2 Sámúẹ́lì 9:1-13
9 Dáfídì sì tẹ̀ síwájú láti sọ pé: “Ẹnikẹ́ni ha ṣì ṣẹ́ kù ní ilé Sọ́ọ̀lù, kí n lè ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́+ sí i nítorí Jónátánì?”+
2 Wàyí o, ilé Sọ́ọ̀lù ní ìránṣẹ́ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Síbà.+ Nítorí náà, wọ́n pè é wá sọ́dọ̀ Dáfídì, nígbà náà ni ọba sọ fún un pé: “Ṣé ìwọ ni Síbà?” ó dáhùn pé: “Èmi ni ìránṣẹ́ rẹ.”
3 Ọba sì ń bá a lọ láti wí pé: “Kò ha sí ẹnikẹ́ni ní ilé Sọ́ọ̀lù mọ́ rárá, kí n lè ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run sí i?”+ Látàrí èyí, Síbà sọ fún ọba pé: “Ọmọkùnrin Jónátánì kan ṣì wà, tí ó rọ ní ẹsẹ̀.”+
4 Nígbà náà ni ọba sọ fún un pé: “Ibo ni ó wà?” Nítorí náà, Síbà sọ fún ọba pé: “Wò ó! Ó wà ní ilé Mákírù+ ọmọkùnrin Ámíélì ní Lo-débárì.”+
5 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Dáfídì Ọba ránṣẹ́, ó sì mú un láti ilé Mákírù ọmọkùnrin Ámíélì ní Lo-débárì.
6 Nígbà tí Mefibóṣẹ́tì ọmọkùnrin Jónátánì ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù wọlé tọ Dáfídì wá, ní kíá, ó dojú bolẹ̀, ó sì wólẹ̀.+ Nígbà náà ni Dáfídì sọ pé: “Mefibóṣẹ́tì!” ó dáhùn pé: “Ìránṣẹ́ rẹ nìyí.”
7 Dáfídì sì ń bá a lọ láti sọ fún un pé: “Má fòyà, nítorí láìkùnà, èmi yóò ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́+ sí ọ nítorí Jónátánì baba rẹ;+ èmi yóò sì dá gbogbo pápá+ Sọ́ọ̀lù baba rẹ àgbà padà fún ọ, ìwọ alára yóò sì máa jẹ oúnjẹ ní tábìlì mi nígbà gbogbo.”+
8 Látàrí ìyẹn, ó wólẹ̀, ó sì sọ pé: “Kí ni ìránṣẹ́ rẹ jẹ́, tí o fi yí ojú rẹ sí òkú ajá+ bí èmi?”
9 Wàyí o, ọba pe Síbà, ẹmẹ̀wà Sọ́ọ̀lù, ó sì sọ fún un pé: “Ohun gbogbo tí ó jẹ́ ti Sọ́ọ̀lù àti gbogbo ilé rẹ̀ ni mo fi fún+ ọmọ-ọmọ ọ̀gá rẹ.
10 Ìwọ yóò sì máa ro ilẹ̀ náà fún un, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ, ìwọ yóò sì máa ṣe kíkójọpọ̀, yóò sì jẹ́ oúnjẹ fún àwọn tí ó jẹ́ ti ọmọ-ọmọ ọ̀gá rẹ, wọ́n yóò sì máa jẹun; ṣùgbọ́n Mefibóṣẹ́tì alára, ọmọ-ọmọ ọ̀gá rẹ, yóò máa jẹ oúnjẹ ní tábìlì mi nígbà gbogbo.”+
Wàyí o, Síbà ní ọmọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti ogún ìránṣẹ́.+
11 Nítorí náà, Síbà sọ fún ọba pé: “Ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú gbogbo èyí tí olúwa mi ọba pa láṣẹ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ ni bí ìránṣẹ́ rẹ yóò ti ṣe; ṣùgbọ́n Mefibóṣẹ́tì+ yóò máa jẹun ní tábìlì mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọba.”
12 Wàyí o, Mefibóṣẹ́tì ní ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Máíkà,+ gbogbo àwọn tí ń gbé ní ilé Síbà sì jẹ́ ìránṣẹ́ fún Mefibóṣẹ́tì.
13 Mefibóṣẹ́tì alára sì ń gbé ní Jerúsálẹ́mù, nítorí pé ó ń jẹun+ nígbà gbogbo ní tábìlì ọba; ó sì rọ ní ẹsẹ̀ méjèèjì.+

