2 Kíróníkà 4:1-22

4  Lẹ́yìn náà, ó ṣe pẹpẹ bàbà,+ ogún ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn rẹ̀, ogún ìgbọ̀nwọ́ sì ni fífẹ̀ rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá sì ni gíga rẹ̀.+  Ó sì tẹ̀ síwájú láti ṣe òkun dídà+ náà ní ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti ẹnu rẹ̀ kan dé ẹnu rẹ̀ kejì, ó rí bìrìkìtì yí ká, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, ó sì gba okùn tí ó jẹ́ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ láti na gbogbo àyíká rẹ̀ já.+  Ìrí àwọn ohun ọ̀ṣọ́ onírìísí akèrègbè+ sì wà lábẹ́ rẹ̀ yí ká, wọ́n yí i ká, mẹ́wàá nínú ìgbọ̀nwọ́ kan, wọ́n yí òkun náà po.+ Àwọn ohun ọ̀ṣọ́ onírìísí akèrègbè náà wà ní ẹsẹ méjì, a rọ ọ́ ní rírọ tirẹ̀.  Ó dúró lórí akọ màlúù méjìlá,+ mẹ́ta dojú kọ àríwá, mẹ́ta dojú kọ ìwọ̀-oòrùn, mẹ́ta dojú kọ gúúsù, mẹ́ta sì dojú kọ ìlà-oòrùn; òkun náà sì wà lókè lórí wọn, gbogbo apá ẹ̀yìn wọ́n sì wà ní ìhà inú.+  Ìnípọn rẹ̀ sì jẹ́ ìbú ọwọ́ kan; ẹnu rẹ̀ sì dà bí iṣẹ́ ọnà ẹnu ife, ìtànná òdòdó lílì.+ Gẹ́gẹ́ bí ìkóhunsí, ẹgbẹ̀ẹ́dógún òṣùwọ̀n báàfù+ ni ó lè gbà.+  Síwájú sí i, ó ṣe bàsíà mẹ́wàá, ó gbé márùn-ún sí apá ọ̀tún àti márùn-ún sí apá òsì,+ láti máa wẹ̀ láti inú wọn.+ Àwọn ohun tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun+ ni wọ́n máa ń ṣàn láti inú wọn. Ṣùgbọ́n òkun náà jẹ́ ti àwọn àlùfáà láti máa wẹ̀ láti inú rẹ̀.+  Lẹ́yìn náà, ó ṣe àwọn ọ̀pá fìtílà wúrà,+ ó ṣe mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ní àwòrán ìwéwèé kan náà,+ ó sì fi wọ́n sínú tẹ́ńpìlì, márùn-ún sí apá ọ̀tún àti márùn-ún sí apá òsì.+  Síwájú sí i, ó ṣe tábìlì mẹ́wàá, ó sì gbé wọn sínú tẹ́ńpìlì, márùn-ún sí apá ọ̀tún àti márùn-ún sí apá òsì,+ ó sì ṣe ọgọ́rùn-ún àwokòtò wúrà.  Lẹ́yìn náà, ó ṣe àgbàlá+ àwọn àlùfáà+ àti gbàgede ńlá+ àti àwọn ilẹ̀kùn tí ó jẹ́ ti gbàgede náà, ó sì fi bàbà bo àwọn ilẹ̀kùn wọn. 10  Òkun náà ni ó sì gbé sí ìhà ọ̀tún, sí ìlà-oòrùn, síhà gúúsù.+ 11  Níkẹyìn, Hírámù ṣe àwọn garawa+ àti àwọn ṣọ́bìrì+ àti àwọn àwokòtò.+ Bẹ́ẹ̀ ni Hírámù parí ṣíṣe iṣẹ́ tí ó ṣe fún Sólómọ́nì Ọba lára ilé Ọlọ́run tòótọ́. 12  Ọwọ̀n méjèèjì+ àti àwọn ọpọ́n rìbìtì+ tí ó wà ní orí ọwọ̀n méjèèjì àti àsokọ́ra bí àwọ̀n méjèèjì+ láti fi bo ọpọ́n rìbìtì méjèèjì tí ó wà ní orí àwọn ọwọ̀n náà 13  àti irínwó pómégíránétì+ náà fún àsokọ́ra bí àwọ̀n méjèèjì, ẹsẹ pómégíránétì méjì fún àsokọ́ra bí àwọ̀n kọ̀ọ̀kan láti fi bo ọpọ́n rìbìtì méjèèjì tí ó wà lórí àwọn ọwọ̀n náà,+ 14  àti kẹ̀kẹ́ ẹrù mẹ́wẹ̀ẹ̀wá+ àti bàsíà mẹ́wẹ̀ẹ̀wá+ tí ó wà lórí àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù náà; 15  òkun náà+ àti akọ màlúù méjìlá tí ó wà lábẹ́ rẹ̀,+ 16  àti àwọn garawa àti àwọn ṣọ́bìrì+ àti àwọn àmúga+ àti gbogbo nǹkan èlò+ wọn ni Hiramu-ábífì+ fi bàbà tí a dán ṣe fún Sólómọ́nì Ọba fún ilé Jèhófà. 17  Àgbègbè Jọ́dánì ni ọba ti rọ wọ́n ní ilẹ̀ líle tí ó wà láàárín Súkótù+ àti Sérédà.+ 18  Bí Sólómọ́nì ti ṣe gbogbo nǹkan èlò wọ̀nyí ní ìwọ̀n púpọ̀ gan-an nìyẹn, nítorí a kò mọ ìwọ̀n bàbà náà dájú.+ 19  Sólómọ́nì sì tẹ̀ síwájú láti ṣe gbogbo nǹkan èlò+ tí ó wà ní ilé Ọlọ́run tòótọ́ àti pẹpẹ wúrà+ àti àwọn tábìlì+ tí búrẹ́dì àfihàn wà lórí wọn, 20  àti àwọn ọ̀pá fìtílà+ àti fìtílà+ wọn ni ó fi ògidì wúrà ṣe, láti máa tàn wọ́n níwájú yàrá inú pátápátá+ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà àfilélẹ̀; 21  àti àwọn ìtànná àti àwọn fìtílà àti àwọn ẹ̀mú+ ni ó fi wúrà ṣe, (ojúlówó ògidì wúrà ni,) 22  àti àwọn àlùmọ́gàjí fìtílà àti àwọn àwokòtò àti àwọn ife àti àwọn ìkóná ni ó fi ògidì wúrà ṣe,+ àti ẹnu ọ̀nà ilé náà,+ àwọn ilẹ̀kùn rẹ̀ ti inú lọ́hùn-ún fún Ibi Mímọ́ Jù Lọ àti àwọn ilẹ̀kùn+ ilé tẹ́ńpìlì ni ó fi wúrà ṣe.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé