Aísáyà 28:1-29

28  Ègbé ni fún adé ọlọ́lá-ògo ti àwọn ọ̀mùtípara Éfúráímù,+ àti ìtànná rírọ ti ìṣelóge ẹwà rẹ̀ tí ó wà ní orí àfonífojì ọlọ́ràá ti àwọn tí wáìnì ti kápá wọn!  Wò ó! Jèhófà ní ẹnì kan tí ó lágbára tí ó sì ní okun inú.+ Bí ìjì yìnyín tí ń sán ààrá,+ ìjì aṣèparun, bí ìjì omi alágbára, ti ìkún omi,+ tí ń sán ààrá, ṣe ni òun yóò fi ipá ṣe jíjù sísàlẹ̀ sórí ilẹ̀.  Ẹsẹ̀ ni a ó fi tẹ àwọn adé ọlọ́lá-ògo ti àwọn ọ̀mùtípara Éfúráímù mọ́lẹ̀.+  Òdòdó+ rírọ ti ìṣelóge ẹwà rẹ̀ tí ó wà ní orí àfonífojì ọlọ́ràá yóò sì dà bí ọ̀pọ̀tọ́ àkọ́pọ́n+ ṣáájú ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, èyí tí ó jẹ́ pé, nígbà tí ẹni tí ń wòran rí i, nígbà tí ó ṣì wà ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, òun a gbé e mì gbìnrín.  Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò dà bí adé ìṣelóge+ àti bí òdòdó ẹ̀yẹ ti ẹwà+ fún àwọn tí ó ṣẹ́ kù+ lára àwọn ènìyàn rẹ̀,  àti bí ẹ̀mí ìdájọ́ òdodo fún ẹni tí ó jókòó nínú ìdájọ́,+ àti bí agbára ńlá fún àwọn tí ń lé ìjà ogun padà ní ẹnubodè.+  Àti àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú—nítorí wáìnì, wọ́n ti ṣáko lọ àti nítorí ọtí tí ń pani, wọ́n ti rìn gbéregbère. Àlùfáà àti wòlíì+—wọ́n ti ṣáko lọ nítorí ọtí tí ń pani, ìdàrúdàpọ̀ ti bá wọn nítorí wáìnì, wọ́n ti rìn gbéregbère+ nítorí ọtí tí ń pani; wọ́n ti ṣáko lọ nínú ìríran wọn, wọ́n ti ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ ní ti ìpinnu.  Nítorí pé gbogbo àwọn tábìlì pàápàá ti kún fún èébì+ ẹlẹ́gbin—kò sí ibi tí kò sí.  Ta ni ènìyàn yóò fún ní ìtọ́ni nínú ìmọ̀,+ ta sì ni ènìyàn yóò mú lóye ohun tí a ti gbọ́?+ Àwọn tí a já lẹ́nu wàrà ni bí, àwọn tí a gbà lẹ́nu ọmú ni bí?+ 10  Nítorí pé ó jẹ́ “àṣẹ lé àṣẹ, àṣẹ lé àṣẹ, okùn ìdiwọ̀n lé okùn ìdiwọ̀n, okùn ìdiwọ̀n lé okùn ìdiwọ̀n, díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn-ún.”+ 11  Nítorí pé nípasẹ̀ àwọn tí ètè+ wọn ń kólòlò àti nípasẹ̀ ahọ́n ọ̀tọ̀+ ni òun yóò fi bá àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀,+ 12  àwọn tí ó ti sọ fún pé: “Èyí ni ibi ìsinmi. Ẹ fún ẹni tí ó ti rẹ̀ ní ìsinmi. Èyí sì ni ibi ìdẹ̀rùn,” ṣùgbọ́n tí wọn kò fẹ́ gbọ́.+ 13  Lójú wọn, ṣe ni ọ̀rọ̀ Jèhófà yóò sì di “àṣẹ lé àṣẹ, àṣẹ lé àṣẹ, okùn ìdiwọ̀n lé okùn ìdiwọ̀n, okùn ìdiwọ̀n lé okùn ìdiwọ̀n,+ díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn-ún,” kí wọ́n bàa lè lọ, kí wọ́n sì ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ sẹ́yìn dájúdájú, kí a sì ṣẹ́ wọn, kí a sì dẹkùn sílẹ̀ dè wọ́n, kí a sì mú wọn ní ti tòótọ́.+ 14  Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin afọ́nnu, ẹ̀yin olùṣàkóso+ àwọn ènìyàn yìí tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù: 15  Nítorí tí ẹ sọ pé: “Àwa ti bá Ikú dá májẹ̀mú;+ a sì ti fìdí ìran+ kan múlẹ̀ pẹ̀lú Ṣìọ́ọ̀lù; ìkún omi ayaluni lójijì tí ó kún àkúnwọ́sílẹ̀, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé yóò kọjá, kì yóò dé ọ̀dọ̀ wa, nítorí pé a ti fi irọ́ ṣe ibi ìsádi wa,+ inú èké sì ni a fi ara wa pa mọ́ sí”;+ 16  nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Kíyè sí i, èmi yóò fi òkúta+ kan lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ ní Síónì,+ òkúta tí a ti dán wò,+ igun ilé ṣíṣeyebíye+ ti ìpìlẹ̀ dídájú.+ Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lo ìgbàgbọ́ tí ẹ̀rù jìnnìjìnnì yóò bá.+ 17  Dájúdájú, èmi yóò sì fi ìdájọ́ òdodo ṣe okùn ìdiwọ̀n,+ èmi yóò sì fi òdodo+ ṣe ohun èlò ìmú-nǹkan-tẹ́jú; yìnyín+ yóò sì gbá ibi ìsádi irọ́ lọ,+ àní omi yóò sì kún bo ibi ìlùmọ́ pàápàá.+ 18  Dájúdájú, májẹ̀mú tí ẹ bá Ikú dá ni a ó sì tú ká,+ ìran tiyín yẹn pẹ̀lú Ṣìọ́ọ̀lù kì yóò sì dúró.+ Ìkún omi ayaluni lójijì tí ó kún àkúnwọ́sílẹ̀, nígbà tí ó bá kọjá+—ẹ ó sì di ibi ìtẹ̀mọ́lẹ̀ fún un pẹ̀lú.+ 19  Nígbàkúùgbà tí ó bá ń kọjá, yóò kó yín lọ,+ nítorí pé òròòwúrọ̀ ni yóò máa kọjá, ní ọ̀sán àti ní òru; kì yóò sì jẹ́ ohun mìíràn bí kò ṣe ìdí fún ìwárìrì+ láti mú kí àwọn mìíràn lóye ohun tí wọ́n ti gbọ́.” 20  Nítorí pé àga ìrọ̀gbọ̀kú ti kúrú jù fún nína ara ẹni lé, aṣọ híhun pàápàá sì tẹ́rẹ́ jù nígbà tí ènìyàn bá fi bora. 21  Nítorí pé Jèhófà yóò dìde gẹ́gẹ́ bí ti Òkè Ńlá Pérásímù,+ a ó ru ú sókè gẹ́gẹ́ bí ti pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ tí ó wà nítòsí Gíbéónì,+ kí ó lè ṣe ìṣe rẹ̀—ìṣe rẹ̀ ṣàjèjì—kí ó sì lè ṣe iṣẹ́ rẹ̀—iṣẹ́ rẹ̀ kàmàmà.+ 22  Wàyí o, ẹ má fi ara yín hàn ní afinirẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà,+ kí ọ̀já yín má bàa lágbára, nítorí pé ìparun pátápátá ń bẹ, àní ohun tí a ti ṣe ìpinnu lé lórí, tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa Ọba Aláṣẹ,+ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, fún gbogbo ilẹ̀ náà.+ 23  Ẹ fi etí sí i, kí ẹ sì fetí sí ohùn mi; ẹ fiyè sílẹ̀, kí ẹ sì fetí sí àsọjáde mi. 24  Láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀+ ha ni atúlẹ̀ máa ń túlẹ̀ kí ó bàa lè fún irúgbìn, tí ó máa ń tú, tí ó sì ń fọ́ ògúlùtu lórí ilẹ̀ rẹ̀ bí?+ 25  Nígbà tí ó bá ti mú ojú rẹ̀ jọ̀lọ̀, kì í ha ṣe lẹ́yìn ìyẹn ni ó ń tú kúmínì dúdú ká, tí ó sì ń wọ́n kúmínì,+ kì yóò ha sì gbin àlìkámà, jéró,+ àti ọkà bálì sí ibi tí a yàn kalẹ̀,+ àti ọkà sípẹ́ẹ̀tì+ gẹ́gẹ́ bí ààlà rẹ̀?+ 26  Ẹnì kan sì ń tọ́ ọ sọ́nà+ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ó tọ́. Ọlọ́run rẹ̀ ń fún un ní ìtọ́ni.+ 27  Nítorí pé kì í ṣe ohun èlò ìpakà+ ni a fi ń lu kúmínì dúdú; a kì í sì í yí àgbá kẹ̀kẹ́ lórí kúmínì. Nítorí pé ọ̀pá+ ni a sábà máa fi ń lu kúmínì dúdú fọ́, a sì máa ń lo ọ̀gọ fún kúmínì. 28  A ha sábà máa ń fọ́ ọkà tí a fi ń ṣe búrẹ́dì bí? Nítorí kò ṣẹlẹ̀ rí pé kí ènìyàn máa tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀+ ṣáá láìdabọ̀.+ Yóò sì mú kí àgbá ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí yí gbiri, àti àwọn ẹṣin rẹ̀, ṣùgbọ́n òun kì yóò fọ́ ọ.+ 29  Èyí pẹ̀lú ni ohun tí ó ti jáde wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun fúnra rẹ̀,+ ẹni tí ó jẹ́ àgbàyanu nínú ète, ẹni tí ó ti ṣe púpọ̀púpọ̀ nínú ìṣiṣẹ́yọrí.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé