2 Kọ́ríńtì 4:1-18

4  Ìdí nìyẹn, níwọ̀n bí a ti ní iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí+ ní ìbámu pẹ̀lú àánú tí a fi hàn sí wa,+ tí àwa kò fi juwọ́ sílẹ̀;  ṣùgbọ́n àwa ti kọ àwọn ohun má-jẹ̀ẹ́-á-gbọ́ tí ń tini lójú+ sílẹ̀ ní àkọ̀tán, a kò rin ìrìn àlùmọ̀kọ́rọ́yí, bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣe àbùlà ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,+ ṣùgbọ́n nípasẹ̀ fífi òtítọ́ hàn kedere, a ń dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà olúkúlùkù ẹ̀rí-ọkàn ẹ̀dá ènìyàn níwájú Ọlọ́run.+  Wàyí o, bí ìhìn rere tí àwa ń polongo bá wà lábẹ́ ìbòjú, ó wà lábẹ́ ìbòjú láàárín àwọn tí ń ṣègbé,+  láàárín àwọn tí ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí+ ti fọ́ èrò inú àwọn aláìgbàgbọ́ lójú,+ kí ìmọ́lẹ̀+ ìhìn rere ológo+ nípa Kristi, ẹni tí ó jẹ́ àwòrán+ Ọlọ́run, má bàa mọ́lẹ̀ wọlé.+  Nítorí àwa kò wàásù ara wa, bí kò ṣe Kristi Jésù gẹ́gẹ́ bí Olúwa,+ àti ara wa gẹ́gẹ́ bí ẹrú+ yín nítorí Jésù.  Nítorí Ọlọ́run ni ẹni tí ó wí pé: “Kí ìmọ́lẹ̀ tàn láti inú òkùnkùn,”+ ó sì ti tàn sí ọkàn-àyà wa láti fi ìmọ̀+ ológo nípa Ọlọ́run tànmọ́lẹ̀+ sí i nípasẹ̀ ojú Kristi.+  Àmọ́ ṣá o, àwa ní ìṣúra+ yìí nínú àwọn ohun èlò+ tí a fi amọ̀ ṣe,+ kí agbára+ tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá lè jẹ́ ti Ọlọ́run,+ kí ó má sì jẹ́ èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ àwa fúnra wa jáde.+  A há wa gádígádí ní gbogbo ọ̀nà,+ ṣùgbọ́n a kò há wa ré kọjá yíyíra; ọkàn wa dàrú, ṣùgbọ́n kì í ṣe láìsí ọ̀nà àbájáde+ rárá;  a ṣe inúnibíni sí wa, ṣùgbọ́n a kò fi wá sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́;+ a gbé wa ṣánlẹ̀,+ ṣùgbọ́n a kò pa wá run.+ 10  Níbi gbogbo nínú ara wa, ìgbà gbogbo ni àwa ń fara da ìlòsíni tí ń ṣekú pani tí wọ́n fi hàn sí Jésù,+ kí a lè fi ìyè Jésù pẹ̀lú hàn kedere nínú ara wa.+ 11  Nítorí àwa tí a wà láàyè ni a ń mú fi ojú ko ojú pẹ̀lú ikú+ nígbà gbogbo nítorí Jésù, kí a lè fi ìyè Jésù pẹ̀lú hàn kedere nínú ẹran ara kíkú wa.+ 12  Nítorí náà, ikú wà lẹ́nu iṣẹ́ nínú wa, ṣùgbọ́n ìyè nínú yín.+ 13  Wàyí o, nítorí a ní ẹ̀mí ìgbàgbọ́ kan náà, irú èyí tí a kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: “Mo lo ìgbàgbọ́, nítorí náà mo sọ̀rọ̀,”+ àwa pẹ̀lú lo ìgbàgbọ́ àti nítorí náà a sọ̀rọ̀, 14  ní mímọ̀ pé ẹni tí ó gbé Jésù dìde yóò gbé àwa náà dìde pa pọ̀ pẹ̀lú Jésù, yóò sì mú àwa pa pọ̀ pẹ̀lú yín wá.+ 15  Nítorí ohun gbogbo jẹ́ nítorí yín,+ kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí a sọ di púpọ̀ bàa lè pọ̀ gidigidi nítorí ìdúpẹ́ àwọn púpọ̀ sí i fún ògo Ọlọ́run.+ 16  Nítorí náà, àwa kò juwọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n bí ẹni tí a jẹ́ ní òde bá tilẹ̀ ń joro, dájúdájú, ẹni tí àwa jẹ́ ní inú+ ni a ń sọ dọ̀tun láti ọjọ́ dé ọjọ́. 17  Nítorí bí ìpọ́njú náà tilẹ̀ jẹ́ fún ìgbà díẹ̀,+ tí ó sì fúyẹ́, fún àwa, ó ń ṣiṣẹ́ yọrí sí ògo tí ó jẹ́ ti ìwọ̀n títayọ síwájú àti síwájú sí i, tí ó sì jẹ́ àìnípẹ̀kun;+ 18  nígbà tí àwa kò tẹ ojú wa mọ́ àwọn ohun tí a ń rí, bí kò ṣe àwọn ohun tí a kò rí.+ Nítorí àwọn ohun tí a ń rí jẹ́ fún ìgbà díẹ̀,+ ṣùgbọ́n àwọn ohun tí a kò rí jẹ́ fún àìnípẹ̀kun.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé