2 Sámúẹ́lì 1:1-27

1  Ó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú Sọ́ọ̀lù, àti nígbà tí Dáfídì ti padà dé láti ibi tí ó ti ṣá àwọn ọmọ Ámálékì balẹ̀,+ pé Dáfídì ń bá a lọ láti gbé ní Síkílágì+ fún ọjọ́ méjì .  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kẹta pé, wò ó! ọkùnrin+ kan ń bọ̀ láti ibùdó, láti ọ̀dọ̀ Sọ́ọ̀lù, pẹ̀lú ẹ̀wù rẹ̀ gbígbọ̀nya+ àti ìdọ̀tí ní orí rẹ̀;+ ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Dáfídì, ní kíá, ó dojú bolẹ̀,+ ó sì wólẹ̀.  Dáfídì sì tẹ̀ síwájú láti sọ fún un pé: “Ibo ni o ti wá?” ó dá a lóhùn pé: “Láti ibùdó Ísírẹ́lì ni mo ti sá wá.”  Dáfídì sì ń bá a lọ láti sọ fún un pé: “Báwo ni ọ̀ràn náà ṣe rí? Jọ̀wọ́, sọ fún mi.” Ó fèsì pé: “Àwọn ènìyàn náà ti sá kúrò níbi ìjà ogun, àti pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ènìyàn náà ti ṣubú tí wọ́n fi kú,+ àní Sọ́ọ̀lù+ àti Jónátánì+ ọmọkùnrin rẹ̀ pàápàá ti kú.”  Nígbà náà ni Dáfídì sọ fún ọ̀dọ́kùnrin tí ó ń bá a sọ̀rọ̀ pé: “Báwo ni o ṣe mọ̀ ní ti tòótọ́ pé Sọ́ọ̀lù ti kú àti Jónátánì ọmọkùnrin rẹ̀ pẹ̀lú?”+  Látàrí èyí, ọ̀dọ́kùnrin tí ó ń bá a sọ̀rọ̀ wí pé: “Mo kàn ṣàdédé dé orí Òkè Ńlá Gíbóà,+ sì kíyè sí i, Sọ́ọ̀lù fi ara ti ọ̀kọ̀ rẹ̀;+ sì wò ó! àwọn oníkẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn agẹṣin ti bá a.+  Nígbà tí ó yíjú padà tí ó sì rí mi, nígbà náà ni ó pè mí, mo sì wí pé, ‘Èmi nìyí!’  Ó sì ń bá a lọ láti sọ fún mi pé, ‘Ta ni ọ́?’ mo sì dá a lóhùn pé, ‘Ọmọ Ámálékì ni mí.’+  Nígbà náà ni ó sọ pé, ‘Jọ̀wọ́, dúró lẹ́bàá mi, kí o sì fi ikú pa mí dájúdájú, nítorí pajápajá ti mú mi, nítorí pé gbogbo ọkàn+ mi ṣì wà nínú mi.’ 10  Nítorí náà, mo dúró lẹ́bàá rẹ̀, mo sì fi ikú pa á+ dájúdájú, nítorí mo mọ̀ pé kò lè wà láàyè mọ́ lẹ́yìn tí ó ti ṣubú. Nígbà náà ni mo mú adé dáyádémà+ tí ó wà lórí rẹ̀ àti júfù tí ó wà ní apá rẹ̀, kí n lè kó wọn wá fún olúwa mi níhìn-ín.” 11  Látàrí èyí, Dáfídì di ẹ̀wù ara rẹ̀ mú, ó sì gbọ̀n ọ́n ya,+ bẹ́ẹ̀ sì ni gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ṣe. 12  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pohùn réré ẹkún,+ wọ́n sì sunkún,+ wọ́n sì gbààwẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́ fún Sọ́ọ̀lù àti fún Jónátánì ọmọkùnrin rẹ̀ àti fún àwọn ènìyàn Jèhófà àti fún ilé Ísírẹ́lì,+ nítorí pé wọ́n ti tipa idà ṣubú. 13  Wàyí o, Dáfídì wí fún ọ̀dọ́kùnrin tí ń bá a sọ̀rọ̀ pé: “Ibo ni o ti wá?” ó dáhùn pé: “Ọmọkùnrin àtìpó kan, ọmọ Ámálékì,+ ni mí.” 14  Nígbà náà ni Dáfídì sọ fún un pé: “Báwo ni ó ṣe jẹ́ tí ìwọ kò bẹ̀rù+ láti na ọwọ́ rẹ láti run ẹni àmì òróró+ Jèhófà?” 15  Pẹ̀lú ìyẹn, Dáfídì pe ọ̀kan nínú àwọn ọ̀dọ́kùnrin, ó sì wí pé: “Sún mọ́ ọn. Kọlù ú.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó ṣá a balẹ̀, ó sì kú.+ 16  Nígbà náà ni Dáfídì sọ fún un pé: “Kí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ rẹ wà ní orí ìwọ fúnra rẹ,+ nítorí ẹnu ara rẹ ti jẹ́rìí lòdì sí ọ,+ pé, ‘Dájúdájú, èmi ni ó fi ikú pa ẹni àmì òróró Jèhófà.’”+ 17  Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin arò+ yìí lórí Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì ọmọkùnrin rẹ̀,+ 18  ó sì wí pé kí a kọ́ àwọn ọmọ Júdà+ ní “Ọrun.”+ Wò ó! A kọ ọ́ sínú ìwé Jáṣárì:+ 19  “Ìwọ Ísírẹ́lì, ẹwà ni a pa lórí àwọn ibi gíga rẹ.+ Wo bí àwọn alágbára ńlá ti ṣubú! 20  Ẹ má sọ ọ́ ní Gátì;+ Ẹ má ṣe kéde rẹ̀ ní àwọn ojú pópó Áṣíkẹ́lónì,+ Kí àwọn ọmọbìnrin Filísínì má bàa yọ̀, Kí àwọn ọmọbìnrin àwọn aláìdádọ̀dọ́ má bàa yọ ayọ̀ ńláǹlà.+ 21  Ẹ̀yin òkè ńlá Gíbóà,+ kí ìrì má sẹ̀, kí òjò má rọ̀ sórí yín, bẹ́ẹ̀ ni kí pápá àwọn ọrẹ mímọ́ má ṣe sí;+ Nítorí pé ibẹ̀ ni a ti sọ apata àwọn alágbára ńlá di àìmọ́, Apata Sọ́ọ̀lù, tí kò fi sí èyí tí a fi òróró yàn.+ 22  Láti inú ẹ̀jẹ̀ àwọn tí a pa, láti inú ọ̀rá àwọn alágbára ńlá, Ọrun Jónátánì kò yí padà,+ Idà Sọ́ọ̀lù kì yóò sì padà láìsí àṣeyọrí sí rere.+ 23  Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì,+ àwọn ẹni fífẹ́ àti ẹni gbígbádùnmọni, A kò sì pín wọn níyà ní ikú wọn.+ Wọ́n yára ju idì lọ,+ Wọ́n jẹ́ alágbára ńlá ju kìnnìún lọ.+ 24  Ẹ̀yin ọmọbìnrin Ísírẹ́lì, ẹ sunkún lórí Sọ́ọ̀lù, Ẹni tí ó fi aṣọ rírẹ̀dòdò tí ó ní ohun ọ̀ṣọ́ tí ó pinmirin wọ̀ yín, Ẹni tí ó fi ohun ọ̀ṣọ́ wúrà sára aṣọ yín.+ 25  Wo bí àwọn alágbára ńlá ti ṣubú ní àárín ìjà ogun!+ A pa Jónátánì lórí àwọn ibi gíga rẹ!+ 26  Wàhálà-ọkàn bá mi nítorí rẹ, Jónátánì arákùnrin mi, Ẹni gbígbádùnmọni gidigidi ni ìwọ jẹ́ fún mi.+ Ìfẹ́ rẹ sí mi jẹ́ àgbàyanu ju ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn obìnrin lọ.+ 27  Wo bí àwọn alágbára ńlá ti ṣubú+ Tí àwọn ohun ìjà ogun sì ṣègbé!”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé