2 Kọ́ríńtì 1:1-24

1  Pọ́ọ̀lù, àpọ́sítélì+ Kristi Jésù nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọlọ́run, àti Tímótì+ arákùnrin wa sí ìjọ Ọlọ́run tí ó wà ní Kọ́ríńtì, pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ẹni mímọ́+ tí ń bẹ ní gbogbo Ákáyà:+ 2  Kí ẹ ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Baba wa Ọlọ́run àti Jésù Kristi Olúwa.+ 3  Ìbùkún ni fún Ọlọ́run àti Baba+ Olúwa wa Jésù Kristi, Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́+ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo,+ 4  ẹni tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa,+ kí àwa lè tu àwọn tí ó wà nínú ìpọ́njú èyíkéyìí nínú+ nípasẹ̀ ìtùnú tí Ọlọ́run fi ń tu àwa tìkára wa nínú.+ 5  Nítorí gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ìjìyà fún Kristi ti pọ̀ gidigidi nínú wa,+ bẹ́ẹ̀ ni ìtùnú tí a ń rí gbà nípasẹ̀ Kristi pọ̀ gidigidi pẹ̀lú.+ 6  Wàyí o, yálà a wà nínú ìpọ́njú, ó jẹ́ fún ìtùnú àti ìgbàlà+ yín; tàbí yálà a ń tù wá nínú, ó jẹ́ fún ìtùnú yín tí ń ṣiṣẹ́ láti mú kí ẹ fara da àwọn ìjìyà kan náà tí àwa pẹ̀lú ń jìyà.+ 7  Àti nítorí náà, ìrètí wa fún yín dúró láìmì, gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ ní tòótọ́ pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti jẹ́ alájọpín àwọn ìjìyà náà, lọ́nà kan náà ni ẹ ó ṣàjọpín ìtùnú pẹ̀lú.+ 8  Nítorí àwa kò fẹ́ kí ẹ ṣe aláìmọ̀, ẹ̀yin ará, nípa ìpọ́njú tí ó bá wa ní àgbègbè Éṣíà,+ pé a wà nínú ìdààmú dé góńgó tí ó ré kọjá okun wa, tó bẹ́ẹ̀ tí a kò ní ìdánilójú rárá nípa ìwàláàyè wa pàápàá.+ 9  Ní ti tòótọ́, a nímọ̀lára nínú ara wa pé a ti gba ìdájọ́ ikú. Èyí jẹ́ kí a má bàa ní ìgbẹ́kẹ̀lé+ wa nínú ara wa, bí kò ṣe nínú Ọlọ́run ẹni tí ń gbé òkú dìde.+ 10  Láti inú irúfẹ́ ohun ńlá kan bẹ́ẹ̀ bí ikú ni òun ti gbà wá sílẹ̀, tí yóò sì gbà wá sílẹ̀;+ ìrètí wa sì wà nínú rẹ̀ pé yóò gbà wá sílẹ̀ síwájú sí i+ pẹ̀lú. 11  Ẹ̀yin pẹ̀lú lè ṣèrànlọ́wọ́ ní àfikún nípa ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ yín fún wa,+ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ lè dúpẹ́+ nítorí wa fún ohun tí a fi inú rere fi fún wa nítorí ọ̀pọ̀ ojú tí ó kún fún àdúrà.+ 12  Nítorí ohun tí àwa fi ń ṣògo nìyí, èyí tí ẹ̀rí-ọkàn wa ń jẹ́rìí sí,+ pé pẹ̀lú ìjẹ́mímọ́ àti òtítọ́ inú lọ́nà ti Ọlọ́run, kì í ṣe pẹ̀lú ọgbọ́n ti ara+ bí kò ṣe pẹ̀lú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ti Ọlọ́run, ni àwa ti hùwà ní ayé, ṣùgbọ́n pàápàá jù lọ sí yín. 13  Nítorí ní ti gidi, àwa kò kọ̀wé àwọn nǹkan sí yín bí kò ṣe àwọn nǹkan tí ẹ mọ̀ dáadáa tàbí tí ẹ mọ̀ dájú pẹ̀lú; èyí tí èmi sì ní ìrètí pé ẹ óò máa bá a lọ láti mọ̀ dájú títí dé òpin,+ 14  gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀ dájú pẹ̀lú, dé àyè kan, pé ìdí kan ni àwa jẹ́ fún yín láti ṣògo,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ó ti jẹ́ fún wa pẹ̀lú ní ọjọ́ Olúwa wa Jésù.+ 15  Nítorí náà, pẹ̀lú ìgbọ́kànlé yìí, mo ń pète-pèrò tẹ́lẹ̀ láti wá sọ́dọ̀ yín,+ kí ẹ bàa lè ní àyè ẹ̀ẹ̀kejì+ fún ìdùnnú, 16  àti lẹ́yìn títẹsẹ̀dúró díẹ̀ lọ́dọ̀ yín láti lọ sí Makedóníà,+ àti láti padà láti Makedóníà sọ́dọ̀ yín,+ kí ẹ sì sìn+ mí díẹ̀ lọ́nà Jùdíà. 17  Tóò, nígbà tí mo ní irúfẹ́ ìpètepèrò bẹ́ẹ̀, èmi kò fi ìwà àìfi-nǹkan-pè+ èyíkéyìí kẹ́ra, àbí mo ṣe bẹ́ẹ̀? Tàbí àwọn ohun tí mo pète, mo ha pète wọn lọ́nà ti ẹran ara,+ pé lọ́dọ̀ mi ni kí ó jẹ́ “Bẹ́ẹ̀ ni, Bẹ́ẹ̀ ni” àti “Bẹ́ẹ̀ kọ́, Bẹ́ẹ̀ kọ́”?+ 18  Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ṣeé gbójú lé pé ọ̀rọ̀ wa tí a sọ fún yín kì í ṣe Bẹ́ẹ̀ ni, síbẹ̀ kí ó sì jẹ́ Bẹ́ẹ̀ kọ́. 19  Nítorí Ọmọ Ọlọ́run,+ Kristi Jésù, tí a wàásù rẹ̀ láàárín yín nípasẹ̀ wa, èyíinì ni, nípasẹ̀ èmi àti Sílífánù àti Tímótì,+ kò di Bẹ́ẹ̀ ni, síbẹ̀ kí ó sì jẹ́ Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n Bẹ́ẹ̀ ni ti di Bẹ́ẹ̀ ni nínú ọ̀ran tirẹ̀.+ 20  Nítorí bí ó ti wù kí àwọn ìlérí+ Ọlọ́run pọ̀ tó, wọ́n ti di Bẹ́ẹ̀ ni nípasẹ̀ rẹ̀.+ Nítorí náà nípasẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ni a ń ṣe “Àmín”+ sí Ọlọ́run fún ògo nípasẹ̀ wa. 21  Ṣùgbọ́n ẹni tí ń fọwọ́ sọ̀yà pé ẹ̀yin àti àwa jẹ́ ti Kristi àti ẹni tí ó fòróró yàn+ wá ni Ọlọ́run. 22  Ó tún ti fi èdìdì+ rẹ̀ sórí wa, ó sì ti fún wa ní àmì ìdánilójú+ ohun tí ń bọ̀, èyíinì ni, ẹ̀mí+ náà, tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà wa. 23  Wàyí o, mo ké pe Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí+ lòdì sí ọkàn èmi tìkára mi pé láti dá yín+ sí ni kò tíì jẹ́ kí n wá sí Kọ́ríńtì. 24  Kì í ṣe pé a jẹ́ ọ̀gá+ lórí ìgbàgbọ́ yín, ṣùgbọ́n a jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀+ fún ìdùnnú yín, nítorí nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín+ ni ẹ dúró.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé