+ tí ó jókòó lórí ìtẹ́+ tí ó ga fíofío, tí a sì gbé sókè, ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ rẹ̀ sì kún inú tẹ́ńpìlì.+  Àwọn séráfù dúró lókè rẹ̀.+ Ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ìyẹ́ apá mẹ́fà. Méjì ni ó fi ń bo ojú rẹ̀,+ méjì sì ni ó fi ń bo ẹsẹ̀ rẹ̀, méjì sì ni ó fi ń fò káàkiri.  Ẹni tibí sì ń ké sí ẹni tọ̀hún pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.+ Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ gbogbo ilẹ̀ ayé ni ògo rẹ̀.”  Àwọn ìkọ́ olóyìípo+ tí ń bẹ ní ibi àbáwọlé sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ nítorí ohùn ẹni tí ń pè, ilé náà sì kún fún èéfín+ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀.  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Mo gbé! Nítorí, kí a sáà kùkù sọ pé a ti pa mí lẹ́nu mọ́, nítorí pé ọkùnrin aláìmọ́ ní ètè ni mí,+ àárín àwọn ènìyàn aláìmọ́ ní ètè sì ni mo ń gbé;+ nítorí pé ojú mi ti rí Ọba, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, tìkára rẹ̀!”+  Látàrí ìyẹn, ọ̀kan lára àwọn séráfù náà fò wá sọ́dọ̀ mi, ẹyín iná pípọ́n yòò+ sì wà ní ọwọ́ rẹ̀, èyí tí ó fi ẹ̀múná mú láti orí pẹpẹ+ wá.  Ó sì fi kan ẹnu mi,+ ó sì wí pé: “Wò ó! Èyí ti kan ètè rẹ, ìṣìnà rẹ sì ti kúrò, ẹ̀ṣẹ̀ rẹ pàápàá ni a sì ti ṣètùtù fún.”+  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ohùn Jèhófà tí ó wí pé: “Ta ni èmi yóò rán, ta sì ni yóò lọ fún wa?”+ Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Èmi nìyí! Rán mi.”+  Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Lọ, kí o sì sọ fún àwọn ènìyàn yìí pé, ‘Ẹ gbọ́ ní àgbọ́túngbọ́, ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe lóye; kí ẹ sì rí ní àrítúnrí, ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe ní ìmọ̀ kankan.’+ 10  Mú kí ọkàn-àyà àwọn ènìyàn yìí sébọ́,+ sì mú kí etí wọn gan-an gíràn-án,+ sì lẹ ojú wọn gan-an pọ̀, kí wọ́n má bàa fi ojú wọn rí, kí wọ́n má sì fi etí wọn gbọ́, kí ọkàn-àyà wọn má sì lóye, kí wọ́n má sì yí padà ní tòótọ́, kí wọ́n má sì rí ìmúláradá gbà fún ara wọn.”+ 11  Látàrí èyí, mo sọ pé: “Yóò ti pẹ́ tó, Jèhófà?”+ Nígbà náà ni ó sọ pé: “Títí àwọn ìlú ńlá náà yóò fi fọ́ bàjẹ́ ní tòótọ́, tí wọn yóò fi wà láìsí olùgbé, tí àwọn ilé yóò fi wà láìsí ará ayé, tí a ó sì run ilẹ̀ pàápàá di ahoro;+ 12  tí Jèhófà yóò sì ṣí àwọn ará ayé lọ sí ọ̀nà jíjìnréré ní ti gidi, tí ipò ìkọ̀tì náà yóò sì wá di gbígbòòrò gidigidi ní àárín ilẹ̀ náà.+ 13  Ìdá mẹ́wàá yóò ṣì wà nínú rẹ̀ síbẹ̀,+ yóò sì tún di ohun kan fún sísun kanlẹ̀, bí igi ńlá àti bí igi ràgàjì, tí ó jẹ́ pé, nígbà tí a gé wọn lulẹ̀,+ wọ́n ní kùkùté;+ irúgbìn mímọ́ ni yóò jẹ́ kùkùté rẹ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé