Aísáyà 3:1-26

3  Nítorí pé, wò ó! Olúwa tòótọ́,+ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, yóò mú ìtìlẹyìn àti amóhundúró kúrò ní Jerúsálẹ́mù+ àti Júdà, gbogbo ìtìlẹyìn oúnjẹ àti gbogbo ìtìlẹyìn omi,+  alágbára ńlá àti jagunjagun, onídàájọ́ àti wòlíì,+ woṣẹ́woṣẹ́ àti àgbàlagbà,+  olórí àádọ́ta+ àti ẹni tí a bọ̀wọ̀ fún gidigidi àti agbani-nímọ̀ràn àti ògbógi nínú idán pípa, àti ọ̀jáfáfá atujú.+  Dájúdájú, èmi yóò fi àwọn ọmọdékùnrin ṣe ọmọ aládé wọn, àní agbára tí kò dúró gbẹ́jọ́ sì ni yóò máa ṣàkóso wọn.+  Àwọn ènìyàn náà yóò sì máa fi ìkà gbo ẹnì kìíní-kejì mọ́lẹ̀ ní ti tòótọ́, àní olúkúlùkù yóò máa gbo ọmọnìkejì rẹ̀ mọ́lẹ̀.+ Wọn yóò fi ipá rọ́ lura, ọmọdékùnrin lu àgbà ọkùnrin,+ àti ẹni tí a kò fi bẹ́ẹ̀ kà sí lu ẹni tí a bọlá fún.+  Nítorí olúkúlùkù yóò gbá arákùnrin rẹ̀ mú nínú ilé baba rẹ̀, yóò sọ pé: “Ìwọ ní aṣọ àlàbora. Apàṣẹwàá+ ni ó yẹ kí o jẹ́ fún wa, kí àgbájọ ènìyàn tí a bì ṣubú yìí sì wà lábẹ́ ọwọ́ rẹ.”  Òun yóò gbé ohùn rẹ̀ sókè ní ọjọ́ yẹn, pé: “Èmi kì yóò di olùwẹ ọgbẹ́; kò sì sí oúnjẹ tàbí aṣọ àlàbora nínú ilé mi. Kí ẹ má fi mí ṣe apàṣẹwàá lé àwọn ènìyàn lórí.”  Nítorí Jerúsálẹ́mù ti kọsẹ̀, Júdà alára sì ti ṣubú,+ nítorí pé ahọ́n wọn àti ìbánilò wọn wà ní ìlòdìsí Jèhófà,+ ní híhùwà ọ̀tẹ̀ ní ojú ògo rẹ̀.+  Àní ìrísí ojú wọn ń jẹ́rìí lòdì sí wọn ní ti gidi,+ ó sì ń sọ nípa ẹ̀ṣẹ̀ wọn,+ bí ti Sódómù. Kò fi í pa mọ́. Ègbé ni fún ọkàn wọn! Nítorí pé wọ́n ti pín ìyọnu àjálù fún ara wọn.+ 10  Ẹ wí pé yóò dára fún olódodo,+ nítorí pé wọn yóò jẹ èso ìbánilò wọn.+ 11  Ègbé ni fún ẹni burúkú!—Ìyọnu àjálù; nítorí pé ìlòsíni tí ọwọ́ òun fúnra rẹ̀ fi báni lò ni a ó fi bá a lò!+ 12  Ní ti àwọn ènìyàn mi, àwọn apínṣẹ́fúnni rẹ̀ ń báni lò lọ́nà mímúná, àní obìnrin sì ni ó ń ṣàkóso lé e lórí+ ní ti tòótọ́. Ẹ̀yin ènìyàn mi, àwọn tí ń ṣamọ̀nà rẹ lọ ń mú kí o rìn gbéregbère,+ wọ́n sì ti da ipa àwọn ọ̀nà rẹ rú.+ 13  Jèhófà dìde dúró láti báni jà, ó sì dìde láti ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn.+ 14  Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò wọnú ìdájọ́ pẹ̀lú àwọn àgbàlagbà nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ àti àwọn ọmọ aládé rẹ̀.+ “Ẹ̀yin fúnra yín sì ti sun ọgbà àjàrà kanlẹ̀. Ohun tí a fi ìjanilólè gbà lọ́wọ́ ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ wà nínú ilé yín.+ 15  Kí ni ẹ ní lọ́kàn, ní ti pé ẹ tẹ àwọn ènìyàn mi rẹ́, àti pé ojú àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ ni ẹ fi ń gbolẹ̀?”+ ni àsọjáde Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun. 16  Jèhófà sì wí pé: “Nítorí ìdí náà pé àwọn ọmọbìnrin Síónì ti di onírera, tí wọ́n sì ń rìn pẹ̀lú ọ̀fun nínà síwájú, tí wọ́n sì ń sejú, wọ́n ń rin ìrìn oge, wọ́n sì ń fi ẹsẹ̀ wọn ṣe ìró dídún woroworo,+ 17  Jèhófà pẹ̀lú yóò mú kí àtàrí àwọn ọmọbìnrin Síónì ní ẹ̀yi+ ní tòótọ́, Jèhófà yóò sì tú iwájú orí wọn gan-an sí borokoto.+ 18  Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà yóò mú ẹwà àwọn ẹ̀gbà ọrùn ẹsẹ̀ kúrò àti ọ̀já ìwérí àti àwọn ohun ọ̀ṣọ́ onírìísí òṣùpá,+ 19  àwọn yẹtí jọlọjọlọ àti júfù àti ìbòjú,+ 20  àwọn ìwérí àti ẹ̀gbà ẹsẹ̀ àti ọ̀já ìgbàyà+ àti ‘àwọn ilé ọkàn’ àti àwọn karawun àfiṣọ̀ṣọ́ tí ń kùn bí oyin,+ 21  òrùka ọwọ́ àti òrùka imú,+ 22  aṣọ ìgúnwà àti àwọ̀lékè àti aṣọ ìlékè àti àpò, 23  àti dígí ọwọ́+ àti ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti láwàní+ àti ìbòjú ńlá.+ 24  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, dípò òróró básámù,+ kìkì òórùn dídìkàsì ni yóò wà; àti dípò ìgbànú, ìjàrá ni yóò wà; àti dípò ìṣètò irun lọ́nà rèǹtèrente, orí pípá+ ni yóò wà; àti dípò ẹ̀wù olówó ńlá, sísán aṣọ àpò ìdọ̀họ+ ni yóò wà; àpá àmì+ dípò ẹwà ojú. 25  Àwọn ọkùnrin rẹ yóò ti ipa idà ṣubú, agbára ńlá rẹ yóò sì ti ipa ogun ṣubú.+ 26  Ó dájú pé àwọn ẹnu ọ̀nà rẹ̀ yóò ṣọ̀fọ̀,+ wọn yóò sì kárísọ, ṣe ni a ó sì gbá a dànù. Òun yóò jókòó sí ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé