2 Sámúẹ́lì 14:1-33

14  Wàyí o, Jóábù+ ọmọkùnrin Seruáyà+ wá mọ̀ pé ọkàn-àyà ọba fà sí Ábúsálómù.+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jóábù ránṣẹ́ lọ sí Tékóà,+ ó sì mú ọlọ́gbọ́n+ obìnrin kan láti ibẹ̀, ó sì sọ fún un pé: “Jọ̀wọ́, bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ̀fọ̀, sì fi ẹ̀wù ọ̀fọ̀ wọ ara rẹ, jọ̀wọ́, má sì fi òróró para;+ kí o sì dà bí obìnrin kan níhìn-ín tí ó ti ń ṣọ̀fọ̀ fún ọjọ́ púpọ̀ lórí ẹnì kan tí ó kú.+  Kí o sì wọlé tọ ọba wá, kí o sì sọ irú ọ̀rọ̀ yìí fún un.” Pẹ̀lú ìyẹn, Jóábù fi àwọn ọ̀rọ̀ náà sí i lẹ́nu.+  Obìnrin ará Tékóà náà sì tẹ̀ síwájú láti wọlé tọ ọba wá, ó sì dojú bolẹ̀,+ ó sì wólẹ̀, ó sì sọ pé: “Gbà mí là,+ ìwọ ọba!”  Látàrí èyí, ọba sọ fún un pé: “Kí ní ṣe ọ́?” Ó fèsì pé: “Ní tòótọ́, opó+ ni mí, nísinsìnyí tí ọkọ mi ti kú.  Ìránṣẹ́bìnrin rẹ sì ní ọmọkùnrin méjì , àwọn méjèèjì sì bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn jì jàkadì ní pápá+ nígbà tí kò sí olùdáǹdè+ láti là wọ́n. Níkẹyìn, ọ̀kan ṣá èkejì balẹ̀, ó sì fi ikú pa á.  Sì kíyè sí i, gbogbo ìdílé ti dìde sí ìránṣẹ́bìnrin rẹ, wọ́n sì ń sọ ṣáá pé, ‘Fi ẹni tí ó kọlu arákùnrin rẹ̀ lé wa lọ́wọ́, kí a lè fi ikú pa á nítorí ọkàn arákùnrin rẹ̀+ tí ó pa,+ sì jẹ́ kí a pa ajogún náà pàápàá rẹ́ ráúráú!’ Dájúdájú, wọn yóò sì fẹ́ ìpọ́nyòò èédú mi tí ó ṣẹ́ kù pa, kí a má bàa fi yálà orúkọ tàbí àṣẹ́kù fún ọkọ mi lórí ilẹ̀.”+  Nígbà náà ni ọba sọ fún obìnrin náà pé: “Máa lọ sí ilé rẹ, èmi fúnra mi yóò sì pàṣẹ nípa rẹ.”+  Látàrí èyí, obìnrin ará Tékóà náà sọ fún ọba pé: “Kí ìṣìnà náà wà lórí mi, ìwọ olúwa mi ọba, àti lórí ilé baba mi+ pẹ̀lú, nígbà tí ọba àti ìtẹ́ rẹ̀ jẹ́ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀.” 10  Ọba sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá ń sọ̀rọ̀ sí ọ, kí ìwọ pẹ̀lú mú un wá sọ́dọ̀ mi, òun kì yóò sì tún ṣe ọ́ lọ́ṣẹ́ mọ́ láé.” 11  Ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Jọ̀wọ́, kí ọba rántí Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ kí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀+ má ṣe máa bá a lọ ní fífa ìparun àti pé kí wọ́n má pa ọmọkùnrin mi rẹ́ ráúráú.” Ó fèsì pé: “Bí Jèhófà ti ń bẹ,+ fọ́nrán irun+ kan ti ọmọkùnrin rẹ kì yóò bọ́ sí ilẹ̀.” 12  Obìnrin náà wá sọ pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin+ rẹ sọ ọ̀rọ̀+ kan fún olúwa mi ọba.” Nítorí náà, ó sọ pé: “Sọ ọ́!”+ 13  Obìnrin náà sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Kí wá ni ìdí tí o fi gbèrò lọ́nà yìí+ sí àwọn ènìyàn Ọlọ́run?+ Bí ọba ti ń sọ ọ̀rọ̀ yìí òun dà bí ẹni tí ó jẹ̀bi,+ ní ti pé ọba kò mú ẹni tirẹ̀ tí a lé kúrò láwùjọ+ padà wá. 14  Nítorí àwa yóò kú láìsí àní-àní,+ a ó sì dà bí omi tí a dà sílẹ̀, èyí tí a kò lè kó jọ. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kì yóò mú ọkàn+ kan kúrò, ó sì ti gbèrò ìdí tí a kò fi ní láti lé ẹni tí a lé kúrò láwùjọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 15  Nísinsìnyí tí mo sì ti wọlé wá láti sọ ọ̀rọ̀ yìí fún olúwa mi ọba, ó jẹ́ nítorí pé àwọn ènìyàn mú mi fòyà. Nítorí náà, ìránṣẹ́bìnrin rẹ sọ pé, ‘Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n bá ọba sọ̀rọ̀. Bóyá ọba yóò gbé ìgbésẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ẹrúbìnrin rẹ̀. 16  Nítorí pé ọba tẹ̀ síwájú láti fetí sílẹ̀, kí ó bàa lè dá ẹrúbìnrin rẹ̀ nídè kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ ọkùnrin tí ń wá ọ̀nà láti pa èmi àti ọmọkùnrin mi kan ṣoṣo rẹ́ ráúráú kúrò lórí ogún tí Ọlọ́run fi fúnni,’+ 17  nígbà náà, ìránṣẹ́bìnrin rẹ sọ pé, ‘Jọ̀wọ́, kí ọ̀rọ̀ olúwa mi ọba ṣiṣẹ́ láti fúnni ní ìsinmi.’ Nítorí bí áńgẹ́lì+ Ọlọ́run tòótọ́ ni bí olúwa mi ọba ti rí, láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó dára àti ohun tí ó burú,+ kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ sì wà pẹ̀lú rẹ.” 18  Ọba dáhùn wàyí, ó sì sọ fún obìnrin náà pé: “Jọ̀wọ́, má fi ohun kan pa mọ́ fún mi nípa èyí tí èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ.”+ Obìnrin náà fèsì pé: “Jọ̀wọ́, kí olúwa mi ọba sọ ọ́.” 19  Ọba sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Ọwọ́ Jóábù+ ha wà pẹ̀lú rẹ nínú gbogbo èyí?”+ Nígbà náà ni obìnrin náà dáhùn, ó sì sọ pé: “Bí ọkàn rẹ ti ń bẹ,+ ìwọ olúwa mi ọba, kò sí ènìyàn tí ó lè lọ sí apá ọ̀tún tàbí lọ sí apá òsì nínú gbogbo èyí tí olúwa mi ọba ti sọ; nítorí ìránṣẹ́ rẹ Jóábù ni ó pàṣẹ fún mi, òun sì ni ó fi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí ìránṣẹ́bìnrin rẹ lẹ́nu.+ 20  Nítorí láti mú àyípadà bá ojú ọ̀ràn ni ìránṣẹ́ rẹ Jóábù fi ṣe nǹkan yìí, ṣùgbọ́n olúwa mi jẹ́ ọlọ́gbọ́n bí ẹni pé pẹ̀lú ọgbọ́n áńgẹ́lì+ Ọlọ́run tòótọ́ láti mọ gbogbo ohun tí ó wà ní ilẹ̀ ayé.” 21  Lẹ́yìn náà, ọba sọ fún Jóábù pé: “Kíyè sí i, nísinsìnyí, èmi yóò ṣe ohun yìí+ dájúdájú. Nítorí náà, lọ, mú ọ̀dọ́kùnrin náà Ábúsálómù padà wá.”+ 22  Látàrí èyí, Jóábù dojú bolẹ̀, ó sì wólẹ̀, ó sì súre fún ọba;+ Jóábù sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Lónìí ni ìránṣẹ́ rẹ mọ̀ pé èmi ti rí ojú rere ní ojú rẹ,+ ìwọ olúwa mi ọba, nítorí pé ọba ti gbé ìgbésẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀.” 23  Pẹ̀lú ìyẹn, Jóábù dìde, ó sì lọ sí Géṣúrì,+ ó sì mú Ábúsálómù wá sí Jerúsálẹ́mù.+ 24  Bí ó ti wù kí ó rí, ọba sọ pé: “Kí ó yí padà lọ sí ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n kò gbọ́dọ̀ rí ojú mi.”+ Nítorí náà, Ábúsálómù yí padà lọ sí ilé rẹ̀, kò sì rí ojú ọba. 25  Wàyí o, ní ìfiwéra, kò sí ọkùnrin kankan tí ó lẹ́wà+ bí Ábúsálómù tí ó yẹ fún ìyìn tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ ní gbogbo Ísírẹ́lì. Láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀, kò sí àbùkù kankan lára rẹ̀. 26  Nígbà tí ó bá sì gé irun orí rẹ̀—ó sì ṣẹlẹ̀ pé òpin ọdọọdún ni ó máa ń gé e; nítorí pé ó wúwo+ púpọ̀ lórí rẹ̀, òun a gé e—ó wọn irun orí rẹ̀, igba ṣékélì gẹ́gẹ́ bí òkúta àfiwọn ìwúwo tí ó jẹ́ ti ọba. 27  A sì wá bí ọmọkùnrin mẹ́ta fún Ábúsálómù+ àti ọmọbìnrin kan ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Támárì. Ó sì wá jẹ́ obìnrin tí ó lẹ́wà jù lọ ní ìrísí.+ 28  Ábúsálómù sì ń bá a lọ ní gbígbé Jerúsálẹ́mù fún ọdún méjì gbáko, kò sì rí ojú ọba.+ 29  Nítorí náà, Ábúsálómù ránṣẹ́ sí Jóábù láti rán an sí ọba, kò sì gbà láti wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Nígbà náà ni ó tún ránṣẹ́, ní ìgbà kejì , kò sì gbà láti wá. 30  Níkẹyìn, ó sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ wo abá ilẹ̀ Jóábù lẹ́gbẹ̀ẹ́ tèmi, ó sì ní ọkà bálì níbẹ̀. Ẹ lọ ti iná bọ̀ ọ́.”+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn ìránṣẹ́ Ábúsálómù ti iná bọ abá ilẹ̀ náà.+ 31  Látàrí èyí, Jóábù dìde, ó sì tọ Ábúsálómù wá ní ilé, ó sì sọ fún un pé: “Èé ṣe tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ fi ti iná bọ abá ilẹ̀ tí ó jẹ́ tèmi?” 32  Nítorí náà, Ábúsálómù sọ fún Jóábù pé: “Wò ó! Mo ránṣẹ́ sí ọ pé, ‘Wá síhìn-ín, sì jẹ́ kí n rán ọ sí ọba pé: “Èé ṣe tí mo fi wá láti Géṣúrì?+ Ì bá sàn fún mi ká ní mo ṣì wà níbẹ̀. Wàyí o, jẹ́ kí n rí ojú ọba, bí ìṣìnà èyíkéyìí bá sì wà nínú mi,+ nígbà náà, kí ó fi ikú pa mí.”’” 33  Lẹ́yìn náà, Jóábù wọlé tọ ọba wá, ó sì sọ fún un. Nígbà náà ni ó pe Ábúsálómù, ẹni tí ó wọlé tọ ọba wá wàyí, ó sì wólẹ̀ fún un, ní dídojúbolẹ̀ níwájú ọba; lẹ́yìn èyí tí ọba fi ẹnu ko Ábúsálómù lẹ́nu.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé