Aísáyà 43:1-28

43  Wàyí o, èyí ni ohun tí Jèhófà wí, Ẹlẹ́dàá rẹ,+ ìwọ Jékọ́bù, àti Aṣẹ̀dá rẹ,+ ìwọ Ísírẹ́lì: “Má fòyà, nítorí pé mo ti tún ọ rà.+ Mo ti fi orúkọ rẹ pè ọ́.+ Tèmi ni ọ́.+  Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o gba inú omi kọjá,+ èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ dájúdájú;+ bí o bá sì gba inú àwọn odò kọjá, wọn kì yóò kún bò ọ́.+ Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o rin inú iná kọjá, kì yóò jó ọ, bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ iná pàápàá kì yóò wì ọ́.+  Nítorí pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì tí í ṣe Olùgbàlà rẹ.+ Mo ti fi Íjíbítì fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà rẹ,+ Etiópíà+ àti Sébà dípò rẹ.  Nítorí òtítọ́ náà pé ìwọ ṣe iyebíye ní ojú mi,+ a kà ọ́ sí ẹni tí ó ní ọlá, èmi fúnra mi sì nífẹ̀ẹ́ rẹ.+ Èmi yóò sì fi àwọn ènìyàn fúnni dípò rẹ, àti àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè dípò ọkàn rẹ.+  “Má fòyà, nítorí pé mo wà pẹ̀lú rẹ.+ Láti yíyọ oòrùn ni èmi yóò ti mú irú-ọmọ rẹ wá, láti wíwọ̀-oòrùn ni èmi yóò sì ti kó ọ jọpọ̀.+  Èmi yóò wí fún àríwá+ pé, ‘Dá sílẹ̀!’ àti fún gúúsù pé, ‘Má ṣe dá dúró. Mú àwọn ọmọkùnrin mi wá láti ibi jíjìnnàréré, àti àwọn ọmọbìnrin mi láti ìkángun ilẹ̀ ayé,+  olúkúlùkù ẹni tí a ń fi orúkọ mi pè,+ tí mo sì dá fún ògo mi,+ tí mo ṣẹ̀dá, bẹ́ẹ̀ ni, tí mo ṣe.’+  “Mú àwọn ènìyàn tí ó fọ́jú wá, bí ojú tilẹ̀ ń bẹ, àti àwọn adití, bí wọ́n tilẹ̀ ní etí.+  Kí a kó orílẹ̀-èdè gbogbo jọpọ̀ sí ibì kan, kí àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè sì kóra jọpọ̀.+ Ta ní ń bẹ nínú wọn tí ó lè sọ èyí?+ Tàbí kẹ̀, wọ́n ha lè mú kí a gbọ́ àní àwọn ohun àkọ́kọ́?+ Kí wọ́n mú àwọn ẹlẹ́rìí wọn jáde wá,+ kí a lè polongo wọn ní olódodo, tàbí kí wọ́n gbọ́, kí wọ́n sì wí pé, ‘Òtítọ́ ni!’”+ 10  “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,”+ ni àsọjáde Jèhófà, “àní ìránṣẹ́ mi tí mo ti yàn,+ kí ẹ lè mọ̀,+ kí ẹ sì ní ìgbàgbọ́ nínú mi,+ àti pé kí ẹ lè lóye pé Ẹnì kan náà ni mí.+ Ṣáájú mi, kò sí Ọlọ́run kankan tí a ṣẹ̀dá,+ àti lẹ́yìn mi, kò sí ìkankan tí ó ṣì wà nìṣó.+ 11  Èmi—èmi ni Jèhófà,+ yàtọ̀ sí mi, kò sí olùgbàlà kankan.”+ 12  “Èmi fúnra mi ti sọ̀rọ̀ jáde, mo sì ti gbà là, mo sì ti mú kí a gbọ́ ọ,+ nígbà tí kò sí àjèjì ọlọ́run kankan láàárín yín.+ Nítorí náà, ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,”+ ni àsọjáde Jèhófà, “èmi sì ni Ọlọ́run.+ 13  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ní gbogbo ìgbà, Ẹnì kan náà ni mí;+ kò sì sí ẹni tí ń dáni nídè kúrò ní ọwọ́ mi.+ Èmi yóò gbé kánkán ṣiṣẹ́,+ ta sì ni ó lè yí i padà?”+ 14  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, Olùtúnnirà yín,+ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì:+ “Nítorí yín, ṣe ni èmi yóò ránṣẹ́ sí Bábílónì, èmi yóò sì mú kí àwọn ọ̀pá ìdábùú ẹ̀wọ̀n kí ó wálẹ̀,+ àti àwọn ará Kálídíà tí ó wà nínú àwọn ọkọ̀ òkun pẹ̀lú kíké tẹ̀dùntẹ̀dùn níhà ọ̀dọ̀ wọn.+ 15  Èmi ni Jèhófà Ẹni Mímọ́ yín,+ Ẹlẹ́dàá Ísírẹ́lì,+ Ọba yín.”+ 16  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, Ẹni tí ń la ọ̀nà gba inú òkun pàápàá kọjá àti òpópónà àní gba inú omi lílágbára kọjá,+ 17  Ẹni tí ń mú kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun àti ẹṣin jáde wá, ẹgbẹ́ ológun àti àwọn alágbára lẹ́ẹ̀kan náà:+ “Wọn yóò dùbúlẹ̀.+ Wọn kì yóò dìde.+ Ṣe ni a óò fẹ́ wọn pa.+ Gẹ́gẹ́ bí òwú àtùpà tí a fi ọ̀gbọ̀ ṣe ni a óò fẹ́ wọn pa.”+ 18  “Ẹ má ṣe rántí àwọn nǹkan àkọ́kọ́, ẹ má sì yí ìrònú yín padà sí àwọn nǹkan àtijọ́. 19  Wò ó! Èmi yóò ṣe ohun tuntun kan.+ Ìsinsìnyí ni yóò rú yọ. Ẹ ó mọ̀ ọ́n, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?+ Ní ti tòótọ́, èmi yóò la ọ̀nà kan gba inú aginjù,+ gba inú àwọn odò aṣálẹ̀.+ 20  Ẹranko ìgbẹ́ yóò yìn mí lógo,+ àwọn akátá àti ògòǹgò;+ nítorí pé èmi yóò ti pèsè omi ní aginjù, àwọn odò ní aṣálẹ̀,+ láti mú kí àwọn ènìyàn mi,+ àyànfẹ́ mi, kí ó mu, 21  àwọn ènìyàn tí mo ti ṣẹ̀dá fún ara mi, kí wọ́n lè máa ròyìn ìyìn mi lẹ́sẹẹsẹ.+ 22  “Ṣùgbọ́n ìwọ kò pe èmi pàápàá, ìwọ Jékọ́bù,+ nítorí tí agara mi ti dá ọ, ìwọ Ísírẹ́lì.+ 23  Ìwọ kò mú àgùntàn àwọn odindi ọrẹ ẹbọ sísun rẹ wá fún mi, o kò sì fi àwọn ẹbọ rẹ yìn mí lógo.+ Èmi kò ṣe é ní ọ̀ranyàn fún ọ pé kí o fi ẹ̀bùn sìn mí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi oje igi tùràrí dá ọ lágara.+ 24  Ìwọ kò fi owó kankan ra ewéko dídùn onípòròpórò+ wá fún mi; ìwọ kò sì fi ọ̀rá àwọn ẹbọ rẹ rin mí gbingbin.+ Ní ti gidi, ìwọ ti sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún mi láti sìn nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ; o ti fi àwọn ìṣìnà rẹ dá mi lágara.+ 25  “Èmi—èmi ni Ẹni tí ń nu+ àwọn ìrélànàkọjá+ rẹ kúrò nítorí tèmi,+ èmi kì yóò sì rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.+ 26  Rán mi létí; ẹ jẹ́ kí a jọ mú ara wa wọnú ìdájọ́;+ sọ ìròyìn tìrẹ nípa rẹ̀ kí o lè jàre.+ 27  Baba tìrẹ, ẹni àkọ́kọ́, ti ṣẹ̀,+ àwọn agbọ̀rọ̀sọ rẹ sì ti rélànà mi kọjá.+ 28  Nítorí náà, èmi yóò sọ àwọn ọmọ aládé ibi mímọ́ di aláìmọ́, ṣe ni èmi yóò sì fi Jékọ́bù léni lọ́wọ́ bí ọkùnrin tí a yà sọ́tọ̀ fún ìparun, èmi yóò sì fi Ísírẹ́lì lé àwọn ọ̀rọ̀ èébú lọ́wọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé