2 Kíróníkà 7:1-22
7 Wàyí o, gbàrà tí Sólómọ́nì parí gbígbàdúrà,+ iná sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jó ọrẹ ẹbọ sísun+ àti àwọn ẹbọ náà run, ògo Jèhófà+ sì kún ilé náà.
2 Àwọn àlùfáà kò sì lè wọnú ilé Jèhófà+ nítorí pé ògo Jèhófà ti kún ilé Jèhófà.
3 Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì jẹ́ òǹwòran nígbà tí iná sọ̀ kalẹ̀ wá, tí ògo Jèhófà sì wà lórí ilé náà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n tẹrí ba+ mọ́lẹ̀ ní ìdojúbolẹ̀ lórí ibi títẹ́, wọ́n sì wólẹ̀,+ wọ́n sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, “nítorí tí ó jẹ́ ẹni rere,+ nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”+
4 Ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn náà sì ń rú ẹbọ níwájú Jèhófà.+
5 Sólómọ́nì Ọba sì ń bá a lọ ní fífi ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàá màlúù àti ọ̀kẹ́ mẹ́fà àgùntàn+ rú ẹbọ. Bí ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn náà ṣe ṣe ayẹyẹ ṣíṣí+ ilé Ọlọ́run tòótọ́ nìyẹn.
6 Àwọn àlùfáà+ sì dúró sí ibi iṣẹ́ wọn, àti àwọn ọmọ Léfì+ pẹ̀lú àwọn ohun èlò orin+ sí Jèhófà èyí tí Dáfídì Ọba+ ṣe láti máa fi dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, “nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin,” nígbà tí Dáfídì bá ń tipa ọwọ́ wọn mú ìyìn wá; àwọn àlùfáà sì ń fun kàkàkí+ kíkankíkan ní iwájú wọn, nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà ní ìdúró.
7 Nígbà náà ni Sólómọ́nì sọ àárín àgbàlá tí ó wà níwájú ilé Jèhófà di mímọ́,+ nítorí pé ibẹ̀ ni ó ti rú àwọn ọrẹ ẹbọ sísun+ àti àwọn apá ọlọ́ràá ti àwọn ẹbọ ìdàpọ̀, nítorí pé pẹpẹ bàbà+ tí Sólómọ́nì ṣe gan-an kò lè gba ọrẹ ẹbọ sísun náà àti ọrẹ ẹbọ ọkà+ àti àwọn apá ọlọ́ràá.+
8 Sólómọ́nì sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àjọyọ̀+ ní àkókò yẹn fún ọjọ́ méje, àti gbogbo Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀,+ ìjọ títóbi gan-an+ láti àtiwọ Hámátì+ títí dé àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Íjíbítì.+
9 Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kẹjọ wọ́n ṣe àpéjọ ọ̀wọ̀,+ nítorí pé wọ́n ti ṣe ayẹyẹ ṣíṣí pẹpẹ fún ọjọ́ méje àti àjọyọ̀ fún ọjọ́ méje.
10 Ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù keje, ó rán àwọn ènìyàn náà lọ sí ilé wọn, wọ́n kún fún ìdùnnú+ àti ìjẹ̀gbádùn nínú ọkàn-àyà lórí oore+ tí Jèhófà ṣe fún Dáfídì àti fún Sólómọ́nì àti fún Ísírẹ́lì àwọn ènìyàn rẹ̀.+
11 Bí Sólómọ́nì ṣe parí ilé Jèhófà+ àti ilé ọba+ nìyẹn; Sólómọ́nì sì ṣe àṣeyọrí sí rere nínú ohun gbogbo tí ó wá sí ọkàn-àyà rẹ̀ láti ṣe nípa ilé Jèhófà àti ilé tirẹ̀.
12 Jèhófà fara han+ Sólómọ́nì wàyí ní òru, ó sì wí fún un pé: “Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ,+ mo sì ti yan+ ibí yìí fún ara mi gẹ́gẹ́ bí ilé ìrúbọ.+
13 Nígbà tí mo bá sé ọ̀run pa kí òjò má rọ̀,+ nígbà tí mo bá sì pàṣẹ fún àwọn tata láti jẹ ilẹ̀ náà tán,+ bí mo bá sì rán àjàkálẹ̀ àrùn sáàárín àwọn ènìyàn mi,+
14 tí àwọn ènìyàn mi+ tí a fi orúkọ mi+ pè sì rẹ ara wọn sílẹ̀,+ tí wọ́n sì gbàdúrà,+ tí wọ́n sì wá ojú mi,+ tí wọ́n sì yí padà kúrò nínú àwọn ọ̀nà búburú wọn,+ nígbà náà, èmi alára yóò gbọ́ láti ọ̀run,+ èmi yóò sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì,+ èmi yóò sì mú ilẹ̀ wọn lára dá.+
15 Wàyí o, ojú mi+ yóò là, etí mi+ yóò sì ṣí sí àdúrà ní ibí yìí.
16 Wàyí o, mo yan+ ilé yìí, mo sì sọ ọ́ di mímọ́ kí orúkọ mi+ lè máa wà níbẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ ojú mi àti ọkàn-àyà mi yóò sì máa wà níbẹ̀ nígbà gbogbo.+
17 “Bí ìwọ alára yóò bá sì rìn níwájú mi, gan-an gẹ́gẹ́ bí Dáfídì+ baba rẹ ti rìn, àní nípa ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ,+ tí ìwọ yóò sì pa àwọn ìlànà+ mi àti àwọn ìpinnu ìdájọ́+ mi mọ́,
18 ṣe ni èmi yóò fìdí ìtẹ́ àkóso rẹ múlẹ̀ pẹ̀lú,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti bá Dáfídì baba rẹ dá májẹ̀mú,+ pé, ‘A kì yóò ké ọkùnrin tìrẹ kankan kúrò nínú ṣíṣàkóso lé Ísírẹ́lì lórí.’+
19 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin alára bá yí padà,+ tí ẹ sì fi àwọn ìlànà àgbékalẹ̀+ mi àti àwọn àṣẹ+ mi tí mo fi síwájú yín sílẹ̀ ní ti tòótọ́, tí ẹ sì lọ sin àwọn ọlọ́run mìíràn+ ní ti tòótọ́, tí ẹ sì tẹrí ba fún wọn,+
20 ṣe ni èmi pẹ̀lú yóò fà wọ́n tu kúrò lórí ilẹ̀ mi tí mo ti fi fún wọn;+ àti ilé yìí tí mo ti sọ di mímọ́+ fún orúkọ mi ni èmi yóò gbé sọnù kúrò níwájú mi,+ èmi yóò sì sọ ọ́ di ọ̀rọ̀ òwe+ àti ìṣáátá láàárín gbogbo ènìyàn.+
21 Ní ti ilé yìí tí ó ti di òkìtì àwókù,+ gbogbo ẹni tí ó bá gba ibẹ̀ kọjá yóò wò sùn-ùn pẹ̀lú kàyéfì,+ dájúdájú, yóò sì wí pé, ‘Nítorí ìdí wo ni Jèhófà fi ṣe bẹ́ẹ̀ sí ilẹ̀ yìí àti sí ilé yìí?’+
22 Dájúdájú, wọn yóò sì sọ pé, ‘Ó jẹ́ nítorí ìdí náà pé wọ́n fi Jèhófà+ Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn sílẹ̀, ẹni tí ó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí di àwọn ọlọ́run mìíràn+ mú, wọ́n sì tẹrí ba fún wọn, wọ́n sì sìn wọ́n.+ Ìdí nìyẹn tí ó fi mú gbogbo ìyọnu àjálù yìí wá sórí wọn.’”+

