2 Kíróníkà 35:1-27
35 Nígbà náà ni Jòsáyà+ ṣe ìrékọjá+ kan ní Jerúsálẹ́mù sí Jèhófà, wọ́n sì pa ẹran ẹbọ ìrékọjá+ ní ọjọ́ kẹrìnlá+ oṣù kìíní.+
2 Nítorí náà, ó yan àwọn àlùfáà sípò lórí àwọn ohun tí ó wà lábẹ́ àbójútó+ wọn, ó sì fún wọn ní ìṣírí+ nínú iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà.+
3 Ó sì ń bá a lọ láti sọ fún àwọn ọmọ Léfì, tí ó jẹ́ olùkọ́ni+ gbogbo Ísírẹ́lì, tí wọ́n jẹ́ mímọ́ sí Jèhófà pé: “Ẹ gbé Àpótí mímọ́+ sínú ilé+ tí Sólómọ́nì ọmọkùnrin Dáfídì ọba Ísírẹ́lì kọ́; kì í ṣe tiyín láti máa gbé e lé èjìká+ gẹ́gẹ́ bí ẹrù ìnira. Wàyí o, ẹ sin+ Jèhófà Ọlọ́run yín àti àwọn ènìyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì.
4 Ẹ sì ṣe ìpèsèsílẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ilé àwọn baba ńlá+ yín, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìpín+ yín, ní ìbámu pẹ̀lú ìwé+ Dáfídì ọba Ísírẹ́lì àti ní ìbámu pẹ̀lú ìwé+ Sólómọ́nì ọmọkùnrin rẹ̀.
5 Kí ẹ sì dúró+ ní ibi mímọ́ ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí ilé àwọn baba ńlá fún àwọn arákùnrin yín, àwọn ọmọ àwọn ènìyàn náà, àti ìpín ìdí ilé baba+ tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Léfì.+
6 Kí ẹ sì pa ẹran ẹbọ ìrékọjá+ kí ẹ sì sọ ara yín di mímọ́+ kí ẹ sì ṣe ìpèsèsílẹ̀ fún àwọn arákùnrin yín láti ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà nípasẹ̀ Mose.”+
7 Wàyí o, Jòsáyà fi àwọn agbo ẹran, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn àti akọ ọmọ ewúrẹ́ ṣe ìtọrẹ fún àwọn ọmọ àwọn ènìyàn náà, gbogbo rẹ̀ jẹ́ fún àwọn ẹran ẹbọ ìrékọjá fún gbogbo àwọn tí a lè rí, iye rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀, àti màlúù, ẹgbẹ̀ẹ́dógún.+ Ìwọ̀nyí jẹ́ láti inú àwọn ẹrù ọba.+
8 Àwọn ọmọ aládé+ rẹ̀ alára ṣe ìtọrẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe fún àwọn ènìyàn náà,+ fún àwọn àlùfáà àti fún àwọn ọmọ Léfì. Hilikáyà+ àti Sekaráyà àti Jéhíélì alára gẹ́gẹ́ bí àwọn aṣáájú ilé Ọlọ́run tòótọ́, fún àwọn àlùfáà ní ẹgbẹ̀tàlá ẹran ẹbọ ìrékọjá, àti ọ̀ọ́dúnrún màlúù.
9 Konanáyà àti Ṣemáyà àti Nétánélì àwọn arákùnrin rẹ̀ àti Haṣabáyà àti Jéélì àti Jósábádì, àwọn olórí àwọn ọmọ Léfì, sì fi ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ẹran ẹbọ ìrékọjá, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta màlúù ṣe ìtọrẹ fún àwọn ọmọ Léfì.
10 A sì múra+ iṣẹ́ ìsìn náà sílẹ̀, àwọn àlùfáà sì ń bẹ ní ìdúró+ ní ipò wọn,+ àti àwọn ọmọ Léfì ní ìbámu pẹ̀lú ìpín wọn,+ ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ ọba.+
11 Wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti pa ẹran ẹbọ+ ìrékọjá, àwọn àlùfáà+ sì wọ́n+ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ láti ọwọ́ wọn, bí àwọn ọmọ Léfì ti ń bó awọ+ rẹ̀ kúrò.
12 Síwájú sí i, wọ́n pèsè àwọn ọrẹ ẹbọ sísun sílẹ̀ láti lè fi wọ́n fún àwọn ìsọ̀rí-ìsọ̀rí+ ní ìbámu pẹ̀lú ìdí ilé baba,+ fún àwọn ọmọ àwọn ènìyàn náà, láti lè mú ọrẹ ẹ̀bùn+ wá fún Jèhófà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ sínú ìwé Mósè;+ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú sì ni wọ́n ṣe sí àwọn màlúù náà.
13 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí se+ ọrẹ ẹbọ ìrékọjá+ lórí iná gẹ́gẹ́ bí àṣà; wọ́n sì se+ àwọn ohun tí a sọ di mímọ́ nínú àwọn ìkòkò ìse-oúnjẹ àti nínú àwọn ìkòkò onídìí rìbìtì àti nínú àwọn àwokòtò àsè, lẹ́yìn èyí tí wọ́n gbé e wá kíákíá sọ́dọ̀ gbogbo àwọn ọmọ àwọn ènìyàn náà.+
14 Lẹ́yìn ìgbà náà sì ni wọ́n pèsè sílẹ̀ fún ara wọn àti fún àwọn àlùfáà,+ nítorí pé àwọn àlùfáà àwọn ọmọ Áárónì wà lẹ́nu rírú àwọn ẹbọ sísun+ àti àwọn apá ọlọ́ràá+ títí di òru, àwọn ọmọ Léfì, ní tiwọn, sì pèsè sílẹ̀+ fún ara wọn àti fún àwọn àlùfáà àwọn ọmọ Áárónì.
15 Àwọn akọrin+ àwọn ọmọ Ásáfù+ sì ń bẹ ní ipò iṣẹ́ wọn ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ Dáfídì+ àti ti Ásáfù+ àti ti Hémánì+ àti ti Jédútúnì+ olùríran+ fún ọba; àwọn aṣọ́bodè+ sì ń bẹ ní àwọn ẹnubodè+ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Kò sí ìdí fún wọn láti yà kúrò nínú iṣẹ́ ìsìn wọn, nítorí pé àwọn arákùnrin wọn àwọn ọmọ Léfì ti pèsè sílẹ̀+ fún wọn.
16 A sì múra gbogbo iṣẹ́ ìsìn Jèhófà sílẹ̀ ní ọjọ́ yẹn láti ṣe ìrékọjá+ náà àti láti rú àwọn ọrẹ ẹbọ sísun lórí pẹpẹ Jèhófà, ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ Jòsáyà Ọba.+
17 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí a rí sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìrékọjá náà+ ní àkókò yẹn àti àjọyọ̀ àwọn àkàrà aláìwú pẹ̀lú fún ọjọ́ méje.+
18 A kò sì ṣe irú ìrékọjá bẹ́ẹ̀ rí ní Ísírẹ́lì láti àwọn ọjọ́ Sámúẹ́lì wòlíì,+ bẹ́ẹ̀ ni èyíkéyìí nínú àwọn ọba+ mìíràn ní Ísírẹ́lì kò ṣe irú ìrékọjá tí Jòsáyà àti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì àti gbogbo Júdà àti Ísírẹ́lì tí a rí àti àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù ṣe.
19 Ní ọdún kejìdínlógún ìgbà ìjọba Jòsáyà ni a ṣe ìrékọjá yìí.+
20 Lẹ́yìn gbogbo èyí, nígbà tí Jòsáyà ti múra ilé náà sílẹ̀, Nékò+ ọba Íjíbítì+ gòkè wá láti jà ní Kákémíṣì+ lẹ́bàá Yúfírétì. Jòsáyà+ wá jáde lọ láti bá a faga gbága.+
21 Látàrí ìyẹn, ó rán àwọn ońṣẹ́ sí i pé: “Kí ní pa tèmi tìrẹ pọ̀, ìwọ ọba Júdà? Kì í ṣe ìwọ ni mo ń bọ̀ wá bá lónìí, ṣùgbọ́n ilé mìíràn ni mo ń lọ bá jà, èyí tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sì sọ pé kí n dá ìyọlẹ́nu sílẹ̀ fún. Fà sẹ́yìn fún ire ara rẹ nítorí Ọlọ́run, ẹni tí ó wà pẹ̀lú mi, má sì jẹ́ kí ó run ọ́.”+
22 Jòsáyà kò sì yí ojú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀,+ ṣùgbọ́n kí ó lè bá a jà, ó para dà,+ kò sì fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ Nékò+ láti ẹnu Ọlọ́run. Nítorí náà, ó wá jà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì Mẹ́gídò.+
23 Àwọn ọ̀tafà+ sì ta Jòsáyà Ọba, tí ọba fi wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ gbé mi sọ̀ kalẹ̀, nítorí mo ti gbọgbẹ́+ gidigidi.”
24 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gbé e sọ̀ kalẹ̀ nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin, wọ́n sì gbé e gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun kejì tí ó jẹ́ tirẹ̀, wọ́n sì gbé e wá sí Jerúsálẹ́mù.+ Bí ó ṣe kú+ nìyẹn, tí a sì sin ín sí itẹ́ àwọn baba ńlá rẹ̀;+ gbogbo Júdà àti Jerúsálẹ́mù sì ń ṣọ̀fọ̀+ Jòsáyà.
25 Jeremáyà+ sì bẹ̀rẹ̀ sí sun rárà+ fún Jòsáyà; gbogbo ọkùnrin akọrin àti obìnrin+ akọrin sì ń sọ̀rọ̀ nípa Jòsáyà ṣáá nínú àwọn orin arò wọn títí di òní; wọ́n sì mú kí a fi wọ́n lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà lórí Ísírẹ́lì, ibẹ̀ sì ni a kọ wọ́n sí nínú àwọn orin arò.+
26 Ní ti ìyókù àlámọ̀rí+ Jòsáyà àti àwọn ìṣe inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́,+ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ sínú òfin+ Jèhófà,
27 àti àwọn àlámọ̀rí rẹ̀, ti àkọ́kọ́ àti ti ìkẹyìn,+ ibẹ̀ ni a kọ wọ́n sí nínú Ìwé+ Àwọn Ọba Ísírẹ́lì àti Júdà.

