2 Kíróníkà 9:1-31
9 Ọbabìnrin Ṣébà+ alára gbọ́ ìròyìn nípa Sólómọ́nì, ó sì tẹ̀ síwájú láti wá fi àwọn ìbéèrè apinnilẹ́mìí+ dán Sólómọ́nì wò ní Jerúsálẹ́mù, pa pọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ abánirìn wíwúnilórí gan-an àti àwọn ràkúnmí+ tí ó ru òróró básámù,+ àti wúrà+ ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ, àti àwọn òkúta iyebíye.+ Níkẹyìn, ó wọlé tọ Sólómọ́nì wá, ó sì bá a sọ̀rọ̀ nípa ohun gbogbo tí ó wà ní góńgó ọkàn-àyà rẹ̀.+
2 Sólómọ́nì, ẹ̀wẹ̀, ń bá a lọ láti sọ gbogbo ọ̀ràn obìnrin náà fún un,+ kò sì sí ọ̀ràn kankan tí ó fara sin fún Sólómọ́nì tí kò sọ fún obìnrin náà.+
3 Nígbà tí ọbabìnrin Ṣébà wá rí ọgbọ́n+ Sólómọ́nì àti ilé tí ó kọ́,+
4 àti oúnjẹ orí tábìlì rẹ̀+ àti jíjókòó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ìṣètò ìgbóúnjẹfúnni àwọn aṣèránṣẹ́ rẹ̀ àti ìwọṣọ wọn+ àti àwọn agbọ́tí rẹ̀+ àti ìwọṣọ wọn, àti àwọn ẹbọ sísun rẹ̀+ tí ó máa ń fi rúbọ déédéé ní ilé Jèhófà,+ nígbà náà, kò wá sí ẹ̀mí kankan mọ́ nínú rẹ̀.
5 Nítorí náà, ó wí fún ọba pé: “Òótọ́ ni ọ̀rọ̀ tí mo gbọ́ ní ilẹ̀ tèmi nípa àwọn ọ̀ràn rẹ àti nípa ọgbọ́n rẹ.+
6 Èmi kò sì ní ìgbàgbọ́+ nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọn títí mo fi wá kí ojú èmi fúnra mi lè rí i;+ sì wò ó! a kò sọ ìdajì ọ̀pọ̀ yanturu ọgbọ́n+ rẹ fún mi. Ìwọ ta yọ ré kọjá ìròyìn tí mo gbọ́.+
7 Aláyọ̀+ ni àwọn ènìyàn rẹ, aláyọ̀ sì ni àwọn ìránṣẹ́ tìrẹ wọ̀nyí tí ń dúró níwájú rẹ nígbà gbogbo tí wọ́n sì ń fetí sí ọgbọ́n+ rẹ.
8 Kí ìbùkún+ jẹ́ ti Jèhófà Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ní inú dídùn+ sí ọ nípa fífi ọ́ sórí ìtẹ́+ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ;+ nítorí pé Ọlọ́run rẹ nífẹ̀ẹ́+ Ísírẹ́lì, láti mú un dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin, tí ó fi fi ọ́ ṣe ọba+ lé wọn lórí láti máa mú ìpinnu ìdájọ́+ àti òdodo+ ṣẹ ní kíkún.”
9 Nígbà náà ni ó fún ọba ní ọgọ́fà tálẹ́ńtì wúrà,+ àti òróró básámù+ ní ìwọ̀n púpọ̀ gan-an, àti àwọn òkúta iyebíye;+ kò sì tíì wá sí òróró básámù tí ó dà bí èyí tí ọbabìnrin Ṣébà fún Sólómọ́nì Ọba.+
10 Àti pé, ní àfikún, àwọn ìránṣẹ́ Hírámù+ àti àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì tí ó kó wúrà+ wá láti Ófírì kó àwọn ẹ̀là gẹdú igi álígúmù+ àti àwọn òkúta iyebíye+ wá.
11 Ọba sì bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ẹ̀là gẹdú igi álígúmù náà ṣe àwọn àtẹ̀gùn+ fún ilé Jèhófà àti fún ilé ọba+ àti àwọn háàpù+ àti àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín+ fún àwọn akọrin+ pẹ̀lú, a kò sì tíì rí èyí tí ó dà bí wọn rí ní ilẹ̀ Júdà.
12 Sólómọ́nì Ọba alára sì fún ọbabìnrin+ Ṣébà ní gbogbo ohun tí ó jẹ́ inú dídùn rẹ̀ èyí tí òun béèrè, ní àfikún sí iye tí ó tó ohun tí ó gbé wá fún ọba. Nítorí náà, ó yíjú padà, ó sì lọ sí ilẹ̀ tirẹ̀, òun pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.+
13 Ìwọ̀n wúrà tí ó ń dé sọ́dọ̀ Sólómọ́nì ní ọdún kan sì jẹ́ ọ̀tà-lé-lẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà tálẹ́ńtì wúrà,+
14 yàtọ̀ sí àwọn ọkùnrin arìnrìn-àjò àti àwọn olówò+ tí ń kó nǹkan wá àti gbogbo ọba àwọn ará Árébíà+ àti àwọn gómìnà ilẹ̀ tí ń kó wúrà àti fàdákà wá fún Sólómọ́nì.
15 Sólómọ́nì Ọba sì tẹ̀ síwájú láti fi àyọ́lù wúrà+ ṣe igba apata ńlá (ẹgbẹ̀ta ṣékélì àyọ́lù wúrà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́ lé apata ńlá kọ̀ọ̀kan),+
16 ó sì fi àyọ́lù wúrà ṣe ọ̀ọ́dúnrún asà (mínà mẹ́ta wúrà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́ lé asà kọ̀ọ̀kan).+ Lẹ́yìn náà, ọba kó wọn sínú Ilé Igbó Lẹ́bánónì.+
17 Síwájú sí i, ọba ṣe ìtẹ́ eyín erin ńlá kan, ó sì fi ògidì wúrà bò ó.+
18 Àtẹ̀gùn mẹ́fà sì ni ìtẹ́ náà ní, ìtẹ́ náà sì ní àpótí ìtìsẹ̀ kan tí ó jẹ́ wúrà (a dè wọ́n mọ́ ọn), ibi ìgbápálé sì wà ní ìhà ìhín àti ní ìhà ọ̀hún lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi ìjókòó, kìnnìún méjì+ sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ibi ìgbápálé náà.+
19 Kìnnìún méjìlá+ sì ni ó wà tí ó dúró níbẹ̀ lórí àtẹ̀gùn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà ní ìhà ìhín àti ní ìhà ọ̀hún. Kò sí ìjọba mìíràn tí ó ní èyíkéyìí tí a ṣe bí èyí gan-an.+
20 Gbogbo ohun èlò+ fún ohun mímu Sólómọ́nì Ọba sì jẹ́ wúrà,+ gbogbo ohun èlò Ilé Igbó Lẹ́bánónì+ sì jẹ́ ògidì wúrà. Kò sí nǹkan kan tí ó jẹ́ ti fàdákà; a kò kà á sí nǹkan kan rárá+ ní àwọn ọjọ́ Sólómọ́nì.
21 Nítorí pé àwọn ọkọ̀ òkun tí ó jẹ́ ti ọba máa ń lọ sí Táṣíṣì+ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ Hírámù.+ Ẹ̀ẹ̀kan ní ọdún mẹ́ta-mẹ́ta ni àwọn ọkọ̀ òkun Táṣíṣì máa ń wọlé, wọn a gbé wúrà àti fàdákà,+ eyín erin,+ àti àwọn ìnàkí àti àwọn ẹyẹ ológe+ wá.
22 Nítorí náà, Sólómọ́nì Ọba pọ̀ ju gbogbo àwọn ọba yòókù ní ilẹ̀ ayé ní ọrọ̀+ àti ọgbọ́n.+
23 Gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ ayé sì ń wá+ ojú Sólómọ́nì láti gbọ́ ọgbọ́n+ rẹ̀, èyí tí Ọlọ́run tòótọ́ ti fi sínú ọkàn-àyà+ rẹ̀.
24 Olúkúlùkù wọn sì ń mú ẹ̀bùn+ tirẹ̀ wá, àwọn ohun èlò fàdákà àti àwọn ohun èlò wúrà+ àti àwọn ẹ̀wù,+ ìhámọ́ra àti òróró básámù, àwọn ẹṣin àti ìbaaka gẹ́gẹ́ bí ìṣe ọdọọdún.+
25 Sólómọ́nì sì wá ní ẹgbàajì ibùso ẹṣin+ àti kẹ̀kẹ́ ẹṣin+ àti ẹgbẹ̀rún méjìlá ẹṣin ogun, ó sì yàn wọ́n dúró sí àwọn ìlú ńlá kẹ̀kẹ́ ẹṣin+ àti sí tòsí ọba ní Jerúsálẹ́mù.
26 Ó sì wá jẹ́ olùṣàkóso lórí gbogbo àwọn ọba láti Odò títí dé ilẹ̀ àwọn Filísínì àti títí dé ààlà Íjíbítì.+
27 Síwájú sí i, ọba ṣe fàdákà tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù bí àwọn òkúta; ó sì ṣe igi kédárì bí àwọn igi síkámórè+ tí ó wà ní Ṣẹ́fẹ́là+ fún ọ̀pọ̀ yanturu.+
28 Àwọn kan sì wà tí ń kó ẹṣin+ jáde wá fún Sólómọ́nì láti Íjíbítì+ àti láti gbogbo àwọn ilẹ̀ yòókù.
29 Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Sólómọ́nì,+ ti àkọ́kọ́ àti ti ìkẹyìn, a kò ha kọ wọ́n sínú àwọn ọ̀rọ̀ Nátánì+ wòlíì àti sínú àsọtẹ́lẹ̀ Áhíjà+ ọmọ Ṣílò+ àti sínú àkọsílẹ̀ àwọn ìran Ídò+ olùríran nípa Jèróbóámù+ ọmọkùnrin Nébátì?+
30 Sólómọ́nì sì ń bá a lọ láti jọba ní Jerúsálẹ́mù lórí gbogbo Ísírẹ́lì fún ogójì ọdún.
31 Níkẹyìn, Sólómọ́nì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀. Nítorí náà, wọ́n sin ín sí Ìlú Ńlá Dáfídì baba rẹ̀;+ Rèhóbóámù+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.+

