Aísáyà 40:1-31

40  “Ẹ tu àwọn ènìyàn mi nínú, ẹ tù wọ́n nínú,” ni Ọlọ́run yín wí.+  “Ẹ bá ọkàn-àyà Jerúsálẹ́mù+ sọ̀rọ̀ kí ẹ sì ké pè é pé iṣẹ́ ìsìn ológun rẹ̀ ti pé,+ pé a ti san ìṣìnà rẹ̀ tán pátá.+ Nítorí pé ó ti gba iye tí ó kún rẹ́rẹ́ fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ láti ọwọ́ Jèhófà.”+  Ẹ fetí sílẹ̀! Ẹnì kan ń ké ní aginjù:+ “Ẹ tún ọ̀nà Jèhófà ṣe!+ Ẹ mú kí òpópó fún Ọlọ́run wa, èyí tí ó la pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ kọjá, jẹ́ títọ́.+  Gbogbo àfonífojì ni kí a gbé sókè,+ gbogbo òkè ńlá àti òkè kéékèèké sì ni kí a sọ di rírẹlẹ̀.+ Ilẹ̀ págunpàgun sì gbọ́dọ̀ di ilẹ̀ títẹ́jú pẹrẹsẹ, ilẹ̀ kángunkàngun sì gbọ́dọ̀ di pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì.+  Dájúdájú, a ó sì ṣí ògo Jèhófà payá,+ gbogbo ẹran ara yóò sì rí i pa pọ̀,+ nítorí pé ẹnu Jèhófà gan-an ni ó sọ ọ́.”+  Fetí sílẹ̀! Ẹnì kan ń sọ pé: “Ké jáde!”+ Ẹnì kan sì sọ pé: “Kí ni kí n ké jáde?” “Gbogbo ẹran ara jẹ́ koríko tútù, gbogbo inú rere wọn onífẹ̀ẹ́ sì dà bí ìtànná pápá.+  Koríko tútù ti gbẹ dànù, ìtànná ti rọ,+ nítorí pé ẹ̀mí Jèhófà gan-an ti fẹ́ lù ú.+ Dájúdájú, koríko tútù ni àwọn ènìyàn.+  Koríko tútù ti gbẹ dànù, ìtànná ti rọ;+ ṣùgbọ́n ní ti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa, yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”+  Bá ọ̀nà rẹ gòkè lọ, àní sórí òkè ńlá gíga,+ ìwọ obìnrin tí ń mú ìhìn rere wá fún Síónì.+ Gbé ohùn rẹ sókè, àní tagbára-tagbára, ìwọ obìnrin tí ń mú ìhìn rere wá fún Jerúsálẹ́mù.+ Gbé e sókè. Má fòyà.+ Sọ fún àwọn ìlú ńlá Júdà pé: “Ọlọ́run yín rèé.”+ 10  Wò ó! Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀ yóò wá, àní gẹ́gẹ́ bí alágbára, apá rẹ̀ yóò sì máa ṣàkóso fún un.+ Wò ó! Ẹ̀san rẹ̀ ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀,+ owó ọ̀yà tí ó ń san sì ń bẹ níwájú rẹ̀.+ 11  Bí olùṣọ́ àgùntàn ni yóò ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran ọ̀sìn rẹ̀.+ Apá rẹ̀ ni yóò fi kó àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn jọpọ̀;+ oókan àyà rẹ̀ sì ni yóò gbé wọn sí.+ Àwọn tí ń fọ́mọ lọ́mú ni yóò máa rọra dà.+ 12  Ta ni ó ti díwọ̀n omi nínú ìtẹkòtò ọwọ́ rẹ̀ lásán,+ tí ó sì ti fi ìbú àtẹ́lẹwọ́+ lásán wọn ọ̀run pàápàá, tí ó sì ti kó ekuru ilẹ̀ ayé+ jọ sínú òṣùwọ̀n, tàbí tí ó fi atọ́ka-ìwọ̀n wọn àwọn òkè ńláńlá, tí ó sì wọn àwọn òkè kéékèèké nínú òṣùwọ̀n? 13  Ta ni ó ti wọn ẹ̀mí Jèhófà, ta sì ni, gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin tí ń gbà á nímọ̀ràn, tí ó lè mú kí ó mọ ohunkóhun?+ 14  Ta ni òun bá fikùn lukùn, tí ẹnì kan fi lè mú kí ó lóye, tàbí kẹ̀, ta ni ó ń kọ́ ọ ní ipa ọ̀nà ìdájọ́ òdodo, tàbí tí ó ń kọ́ ọ ní ìmọ̀,+ tàbí tí ó ń mú kí ó mọ àní ọ̀nà òye gidi?+ 15  Wò ó! Àwọn orílẹ̀-èdè dà bí ẹ̀kán omi kan láti inú korobá; bí ekuru fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ lórí òṣùwọ̀n sì ni a kà wọ́n sí.+ Wò ó! Ó ń gbé àwọn erékùṣù+ pàápàá sókè gẹ́gẹ́ bí ekuru lẹ́búlẹ́bú lásán. 16  Lẹ́bánónì pàápàá kò tó fún mímú kí iná máa jó, àwọn ẹranko ìgbẹ́+ rẹ̀ kò sì tó fún ọrẹ ẹbọ sísun.+ 17  Gbogbo orílẹ̀-èdè dà bí ohun tí kò sí ní iwájú rẹ̀;+ bí aláìjámọ́ nǹkan kan àti òtúbáńtẹ́ ni ó kà wọ́n sí.+ 18  Ta sì ni ẹ lè fi Ọlọ́run wé,+ ohun ìrí wo sì ni ẹ lè mú kí ó bá a dọ́gba?+ 19  Oníṣẹ́ ọnà mọ ère dídà lásán-làsàn,+ oníṣẹ́ irin sì fi wúrà bò ó,+ ó sì ń rọ ẹ̀wọ̀n fàdákà.+ 20  Igi kan gẹ́gẹ́ bí ọrẹ, igi kan tí kò jẹrà, ni ó yàn.+ Oníṣẹ́ ọnà tí ó jáfáfá ni ó wá kàn fún ara rẹ̀, láti pèsè ère gbígbẹ́+ tí a kò lè mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.+ 21  Ṣé ẹ kò mọ̀ ni? Ṣé ẹ kò gbọ́ ni? Ṣé a kò sọ fún yín láti ìbẹ̀rẹ̀pàá ni? Ṣé ẹ kò lo òye láti ìgbà ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé ni?+ 22  Ẹnì kan wà tí ń gbé orí òbìrìkìtì ilẹ̀ ayé,+ tí àwọn olùgbé inú rẹ̀ dà bí tata, Ẹni tí ó na ọ̀run gẹ́gẹ́ bí aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ oníhò wínníwínní, tí ó tẹ́ ẹ bí àgọ́ láti máa gbé inú rẹ̀,+ 23  Ẹni tí ń sọ àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga di aláìjámọ́ nǹkan kan, tí ó ti sọ àwọn onídàájọ́ ilẹ̀ ayé di òtúbáńtẹ́ lásán-làsàn.+ 24  A kò tíì gbìn wọ́n rí; a kò tíì fúnrúgbìn wọn rí; kùkùté wọn kò tíì ta gbòǹgbò rí ní ilẹ̀.+ Kí ènìyàn kàn fẹ́ atẹ́gùn lù wọ́n ni, wọn a sì gbẹ dànù;+ ìjì ẹlẹ́fùúùfù yóò sì gbé wọn lọ bí àgékù pòròpórò.+ 25  “Ṣùgbọ́n ta ni ẹ lè fi mí wé, tí a ó fi mú mi bá a dọ́gba?” ni Ẹni Mímọ́+ wí. 26  “Ẹ gbé ojú yín sókè réré, kí ẹ sì wò. Ta ni ó dá nǹkan wọ̀nyí?+ Ẹni tí ń mú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn jáde wá ni, àní ní iye-iye, àwọn tí ó jẹ́ pé àní orúkọ ni ó fi ń pe gbogbo wọn.+ Nítorí ọ̀pọ̀ yanturu okun rẹ̀ alágbára gíga,+ àti ní ti pé òun ní okun inú nínú agbára, kò sí ìkankan nínú wọn tí ó dàwáàrí. 27  “Kí ni ìdí tí o fi ń sọ, ìwọ Jékọ́bù, tí o sì fi ń sọ̀rọ̀ jáde, ìwọ Ísírẹ́lì, pé, ‘Ọ̀nà mi pa mọ́ kúrò lójú Jèhófà,+ àti pé ìdájọ́ òdodo sí mi ń yọ́ bọ́rọ́ mọ́ Ọlọ́run mi tìkára rẹ̀ lọ́wọ́’?+ 28  Ṣé o kò tíì mọ̀ ni tàbí ṣé o kò tíì gbọ́ ni?+ Jèhófà, Ẹlẹ́dàá àwọn ìkángun ilẹ̀ ayé, jẹ́ Ọlọ́run fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ Àárẹ̀ kì í mú un, bẹ́ẹ̀ ni agara kì í dá a.+ Kò sí àwárí òye rẹ̀.+ 29  Ó ń fi agbára fún ẹni tí ó ti rẹ̀;+ ó sì ń mú kí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá pọ̀ gidigidi fún ẹni tí kò ní okun alágbára gíga.+ 30  Àárẹ̀ yóò mú àwọn ọmọdékùnrin, agara yóò sì dá wọn, àwọn ọ̀dọ́kùnrin pàápàá yóò sì kọsẹ̀ dájúdájú, 31  ṣùgbọ́n àwọn tí ó ní ìrètí+ nínú Jèhófà yóò jèrè agbára padà.+ Wọn yóò fi ìyẹ́ apá ròkè bí idì.+ Wọn yóò sáré, agara kì yóò sì dá wọn; wọn yóò rìn, àárẹ̀ kì yóò sì mú wọn.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé