Aísáyà 50:1-11

50  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ibo wá ni ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀+ ìyá yín wà, ẹni tí mo rán lọ?+ Tàbí kẹ̀, èwo lára àwọn tí mo jẹ ní gbèsè ni mo tà yín fún?+ Wò ó! Nítorí àwọn ìṣìnà+ tiyín ni a fi tà yín, nítorí àwọn ìrélànàkọjá tiyín ni a sì fi rán ìyá yín lọ.+  Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé, nígbà tí mo wọlé wá, kò sí ẹnì kankan?+ Nígbà tí mo pè, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó dáhùn?+ Ṣé ọwọ́ mi ti wá kúrú tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí kò fi lè túnni rà padà ni,+ tàbí kẹ̀, ṣé kò sí agbára nínú mi láti dáni nídè ni? Wò ó! Ìbáwí mímúná+ mi ni mo fi mú òkun gbẹ táútáú;+ mo sọ àwọn odò di aginjù.+ Ẹja wọn ṣíyàn-án nítorí pé kò sí omi, wọ́n sì kú nítorí òùngbẹ.+  Mo fi òkùnkùn ṣíṣú bo ọ̀run,+ mo sì fi aṣọ àpò ìdọ̀họ ṣe ìbòjú wọn.”+  Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀ ti fún mi ní ahọ́n àwọn tí a kọ́,+ kí n lè mọ bí a ti ń fi ọ̀rọ̀ dá ẹni tí ó ti rẹ̀ lóhùn.+ Ó ń jí mi ní òròòwúrọ̀; ó ń jí etí mi láti gbọ́, bí àwọn tí a kọ́.+  Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀ ti ṣí etí mi, èmi, ní tèmi, kò sì ya ọlọ̀tẹ̀.+ Èmi kò yí padà sí òdì-kejì.+  Ẹ̀yìn mi ni mo fi fún àwọn akọluni, mo sì fi ẹ̀rẹ̀kẹ́+ mi fún àwọn tí ń fa irun tu. Ojú mi ni èmi kò fi pa mọ́ fún àwọn ohun tí ń tẹ́ni lógo àti itọ́.+  Ṣùgbọn Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀ yóò ràn mí lọ́wọ́.+ Ìdí nìyẹn tí a kì yóò fi tẹ́ mi lógo. Ìdí nìyẹn tí mo fi gbé ojú mi ró bí akọ òkúta, mo sì mọ̀ pé ojú kì yóò tì mí.+  Ẹni tí ń polongo mi ní olódodo ń bẹ nítòsí.+ Ta ni ó lè bá mi fà á? Jẹ́ kí a jọ dìde dúró.+ Ta ni ó dojú ìjà kọ mí nínú ọ̀ràn ìdájọ́?+ Kí ó sún mọ́ mi.+  Wò ó! Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀ yóò ràn mí lọ́wọ́. Ta ni ó lè pè mí ní ẹni burúkú?+ Wò ó! Gbogbo wọn, bí ẹ̀wù, yóò gbó.+ Òólá lásán-làsàn ni yóò jẹ wọ́n tán.+ 10  Ta ní ń bẹ̀rù+ Jèhófà lára yín, tí ń fetí sí ohùn ìránṣẹ́ rẹ̀,+ tí ń rìn nínú òkùnkùn ìgbà gbogbo+ àti ẹni tí ìtànyòò kò sí fún? Kí ó gbẹ́kẹ̀ lé orúkọ Jèhófà,+ kí ó sì gbé ara rẹ̀ lé Ọlọ́run rẹ̀.+ 11  “Wò ó! Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ń mú kí iná ràn, tí ẹ ń mú kí ìtapàrà mọ́lẹ̀ kedere, ẹ máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ iná yín, àti láàárín ìtapàrà tí ẹ ti mú kí ó jó. Dájúdájú, láti ọwọ́ mi ni ẹ ó ti wá ní èyí: Nínú ìroragógó ni ẹ ó dùbúlẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé