2 Sámúẹ́lì 22:1-51
22 Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àwọn ọ̀rọ̀ orin yìí+ fún Jèhófà ní ọjọ́ tí Jèhófà dá a nídè kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá+ rẹ̀ àti kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ Sọ́ọ̀lù;+
2 ó sì ń bá a lọ láti sọ pé:
“Jèhófà ni àpáta gàǹgà+ mi àti odi agbára+ mi àti Olùpèsè àsálà fún mi.+
3 Ọlọ́run mi ni àpáta mi.+ Èmi yóò sá di í,
Apata+ mi àti ìwo+ ìgbàlà mi, ibi gíga ààbò mi,+
Àti ibi ìsásí mi,+ Olùgbàlà mi;+ ìwọ gbà mí là kúrò nínú ìwà ipá.+
4 Jèhófà, ẹni tí ó yẹ fún ìyìn,+ ni èmi yóò ké pè,
A ó sì gbà mí là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.+
5 Nítorí àwọn ìgbì aṣekúpani tí ń fọ́n ká di ìfóófòó ká mi mọ́;+
Ìkún omi ayaluni lójijì ti àwọn ènìyàn tí kò dára fún ohunkóhun wà tí ń kó ìpayà bá mi ṣáá.+
6 Àwọn ìjàrá Ṣìọ́ọ̀lù yí mi ká;+
Àwọn ìdẹkùn ikú kò mí lójú.+
7 Mo ń ké pe Jèhófà ṣáá nínú wàhálà mi,+
Mo sì ń pe Ọlọ́run mi.+
Nígbà náà, ó gbọ́ ohùn mi láti inú tẹ́ńpìlì rẹ̀,+
Pẹ̀lú igbe mi fún ìrànlọ́wọ́ ní etí rẹ̀.+
8 Ilẹ̀ ayé sì bẹ̀rẹ̀ sí mì síwá-sẹ́yìn, ó sì mì jì gìjì gì;+
Ṣìbáṣìbo bá àwọn ìpìlẹ̀ ọ̀run,+
Wọ́n sì ń mì síwá-sẹ́yìn nítorí pé a ti mú un bínú.+
9 Èéfín gòkè lọ láti ihò imú rẹ̀, iná láti ẹnu rẹ̀ sì ń jẹ run nìṣó;+
Àwọn ẹyín iná sì ń jó láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.+
10 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹ ọ̀run wálẹ̀, ó sì sọ̀ kalẹ̀;+
Ìṣúdùdù nínípọn sì wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.+
11 Ó sì ń gun kérúbù+ bọ̀, ó sì ń fò bọ̀;
Ó sì di rírí lórí àwọn ìyẹ́ apá ẹ̀mí kan.+
12 Nígbà náà ni ó fi òkùnkùn yí ara rẹ̀ ká gẹ́gẹ́ bí àwọn àtíbàbà,+
Omi ṣíṣú, àwọsánmà nínípọn.+
13 Láti inú ìtànyòò tí ó wà ní iwájú rẹ̀ ni ẹyín iná ti ń jó.+
14 Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí sán ààrá láti ọ̀run,+
Ẹni Gíga Jù Lọ sì bẹ̀rẹ̀ sí fọ ohùn rẹ̀ jáde.+
15 Ó sì ń rán àwọn ọfà jáde ṣáá, kí ó lè tú wọn ká;+
Mànàmáná, kí ó lè kó wọn sínú ìdàrúdàpọ̀.+
16 Ojú ìṣàn omi òkun sì di rírí,+
Àwọn ìpìlẹ̀ ilẹ̀ eléso+ di títú síta,
Nípa ìbáwí mímúná Jèhófà, láti inú ìtújáde èémí ihò imú rẹ̀.+
17 Ó ń ránṣẹ́ láti ibi gíga lókè, ó ń mú mi,+
Ó ń fà mí jáde kúrò nínú omi púpọ̀.+
18 Ó ń dá mi nídè kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára,+
Kúrò lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi; nítorí pé wọ́n lágbára jù mí.+
19 Wọ́n ń kò mí lójú ṣáá ní ọjọ́ àjálù mi,+
Ṣùgbọ́n Jèhófà di ìtìlẹyìn mi.+
20 Ó sì tẹ̀ síwájú láti mú mi jáde sí ibi aláyè gbígbòòrò;+
Ó ń gbà mí sílẹ̀, nítorí pé ó ní inú dídùn sí mi.+
21 Jèhófà san mí lẹ́san gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;+
Ó san án padà fún mi gẹ́gẹ́ bí ìmọ́tónítóní ọwọ́ mi.+
22 Nítorí mo ti pa àwọn ọ̀nà Jèhófà mọ́,+
Èmi kò sì fi Ọlọ́run mi sílẹ̀ lọ́nà burúkú.+
23 Nítorí gbogbo ìpinnu ìdájọ́+ rẹ̀ wà ní iwájú mi;
Àti ní ti àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ̀, èmi kì yóò yapa kúrò nínú wọn.+
24 Èmi yóò sì fi ara mi hàn ní aláìní-àléébù+ sí i,
Dájúdájú, èmi yóò sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ìṣìnà níhà ọ̀dọ̀ mi.+
25 Kí Jèhófà sì san án padà fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,+
Gẹ́gẹ́ bí ìmọ́tónítóní mi ní iwájú rẹ̀.+
26 Ìwọ yóò hùwà lọ́nà ìdúróṣinṣin sí ẹni ìdúróṣinṣin;+
Ìwọ yóò bá aláìní-àléébù, alágbára ńlá lò lọ́nà àìlálèébù;+
27 Sí ẹni tí ó mọ́, ìwọ yóò fi ara rẹ hàn ní ẹni tí ó mọ́;+
Sí oníwà wíwọ́, ìwọ yóò ṣe bí ọ̀dẹ̀.+
28 Àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni ìwọ yóò sì gbà là;+
Ṣùgbọ́n ojú rẹ lòdì sí àwọn onírera, kí o lè rẹ̀ wọ́n wálẹ̀.+
29 Nítorí ìwọ ni fìtílà mi, Jèhófà,+
Jèhófà sì ni ó mú kí òkùnkùn mi mọ́lẹ̀.+
30 Nítorí nípasẹ̀ rẹ, mo lè sáré ní ìgbéjàko ẹgbẹ́ onísùnmọ̀mí;+
Nípasẹ̀ Ọlọ́run mi, mo lè gun ògiri.+
31 Ní ti Ọlọ́run tòótọ́, pípé ni ọ̀nà rẹ̀;+
Àsọjáde Jèhófà jẹ́ èyí tí a yọ́ mọ́.+
Apata ni ó jẹ́ fún gbogbo àwọn tí ń sá di í.+
32 Nítorí pé ta ni Ọlọ́run, yàtọ̀ sí Jèhófà,+
Ta sì ni àpáta, yàtọ̀ sí Ọlọ́run wa?+
33 Ọlọ́run tòótọ́ ni odi agbára mi tí ó lókun,+
Òun yóò sì mú kí ọ̀nà mi jẹ́ pípé,+
34 Ó ṣe ẹsẹ̀ mi bí ti egbin;+
Ó sì mú mi dúró sórí àwọn ibi tí ó ga fún mi.+
35 Ó ń kọ́ ọwọ́ mi fún ogun;+
Apá mi sì ti tẹ ọrun bàbà.+
36 Ìwọ yóò sì fún mi ní apata ìgbàlà rẹ,+
Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ rẹ sì ni ó sọ mí di ńlá.+
37 Ìwọ yóò ṣe àyè tí ó tóbi tó fún àwọn ìṣísẹ̀ mi lábẹ́ mi;+
Dájúdájú, ọrùn ẹsẹ̀ mi kì yóò gbò yèpéyèpé.+
38 Ṣe ni èmi yóò lépa àwọn ọ̀tá mi, kí n lè pa wọ́n rẹ́ ráúráú,
Èmi kì yóò sì padà, títí wọn yóò fi pa run pátápátá.+
39 Èmi yóò sì pa wọ́n run pátápátá, èmi yóò sì ṣẹ́ wọn sí wẹ́wẹ́,+ kí wọ́n má bàa dìde mọ́;+
Wọn yóò sì ṣubú lábẹ́ ẹsẹ̀ mi.+
40 Ìwọ yóò sì fi ìmí dì mí lámùrè fún ìjà ogun;+
Ìwọ yóò mú kí àwọn tí ó dìde sí mi wó lulẹ̀ lábẹ́ mi.+
41 Àti ní ti àwọn ọ̀tá mi, ìwọ yóò fún mi ní ẹ̀yìn ọrùn [wọn] dájúdájú;+
Àwọn tí ó kórìíra mi lọ́nà gbígbóná janjan—èmi yóò pa wọ́n lẹ́nu mọ́ pẹ̀lú.+
42 Wọ́n kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n kò sí olùgbàlà kankan;+
Sí Jèhófà, ṣùgbọ́n kò dá wọn lóhùn ní ti tòótọ́.+
43 Èmi yóò sì gún wọn kúnná bí ekuru ilẹ̀;+
Bí ẹrẹ̀ ojú pópó ni èmi yóò lọ̀ wọ́n lúúlúú;
Èmi yóò lù wọ́n di pẹrẹsẹ.
44 Ìwọ yóò sì pèsè àsálà fún mi kúrò lọ́wọ́ àléébù wíwá àwọn ènìyàn mi.+
Ìwọ yóò fi ìṣọ́ ṣọ́ mi kí n lè jẹ́ olórí àwọn orílẹ̀-èdè;+
Àwọn ènìyàn tí èmi kò mọ̀—wọn yóò sìn mí.+
45 Àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè alára yóò wá fi ìwárìrì tẹrí ba fún mi;+
Àwọn etí yóò jẹ́ onígbọràn láti gbọ́ mi.+
46 Àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè alára yóò pòórá,
Wọn yóò sì fi ìwárìrì jáde wá láti inú odi ààbò wọn.+
47 Jèhófà ń bẹ;+ ìbùkún sì ni fún Àpáta mi;+
Kí a sì gbé Ọlọ́run àpáta ìgbàlà mi ga.+
48 Ọlọ́run tòótọ́ ni Olùpèsè ìgbẹ̀san fún mi+
Àti Ẹni tí ń rẹ àwọn ènìyàn sílẹ̀ lábẹ́ mi,+
49 Àti Ẹni tí ń mú mi jáde kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.+
Ìwọ yóò sì gbé mi lékè àwọn tí ń dìde sí mi;+
Ìwọ yóò dá mi nídè kúrò lọ́wọ́ ènìyàn oníwà ipá.+
50 Ìdí nìyẹn tí èmi yóò fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Jèhófà, láàárín àwọn orílẹ̀-èdè;+
Èmi yóò sì kọ orin atunilára sí orúkọ rẹ:+
51 Ẹni tí ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìgbàlà ńlá fún ọba rẹ̀,+
Tí ó sì ń ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí ẹni àmì òróró rẹ̀,+
Sí Dáfídì àti sí irú-ọmọ rẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin.”+

