Aísáyà 38:1-22
38 Ní ọjọ́ wọnnì, Hesekáyà ṣàìsàn dé ojú ikú.+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Aísáyà+ ọmọkùnrin Émọ́sì, tí í ṣe wòlíì, wọlé tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Pa àṣẹ fún agbo ilé rẹ,+ nítorí pé ìwọ fúnra rẹ yóò kú ní tòótọ́, ìwọ kì yóò sì yè.’”+
2 Látàrí ìyẹn, Hesekáyà yí ojú sí ògiri,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà sí Jèhófà,+
3 ó sì wí pé: “Mo fi taratara bẹ̀ ọ́, Jèhófà, jọ̀wọ́, rántí+ bí mo ṣe rìn+ níwájú rẹ nínú òtítọ́+ àti pẹ̀lú ọkàn-àyà pípé pérépéré,+ ohun tí ó dára ní ojú rẹ sì ni mo ṣe.” Hesekáyà sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀.+
4 Ọ̀rọ̀+ Jèhófà sì tọ Aísáyà wá wàyí, pé:
5 “Lọ, kí o sì sọ fún Hesekáyà pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Dáfídì baba ńlá rẹ+ wí: “Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ.+ Mo ti rí omijé rẹ.+ Kíyè sí i, èmi yóò fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kún ọjọ́ rẹ;+
6 èmi yóò sì dá ìwọ àti ìlú ńlá yìí nídè kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ ọba Ásíríà, èmi yóò sì gbèjà ìlú ńlá yìí dájúdájú.+
7 Èyí ni àmì fún ọ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, pé Jèhófà yóò mú ọ̀rọ̀ yìí tí ó ti sọ ṣẹ:+
8 Kíyè sí i, èmi yóò mú kí òjìji tí ń bẹ lára àwọn ìdásẹ̀lé ara àtẹ̀gùn, tí oòrùn+ ti mú kí ó sọ̀ kalẹ̀ sára àtẹ̀gùn Áhásì, kí ó tọsẹ̀ padà sẹ́yìn ní ìdásẹ̀lé mẹ́wàá ara àtẹ̀gùn.”’”+ Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, oòrùn padà sẹ́yìn ní ìdásẹ̀lé mẹ́wàá ara àtẹ̀gùn lórí àtẹ̀gùn tí ó ti sọ̀ kalẹ̀ lé.+
9 Ìwé Hesekáyà ọba Júdà, nígbà tí ó ṣàìsàn+ tí ó sì sàn nínú àìsàn rẹ̀.+
10 Èmi fúnra mi wí pé: “Àárín àwọn ọjọ́ mi ni èmi yóò lọ sí àwọn ẹnubodè+ Ṣìọ́ọ̀lù.
A ó fi ìyókù+ àwọn ọdún mi dù mí.”
11 Mo wí pé: “Èmi kì yóò rí Jáà, àní Jáà, ní ilẹ̀ àwọn alààyè.+
Èmi kì yóò wo aráyé mọ́—pẹ̀lú àwọn olùgbé ilẹ̀ ìdákẹ́.
12 A ti fa ibi gbígbé mi tu,+ a sì ti mú un kúrò lọ́dọ̀ mi bí àgọ́ àwọn olùṣọ́ àgùntàn.
Mo ti ká ìwàláàyè mi jọ gẹ́gẹ́ bí olófì;
Ẹnì kan tẹ̀ síwájú láti ké mi kúrò+ lára àwọn fọ́nrán òwú títa gan-an.
Láti ojúmọmọ títí di òru, o ń fi mí léni lọ́wọ́.+
13 Mo ti tu ara mi lára pẹ̀sẹ̀ títí di òwúrọ̀.+
Bí kìnnìún, bẹ́ẹ̀ ni ó ń fọ́ gbogbo egungun mi;+
Láti ojúmọmọ títí di òru, o ń fi mí léni lọ́wọ́.+
14 Bí ẹyẹ olófèéèré, ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ́, bẹ́ẹ̀ ni mo ń ké ṣíoṣío;+
Mo ń ké kúùkúù bí àdàbà.+
Ojú mi ti wo ibi gíga tí-tí-tí:+
‘Jèhófà, mo wà lábẹ́ ìnilára. Dúró tì mí.’+
15 Kí ni kí n sọ, kí sì ni òun yóò wí fún mi ní ti tòótọ́?+
Òun fúnra rẹ̀ ti gbé ìgbésẹ̀.+
Mo ń rìn tìrònú-tìrònú ní gbogbo ọdún mi nínú ìkorò ọkàn mi.+
16 ‘Jèhófà, ní tìtorí èyíinì, wọ́n ń wà láàyè nìṣó; àti ní ti gbogbo ènìyàn, ipasẹ̀ wọn ni ìwàláàyè ẹ̀mí mi.+
Ìwọ yóò sì mú mi padà sípò ìlera, ìwọ yóò sì pa mí mọ́ láàyè dájúdájú.+
17 Wò ó! Dípò àlàáfíà mo ní ohun kíkorò, bẹ́ẹ̀ ni, kíkorò;+
Ìwọ fúnra rẹ sì ti fà mọ́ ọkàn mi, o sì pa á mọ́ kúrò nínú kòtò ìfọ́kélekèle.+
Nítorí pé o ti ju gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ẹ̀yìn rẹ.+
18 Nítorí pé kì í ṣe Ṣìọ́ọ̀lù ni ó lè gbé ọ lárugẹ;+ ikú pàápàá kò lè yìn ọ́.+
Àwọn tí ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú kòtò kò lè wo òótọ́ rẹ tìrètí-tìrètí.+
19 Àlààyè, alààyè, òun ni ó lè gbé ọ lárugẹ,+
Gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti lè ṣe ní òní yìí.+
Baba fúnra rẹ̀ lè fún àwọn ọmọ rẹ̀ ní ìmọ̀+ nípa òótọ́ rẹ.
20 Jèhófà, dáwọ́ lé gbígbà mí là,+ a ó sì máa kọ àwọn àṣàyàn orin mi tí a fi ohun èlò olókùn tín-ín-rín kọ+
Ní gbogbo ọjọ́ ayé wa ní ilé Jèhófà.’”+
21 Aísáyà sì tẹ̀ síwájú láti sọ pé: “Kí wọ́n mú ìṣù èso ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ, kí wọ́n sì fi pa ojú oówo náà,+ kí ó lè sàn.”+
22 Láàárín àkókò náà, Hesekáyà sọ pé: “Kí ni àmì pé èmi yóò gòkè lọ sí ilé Jèhófà?”+

